1 PeteruÀpẹrẹ
Peteru ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu jáde lọ káàkiri agbègbè àwọn onígbàgbọ́ títí dé àwọn ibi kékèké ni Asia, níbi tí à ń pè ní Turkey báyìí. Ó se é se kí àwọn onígbàgbọ́ yìí jẹ́ kèfèrí, àti ọmọ ilẹ̀ Romu, ṣùgbọ́n Peteru pè wọ́n ní “ àwọn tí Ọlọ́run mú lọ sí oko ẹrú”. Wọ́n jẹ́ àjèjì tí Ọlọ́run yàn, tí wọ́n sì ti fọ́nká jákè jádò orílẹ̀
Pẹ̀lú irú ọ̀rọ̀ yìí, Peteru mọ̀-ọ́n-mọ̀ fi àwọn àjèjì kèfèrú wọ́nyí sínú ìtàn àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí í ṣe àwọn Júù. Gẹ́gẹ́ bí i àyàfẹ́ Israeli, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe yan Romu.Bí àwọn ìjọba Babiloni se fọ́n Júù ká, bẹ́ẹ̀ ni àwọn onígbàgbọ́ nínú Jesu se di fí fọ́nká láti ọwọ́ àwọn Romu. Ṣùgbọ́n Peteru kò fi ìtàn afẹ́ àti tí òsèlú wé ara wọn lásán. Ó ń wí pé Ọlọ́run yan àwọn Kèfèrí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yan àwọn ara Júù.Ìtàn ìléni kúrò nílùú àti ti ìpadàbọ̀ wálé tí ó ṣe pàtàkì nínú ìtàn Israeli ni ó wá jẹ́ ìtàn Ọlọ́run tí a kọ sí gbogbo ènìyàn.
Gbogbo onígbàgbọ́ nínú Jesu ni a ó lé kúrò. Kò sí onígbàgbọ́ tóó jẹ́ ọmọ inú ayé yìí torí pé Ọlọ́tun tí fún wa ní ìjọba rẹ̀.Peteru fi kún un pé a ti yàn wa nipaṣẹ̀ ìmọ̀ ìṣaáju nínú Ọlọ́run baba nípa iṣẹ́ ìfàmì òróró yan Ẹ̀mí Mímọ́ fún ìgbọràn àtiìbu ẹ̀jẹ̀ wọ́nni. Gbogbo ìwọ̀yí ọ̀nà ni ó jẹ́ ọ̀nà láti fi àwọn kèfèrí sí inú ìtàn àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run.Láti ìgbà ayé Abrahamu ní Ọlọ́run mọ̀, ó sí yan àwọn ẹrúláti bùkún ayé. Ẹ̀mí Ọlọ́run yan Israeli gẹ́gẹ́ bí i ilé rẹ̀ nígbà tí o sọ̀kalẹ̀ sí inú àgọ́. Ní ọjọ́ tí Israeli di Orílẹ̀ èdè ní àwọn ọmọ Ọlọ́run ṣèlérí láti má a gbọ́ràn, Mose sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ sí wọn lára. Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Israeli náà di Orílẹ̀ èdè tí a sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ́jẹ́ Jesu náà ti di Orílẹ̀ èdè titun.
Lílọ sí oko erú tí Ọlọ́run mú wa lọ ti wà ní àkọsílẹ̀ pé a ó kúrò ní ibùgbé wà, èyí sì jẹ́ ìròyìn ayọ̀ fún wa.Peteru wí pé ìrísí titun tí a ní gẹ́gẹ́ bí ẹrú túmọ̀ sí pé à ń dara pọ̀ mọ́ ẹbí titun. A ti kú fún Orílẹ̀ èdè, a sì ti bí wa sí inú ẹbí ayérayé àti sínú àjíǹde ìyè tí Ọlọ́run sètò. Gẹ́gẹ́ bí i ọmọ Ọlọ́run àti iyèkan Jesu, a tí fún wa ní ogún tí kò le dòkú, tí Èsù kò le gbà, ní èyí tí yóó sì wà láéláé, Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ní yóó sì dáabò bòó. Torí náà, jíjẹ́ àjòjì sí ayé àti jíjẹ́ ọmọ ní ìjọba Ọlọ́run ni ìdí fún ayọ̀ wa.
