Kò ì Tí ì Tán Fún ỌÀpẹrẹ

Kọjú sí àwọn Èyíṣejẹ́ Rẹ
Kylie ni ọ̀rẹ́ mi ìgbà pípẹ́, tí mo sì fẹ́ràn jùlọ, bíi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi, ó máa ń sá eré ìje ọ̀nà-jíjìn déédéé. Mi ò mọ̀ bóyá mò ń gbé ìgbé ayé wọn nínú tèmi ni, ṣùgbọ́n ó dà bíi pé mokàn ń kó ọ̀rẹ́ tí wọ́n fẹ́ràn láti máa sáré tí ò jìnnà jọni. Ohun kan tí mo fẹ́ràn nípa Kylie ni pé ó máa ń tẹ̀lé ìlànà kan náà ní gbogbo ìgbà tí ó bá ń sáré ìje ọ̀nà-jíjìn. Bí ìbọn ìbẹ̀rẹ̀ bá ti yìn, yíò sọ sí ìta pé, "Kylie, kìkì ohun tí o láti ṣe ni kí o parí eré náà."
Ní gbogbo bí ó tií ń sáré, ohun tí ó máa ń so fún ara rẹ̀ ókérétán, ní ìgbà ọ̀gọ́rún ni èyí. Kì í ṣe pé ó ń gbìyànjú láti jẹ́ ẹni tó dára jù lọ, kì í fi bí eré ìje náà ṣe ń yára tó wé ti àwọn tó kù, ńṣe ló kàn máa ń dá eré ìje náà ṣe fúnra rẹ̀, tí ó sì máa ń sá eré náà. Èyí tó sì ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ó fẹ́ de iparí eré náà.
Ẹ̀kọ́ ńlá lèyí jẹ́ fún gbogbo wa. Bí ète wa bá jẹ́ láti di aláfarawé àti láti yí padà sí àwòrán Jésù, ó túmọ̀ sí pé ohun tó yẹ kó jẹ́ àfojúsùn wa ni ká túnbọ̀ dà bí Jésù. Kí á máa sá eré ìje wa lọ́nà tí Jésù fẹ́ kí á sá a ni ó yẹ kí ó jẹ́ àfojúsùn wa. Nítorínáà, a kò wá bí a ó ṣe borí ẹlòmíràn; kì í ṣe pé a fẹ́ ṣe dáadáa ju àwọn ẹlòmíràn lọ; a ń ṣe gbogbo ohun tí á lè ṣe láti dà bíi Jésù síi ni.
Bí a bá ṣí ojú wa kúrò lórí èrè tó ga jù lọ láìmọ̀ èyí tí í ṣe—Jésù—ojú wa á wá máa wo àwọn nǹkan míì, bíi ènìyàn, ipò wa, àti wíwá àti tẹ́ ara wa lọ́rùn, a ò ní lè gbé ayé tó dúró déédéé, a ó sì yẹ̀bá kúrò lọ́nà ohun tí ó tọ́. Bí a bá mú ojú wa kúrò lórí àfojúsùn wa, ó ṣeéṣe kí á máa ronú pé nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ kì ó lọ. Pé a kò rí èrè tàbí ìtẹ́wọ́gbà ní kíákíá. A sì lè fi àìmọ̀kan yọ ara wa kúrò kí á sì rìn ṣáko nínú ète wa.
p>Ká sòótọ́, ní àwọn ìgbà kan tí mo kojú àwọn ìpèníjà tí ó le jù lọ nígbèésí ayé mi, àti lẹ́nu iṣẹ́ ìránṣẹ́—àwọn ìgbà tí mo bá ara mi tí mo ń ronú pé, Kí ló dé tí mo fi ń ṣe èyí?tí mó sì ní ìdí ogún tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀—Mo ti ní láti tún ìwòye àfojúsùn mi ṣe sí góńgó tí ó ga jùlọ tí ó nííṣe pẹ̀lú àkókò àti ìdí tí Ọlọ́run fi pè mí. Èyí ló ń gbé mi ró láwọn àkókò tí nǹkan le koko fún mi. Òhun ni ìdí ti ó ràn mí lọ́wọ́ láti máa sá èrè ìje náà, nígbà tí báwo ò bá ní ìtumọ̀ kankan.Ó ṣeéṣe kì ó jẹ́ ibi tí o ti ń ní ìṣòro lónìí nìyí. Ó ṣeéṣe kí apá kan ìdáhùn náà jẹ́ láti mú ọ fiyèsí ìbéèrè Kílósè jẹ́ rẹ. Ohun tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ jù lọ ni pé kì á má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan tí kò ní pẹ́ dópin, èyí tí ó lè tẹ́ wa lọ́rùn lójú ẹsẹ̀, pín ọkàn wa níyà, kí a lè parí eré ìje wa kí a sì gba èrè wa. Ẹ jẹ́ kí a yí ojú wa, ọkàn wa àti èrò inú wa padà si odo Jésù. Ẹ jẹ́ ká pinnu láti parí eré ìje wa àti iṣẹ́-ìránṣẹ ̣ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí Lúùkù ṣe kọ, kí a lè jẹ́rìí sí ìhìn rere ti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
Àdúrà
Jésù, ète mi ni láti parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́-ìránṣẹ tí mo gbà lọ́wọ́ Rẹ. Jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣe é. Ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa wo Ọ, èrè tí ó ṣe pàtàkì jù lọ. Ní orúkọ Rẹ, ámín..
Máa Bá Ìrìn Àjò Rẹ Lọ
Àtòjọ ìkàwé yìí ni wọ́n mú láti inú You're Not Finished Yet láti ọwọ́ Christine Caine. Ka àlàyé sí i níbí ChristineCaine.com/Devo
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ṣé o ní ohun tí o pè fún láti lọ sí ibi tí ó jìnà? Láti rìn nínú ninu èrèdí rẹ fún ìgbà pípẹ́? Àárín ìgbìyànjú èyíkéyìí— iṣẹ́-àmọ̀dá, áwọn ìbátan, iṣẹ́-ìránṣẹ́, ìlera—ní ìgbà gbogbo jẹ́ ìgbátí aibalẹ ati ifarada wa máa ń kùnà nítorí àwọn àkókò tí a bá bá ohun kan dé àárín yẹn ní ọ̀pọ̀ ìgbà kún fún réderède a sì máa nira. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn yii, Christine Caine rán wa létí pé a lè lọ sí ibi tí ó jìnà - kìí ṣe nítorí a ní agbára ṣùgbọ́n nítorípé Ọlọrun Níi.
More