Kò ì Tí ì Tán Fún ỌÀpẹrẹ

Eré-ìje Gígùn Tí A Pé Ní Ilé Ayé Yí
Mó nífẹ̀ẹ́ láti sáré, bótilẹ̀jẹ́pé eré ṣíṣá kò mọ mi lára tó bẹ́ẹ̀. Èrò mi nípa eré ṣíṣá jẹ́ eré ìdárayá oníbùsọ̀ márùn tí ań sá ni jẹ̀lẹ̀nkẹ̀, nígbà tí mo bá sọ pé jẹ̀lẹ̀ǹkẹ̀, mo ń sọ wípé tí àwọn ìyá bá gbé àwọn ọmọ wọn sì inú kẹ̀kẹ́ tí wọn sì táárí wọn síwájú àwọn ọmọdé wọ̀nyí yóò yá mi silẹ. Ọrẹ mi Dawn, ẹni ti a jìjọ̀ ń gun awọn oke-nla, ni olùsáré gidi. Ní ìgbà gbogbo ni ó máà ń kópa nínú àwọn eré-ìdíje gígùn ati pe o ti ṣe ìgbé-dúró ohun méjèèjì tí ì ṣe ìfaradà tí ara àti ti ọpọlọ láti lọ si irú àwọn ibi tí ó jìnnà bẹ́ẹ̀. O sáré tó láti mọ ohun ti o jẹ́ lati dé ibi tí ó jẹ́ odi ní àkókò ti o ń sáré, erongba kán ti èmi kò tì í ni ìrírí rẹ nitori pe o han gedegbe ni pé èmi kò sáré tó bẹ́ẹ̀ rí!
Dídé ibi odi kan jẹ ibi ti àwọn olùsáré le fi yege nìkan nípa ìmúlò ọkan wọn. O jẹ ìmúlò ọpọlọ ju ti ara lílò lọ, paapaa nigba ti ara bá wà nínú ìrora. Nígbà kan Dawn ṣe àlàyé fún mi nipa àpèjúwe ohun ti o ṣẹlẹ̀ nínú èrè-ìje gígùn rẹ àkọ́kọ́. Ó wá ni ibùsọ̀ mẹ́tàlélógún nígbàtí o kan odi ailokiki ná. Ó kú ìṣẹ́jú mẹ́rìndínlógójì láti sá ibùsọ̀ mẹ́ta àti díẹ̀ tí ó kú kí ó parí rẹ. Ìbá má jẹ ọ̀ràn rárá tí kò bá ṣe pé òun ti sá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùsọ̀ tẹ́lẹ̀ àti wípé tí kò bá ní ìrora tí ó ní agbára ni ibadi rẹ apá òsì. Bí ó ti n sọ eyi, ọpọlọ rẹ apa osi (tí ọgbọn tí ń wá) sọ fún u pé kí ó dúró ati ki o rin èyí tí ó kú yí. Àwọn èrò bí ì,Máṣe yọ ara rẹ lẹ́nu láti dé ojú ìlà ìparí náà. Àwọn ènìyàn yóò ní òye nígbàtí wọn ba ṣe àkíyèsí bí èrè ìje náà tí gbóná tó àti pẹ̀lú Ìpalára tí mo ní, bi àárá ni ó ṣe dùn ni orí rẹ. Ṣùgbọ́n ó gbọ́ ariwo, bí ọpọlọ rẹ apá ọ̀tún se sán àárá padà, Ìrètí ṣi wá síbẹ̀! Eré-ìjẹ náà kò ti ì parí rárá! Ó sí ṣeé ṣe fún mi láti de ojú ìlà ni àsìkò tí ó yẹ. Má ṣe dẹ́kun ère ṣíṣá rárá!
Ǹjẹ́ o ti rí ara rẹ rí nínú irú ogun ọpọlọ bẹ́ẹ̀ bi? Nígbàtí ọkàn rẹ bá ń pariwo si ọ létí? Nínú èrè-ìje irú èyí ń ṣẹlẹ̀ nígbàtí o ba kan odi kan, nígbàtí ìwọ kò ni ìgbésẹ̀ míràn ti o kù láti gbé, nígbàtí ó bá ti lo gbogbo agbara ati ohun gbogbo ti o wà nínú rẹ tí ó sì fẹ́ pẹ̀hìndà. Àti síbẹ̀síbẹ̀, bi Dawn ti ni iriri yí, ibikan wá ni ìsàlẹ̀ inú rẹ, ti o dàbí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ ìlépa tàbí àfojúsùn ń bẹ̀bẹ̀ pé kí a má pa òun rẹ́.
Mó ti wa ni irú ibi kan ri, ní ibi tí mo ti dé ibi odi kan nipa ti ẹmi, nípa ọpọlọ, ati nípa ẹdun. Ṣùgbọ́n ni àkókò kan náà, Mó ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ọkan ati oókan àyà mi. Mó tí ni àwọn ìlérí Ọlọ́run ti ń dún lemọ́ lemọ́ nínú mi ni àkókò kan náà ọkan mi ń pariwo fún mi láti da dúró. Àti nítorí àwọn ìlérí Rẹ̀, ìrètí yẹn, ó ṣeé ṣe fún mi láti máà tẹ́ síwájú nípa fífi Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sì ọkàn mi. Láìka iye ìgbà tí ọkàn mi bá mi jà láti jáwọ́, mó sáà ń darí ọkàn mi kúrò nínú ohun tí ó fẹ́ rò nípa rẹ àti sí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ó jẹ́ òtítọ́.
Bóyá o ti wa ni irú ibẹ̀ yẹn nísinsìnyí. Kini ọkan rẹ n pariwo si ọ létí? Ṣe wípé kò ṣeé ṣe àbí? Tàbí wípé ó ti pẹ ju? Tàbí wípé ìwọ kò wà ni Ìmúrasílẹ̀? Tàbí ìwọ kò já fáfá tó? Tàbí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé julọ? Tàbí wípé ó ti dàgbà jù? Tàbí ṣe ó kọ ẹkọ to? O le ṣẹgun ogun náà nínú ọkàn rẹ nípa ìsọdọ́tun àwọn èrò inú rẹ pẹ̀lù àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. O lè ní ìfaradà nípa mímú ohùn Ọlọ́run ga ju ohùn míràn lọ ni orí rẹ.
Adura
Baba wa ti mbẹ ni ọrun, Ó ṣeun fun Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Rán mi lọ́wọ́ láti tẹ́ síwájú nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kí èmi bá a lè yípadà nípa ìsọdọ́tun èrò inú mi, ati nitorinaa kí èmi lè lá odi èyíkéyìí kọjá. Ní orúkọ Jésù’, Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ṣé o ní ohun tí o pè fún láti lọ sí ibi tí ó jìnà? Láti rìn nínú ninu èrèdí rẹ fún ìgbà pípẹ́? Àárín ìgbìyànjú èyíkéyìí— iṣẹ́-àmọ̀dá, áwọn ìbátan, iṣẹ́-ìránṣẹ́, ìlera—ní ìgbà gbogbo jẹ́ ìgbátí aibalẹ ati ifarada wa máa ń kùnà nítorí àwọn àkókò tí a bá bá ohun kan dé àárín yẹn ní ọ̀pọ̀ ìgbà kún fún réderède a sì máa nira. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn yii, Christine Caine rán wa létí pé a lè lọ sí ibi tí ó jìnà - kìí ṣe nítorí a ní agbára ṣùgbọ́n nítorípé Ọlọrun Níi.
More