Gẹ́gẹ́ bí i àwọn mìíràn, a ó jìyà fún jíjẹ́ àjèjì. Nínú gbogbo lẹ́tà Peteru, Peteru ń sọ nípa àwọn ohun tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ ti ẹ̀mí fún títẹ̀lé Jesu.Ní ìkóríta yìí Jesu rán wa létí pé jíjẹ́ àjèjì sí ayé yìí ni ó ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ ọ̀run ni wá. Ìnúnibíni kọ́ ni ìdí fún àìnírẹ̀tí wa; ṣùgbọ́n àwọn àdánwò tí à ń rí ni ìdí ayọ̀ wa. Ìfarapa inúnibíni wa kò tó ìfarapa tí wúrà ní nínú iná. A lè yọ̀ torí pé ìpọ́njú sọ wá di mímọ́, ó sì ń sàfihàn ẹ̀rí ìgbàgbọ́ wa.
Jesu àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ìpọ́njú Jesu yọrí sí ògo, ìyè láti inú ikú lọ sí ìtẹ́ Ọlọ́run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa gan kò tilẹ̀ rí Jesu rí,Ṣùgbọ́n a lè yọ̀ nígbà tí a bá gbàgbọ́ nínú rẹ̀, ti a sì ní ìfẹ́ rẹ̀. Olùfisùn wa kò mọ ọ̀rọ̀ tí ó gbẹ̀yìn yìí torí pé wọn kò le pa ìgbàlà wa lára. Gẹ́eẹ́bí Peteru se fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣẹ́yìn, kò sí Orílẹ̀ èdè tàbí ẹnikan tí ó le pa, tí ó le hùwà àìtọ́ tàbítí ó le pa ohun tí Ọlọ́run ní fún ọ rẹ́.
Ìjìyà ìràpadè àti yíyanni lọ sí oko ẹrú le sàjòjì sí wa ṣùgbọ́n ó jẹ́ òtítọ́ tí ó lágbára. Àwọn wòlíì nínú májẹ̀mu láèláè se àṣàrò nínú bíbélì, wọ́n ń gbìyànjú láti wá a jáde. Àwọn Ańgẹ́lì pàápàá gbìyànjú láti sàfihàn díẹ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe sọ ìpọ́njú di ogo. Ṣùgbọ́n ohun tí àwọn wòlíì àti àwọn Ańgẹ́lì ń tiraka láti rí ní a rí dáadáa nínú Jesu. Ìpọ́njú rẹ̀ yọrí sí àjíǹde, ikú rẹ̀sì yọrí sí ògo. Nítorí Jesu, a mọ̀ pé ìpọ́njú àti ikú gbogbo onígbàgbọ́ má a ń yọrí sí ogún ibi ológo tí ó wà títí láé, tí kò sí le è parẹ́.
Kí ẹ̀mí mímọ́ sí ojú yín láti rí Ọlọ́run tí o mú wa lọ sí oko ẹrú. Ìwọ yóò sì rí Jesu gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó rà wá padà kúrò nínú ìpọ́njú, tí ó sì sọ wa di ẹbí nípa ẹ̀jẹ̀ àti àjíńde rẹ̀.
Nípa Ìpèsè yìí
Nípa ìrètí rẹ̀ nínú lẹ́tá tí ó ko sí ìjọ àkọ́kọ́, Peteru gbà wá níyànjú kí a ní ìgbàgbọ́, kí á sì gbọ́ràn. Ó ní kí á dúró sinsin nínú ìgbàgbọ́ nígbà tí a bá ń kojú àdánwò àti inúnibíni. Ó ní nítorí ẹ̀dá tí a jẹ́ nínú Jésù, a ní agbára láti gbé ìgbá ayé ìwà mímọ́, a ó sì le ní àfojúsùn ogún ayérayé.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/