Idalare Nipa IgbagboÀpẹrẹ
Ileri Abraham
Afi Abrahamu ṣe atọkasi ìfẹ Ọlọrun nínú Majẹmu Titun "tí ofi Ọmọbibi Rẹ̀ kàn ṣoṣo..." Abrahamu jọwọ Isaki ọmọ ileri nínú ìgbàgbọ pé Ọlọrun lè gbé dìde nínú òkú, ṣugbọn eleyii jẹ ìdánwò ìgbàgbọ rẹ nínú Ọlọrun.
Ni idahun Ọlọrun sí igbesẹ ìgbàgbọ Abrahamu; Ọlọrun búra ileri ìbùkún Rẹ fún Abrahamu ati èso inú rẹ. Nisiyi, ko niiṣe pẹlu ibì tò tí ti wá, òdí alabapin nínú ìlérí kan na l'akoko tó gbà Kristi Jésù.
Ileri yii jasi níní ipín nínú iran kristi, didi ẹni ìràpadà ati dídì ajumọ jogún pẹlu Kristi gẹgẹbi ọmọ Ọlọrun.
Ṣugbọn, ibẹrẹ àti opin ẹ̀ ni wípé o dà ẹni tó dà nipa igbagbọ nínú Kristi Jésù Kiiṣe nipa jijẹ ẹlẹsin tabi nipa pipa àwọn òfin ẹsìn mọ.
Siwaju kika: Galatia 3:28-29, 3:26-27, Genesisi 12:1-3.
Adura: Jésù mo gba ọ lóni, mo di ajumọ jogún ileri pẹlu rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo eniyan ni afi fún lati de ipò ìdáláre, tá owá ni àlàáfíà pẹlu Ọlọrun ati ará wa, nínú ìmọ pé Ọlọrun ti dariji ọ ati pé otí pa gbogbo ifisun rẹ àti ìdálẹbi rẹ rẹ́, kó ni óhùn kán sí ọ ṣugbọn O ri ọ gẹgẹbi òdodo Rẹ, O fẹràn rẹ, òsì ni ọpọlọpọ ileri ti O fi pámọ́ fún ọ. Ìgbé ayé ìyanu ni eyi jẹ! Ṣugbọn kini a nilo lati lè gbé igbeaye yii tabi ṣe oṣe ṣe?
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Adeoye Gideon fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL