1 PeteruÀpẹrẹ

1 Peteru

Ọjọ́ 4 nínú 5

Àwọn ìyàwo Kristẹ́ní, ẹrú, àti àw\n ọmọ ìlú ni wọ́n pa lára nítorí wọ́n jẹ́ olódod sí Jesu. Ó rọrùn fún wọn púpọ̀ láti gbẹ̀san ṣugbn Peteru ni pé ó dára púpọ́ kí ènìyàn rí ìpọ́njú torí pé ó se rere ju kí ènìyàn gba ìre nígbà tí ó bá se ibi. A pé àwọn èniyàn Ọlọ́run láti wa bùkún aráyé, kìí se láti wa fi wọ́n ré. Ó tọ́ka sí Psalm 34, Peteru wí pé ó ní àwọn tí wọn kò se ibi ni wọ́n ń gbá ìgbé ayé rere. Peteru so ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ pé àwọn tí wọ́n rí ìpọ́njú fún ìsòdodo wọ́n ni a ó bùkún fún. Síse rere ní ọ̀nà tí ó tọ́ ni ìlànà tí Jsu fi lélẹ̀

Torí pé a kò gbẹ̀san lára olùfisùn ni Jesu fi mú wa súnmọ́ Ọlọ́run. Bí ó bá jẹ́nípa ṣíse èyí ni a ṣe rí ìgbàlà, a jẹ́ pé bẹ̀ẹ́ lo se yẹ kí a má a se sí àwọn olùfisùn. Bákan náà, Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àjíǹde Jesu láti iṣà òkú se kó ìtìjú bá àwọn ará Romu, ikú àti ọ̀run àpáàdì. Ìwà pẹ̀lẹ́ àti ìtẹríba wa le mú ìdójútì bá àwọn asọ̀rọ̀ ìbájẹ́ ẹni àti àwọn asenúnibíni.

Peteru rán àwọn ènìyàn rẹ̀ léti pé ìjà láàrin ẹ̀mí Esú àti èniyàn Ọlọ́run ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ìjà náà kì í yàtọ́ ní gbogbo ìgbà: Ọlọ́run máa ń gba àwọn ènìyàn tirẹ̀, ó sì máa ń dójú ti Èsù. Ọlọ́run gba Nua àti ìdílé rẹ̀ nígbà tí ó mí ẹ̀kún omi wá, ó sì dújúti agbára Èsù. Gẹ́gẹ́ bí a se gba Nua lọ́wọ́ ẹ̀kún omi bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa náà se rí ìgbàlà nípaṣẹ̀ ìrìbọmi.

Bí àwọn ènìyàn ibi ìgbà ayé Nua se rì sínú omi, ni a ti fi gbogbo agbára àti àṣẹ lé Jesu lọ́wọ́. Torí náà, kí a máa fi ire san ibi ni snà sí ìgbàlà.

Jíjìyà nínú ìwà búburú ṣùgbọ́n dídàgbà nínú agbára ayé jẹ́ ìkùnà fún ọmọ ẹ̀yìn Jesu. Àwọn alábàágbá wa yóó se inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí pé, kódà, bí a bá kú a ó dìde.

Jíjìyà fún òdodo kìí se òhuntó se àjòjì. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu ni láti mọ̀ pé àwọn ènìyàn yóó se inúnibíni sí wọn torí pé wọ́n ń gbé ìgbé ayé Jesu. Ṣugbọ́n fún àwọn ti a se inúnibíni sí, Kìí se ikú Jesu àti àjíǹde rẹ̀ nìkan ni àpẹẹrẹ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ ìsaájú. Nígbà tí a bá rí ìpọ́njú bí i Jesu, a ó díde bí i rẹ̀. Nígbà tí a bá jìyà fún ohun tí ó dára, ojú kò ní tìwá.Láìsí ìbẹ̀rù kankan, a lè di òkú sí, ìwà búburú, ẹ̀san torí pé a mọ̀ pé a ó dìde.

A tún le di òkú sí àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀. Fún àwọn ènìyàn ìgbà ayé Nua, àwọn Farisí ìgbà ayé Peteru àti àwọn alábàágbé wa lónìí, kò dára láti dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìwà èérí, ọ̀mùtí, àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Ki á má se gbé bí i àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní àyíká wa, tí wọ́n ń se ìṣe afẹ́, òsèlú àti àwọn onírúurú ohun mìíràn. Ṣùgbọ́n kí a gbé ìgbé aye bí i ti Jesu. Peteru sọ pé bí Jesu se jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí ó sì dìde, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn búburú se rì sínú ẹ̀kún omi tí Nua sì rí ìgbàlà, Rírí ìpọ́njú nínú ìserere yóó yọrí sí àjíǹde àti ìgbàlà.

Bí ó bá ń gbé ni Orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti ń tako Kristẹ́nì, tàbí ní egbègbè tíwọ́n ti ń yọ̀ nínú ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti tí wọ́n ti ń se yẹ̀yẹ̀ àwọn olódodo, tàbí ní Orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti kórira àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu, àjíǹde wà ní ibi gbogbo. Gbogbo ìwà inúnibíni wọ̀nyí ní ó ń fi ìdí ìgbálá wa múlẹ̀, nígbà tí ikú sì ń se ayérayé wa lọ́jọ̀. Kristẹ́nì kò ní ìpalára nínú ayé ti kò ní òye kúkún nípa Kristẹ́nì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí i Jesu, a jẹ́ aṣẹ́gun lórí gbogbo agbára, ìdí nìyí tí ó fi dára kí á rí ìpọ́njú nínú ìṣe rere

Kí Ẹ̀mí Mímọ́ si yín lójú láti rí Ọlọ́run tí ó ń se dájọ́. Ìwọ yóó sì rí àjíǹde Jesu Olùgbàlà, ẹni tí ó rí ìpọ́njú nídìí ṣíse iṣẹ́ rere, kí a le dìde pẹ̀lú rẹ̀ nínú òkú.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

1 Peteru

Nípa ìrètí rẹ̀ nínú lẹ́tá tí ó ko sí ìjọ àkọ́kọ́, Peteru gbà wá níyànjú kí a ní ìgbàgbọ́, kí á sì gbọ́ràn. Ó ní kí á dúró sinsin nínú ìgbàgbọ́ nígbà tí a bá ń kojú àdánwò àti inúnibíni. Ó ní nítorí ẹ̀dá tí a jẹ́ nínú Jésù, a ní agbára láti gbé ìgbá ayé ìwà mímọ́, a ó sì le ní àfojúsùn ogún ayérayé.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/