Kò ì Tí ì Tán Fún ỌÀpẹrẹ

You're Not Finished Yet

Ọjọ́ 2 nínú 5

A Dá Ọ Láti Tẹ̀síwájú

Àmìn ìjọba Ọsirélíà jẹ́ àpẹẹrẹ àmìn tí ó ń mú kí òye kún, àmìn yìí ṣe pàtàkì sí mi nítorí pé Ọsirélíà ni a ti bí mi tí a sì ti tọ́ mi dàgbà àti wípé ó ní ìtumọ̀ fún mi lọ́pọ̀lọ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan. Ẹranko méjì gbé àpáta kan lọ́wọ́—kangarúù pupa àti ẹyẹ ńlá kan tí ó ń jẹ́ emu. Kìí ṣe nítorí pé wón jẹ́ abínibí ilẹ̀ Ọsirélíà nìkan ni wọ́n ṣe yàn wọ́n ṣùgbọ́n nítorí pé a ṣẹ̀dá wọn láti máa lọ síwájú.

 

Emu, ẹyẹ ńlá, tí kìí fò tí ó sì kéré díẹ̀ ju ẹyẹ ògòngò tíí ṣe ìyekan rẹ̀ lọ, ni a mọ̀ fún ìyára rẹ̀, ìgbésẹ̀ rẹ̀ kan fẹ̀ tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà  mẹ́sàn-án nígbà tí ó bá ń fi gbogbo agbára sáré. Òun ni ẹyẹ kan ṣoṣo tí ó ní iṣu ẹ̀yìn ẹsẹ̀—bíi ti ènìyàn. Síbẹ̀síbẹ̀, kò lè rìn sí ẹ̀hìn. Iwájú nìkan ni ó lè lọ.

 

Kangarúù pupa—bíi àwọn kangarúù ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó kù—máa ń bẹ́ sí iwájú ni. Wọn a ti ara wọn sí iwájú pẹ̀lú ẹsẹ̀ wọn níńlá méjèèjì lẹ́ẹ̀kan náà wọ́n á sì lo ìrù wọn ṣe òdiwọ̀n kí wọ́n má baà fì sí ẹ̀gbẹ́ kan ju ọ̀kan lọ. Àpapọ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì tí ó ní agbára, ìtẹ̀lẹ̀ níńlá, àti ìrù máa ń ran kangarúù lọ́wọ́ láti ggbésẹ̀ sí iwájú ní ọ̀nà tí ó dára. Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kan síi, iwájú nìkan ni wọ́n lè lọ—wọn kò lè lọ sí ẹ̀hìn.

 

Ní ìgbà tí mo bá ronú wọn àti pé wọ́n jẹ́ ẹ̀dá tí Ọlọ́run dá tí kò lè rìn lọ sí ẹ̀hìn, n kò lè ṣe aláìronú nípa wa—àwa ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run, àgbàyanu ìṣẹ̀dá mìíràn tí a dá láti rìn ní ọ̀nà kan náa.

Ó yé mi pé a ní láti máa b’ojú wo ẹ̀hìn láti ìgbà dé ìgbà kí á rántí ǹkan tí ó ti kọjá kí á lè tẹ̀síwájú, àti pé ní ìgbà mìíràn ǹkan máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa tí á mú wa rò pé a ti padà sẹ́hìn, ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ olódodo láti gbé wa dìde áti láti mú wa máa tẹ̀síwájú. Orí ìrìn àjò ni gbogbo wá wà ibi yóò wù tí a dé nínú rẹ̀. Ní àwọn ìgbà kan à máa tẹ̀síwájú ní kánkán, nígbà mííràn kò sì níí yá tó bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ní àpapọ̀, à ń tẹ̀síwájú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè dúró díẹ̀ kí á sì b’ojú wo ohun tí ó ti kọjá, a kò ní dúró pa síbẹ̀, àbí? Ìgbà mélò ni a ti gbà ki àkókò ìjákulẹ̀, ìbanilọ́kànjẹ́, àì-tẹ́wọ́-gbani, tàbí ẹ̀rù dí wa lọ́nà láti tẹ̀síwájú? Òní jẹ́ ọjọ́ tí ó dára láti di ọwọ́ Jésù mú, kí á sì gbé ìgbésẹ̀ tí ó kàn sí iwájú, gẹ́gẹ́ bíi ẹyẹ emu àti kangarúù pupa.

 

Ẹ jẹ́ kí á gba ìmọ́ràn Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Fílípì pé, kí á gbàgbé ohun tí ó ti kọjá kí á sì máa nàgà wo ohun tí ó wà ní iwajú. A kò lè yí ohun tí ó ti kọjá padà. Kò ṣeé ṣe rárá. Ṣùgbọ́n a lè ní ipa ní orí ọjọ́ iwájú wa. A lè máa f’aradà nínú ìgbàgbọ́, kí á máa nàgà sí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe èètò fún wa. A lè máa tẹ̀síwájú ní ọ̀nà kan ṣoṣo eléyìí tí a ṣẹ̀dá wa láti rìn.

 

Ẹyẹ emu. Kangarúù pupa. Àti ìwọ́. Gbogbo wọ̀nyí ni a ṣẹ̀dá láti máa lọ sí iwájú. Kìí ṣe sí ẹ̀hìn láéláé. Ẹ jẹ́ kí á jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run dá wa láti jẹ́ kí á baà lè ṣe gbogbo ohun tí Ó pè wá láti ṣe!

Àdúrà

Bàbá Ọ̀run, a dúpẹ́ pé kódà nínú ìṣẹ̀dá Ẹ fún wa ní àwọn àpẹẹrẹ. Ẹ fún wa ní òye. Ẹ ràn wá lọ́wọ́ láti rìn ní ọ̀nà tí Ẹ ṣẹ̀dá wa láti rìn sí—iwájú, láì rìn sí ẹ̀hìn láeláe. Ní orúkọ́ Jésù, àmín.

Ìwé mímọ́

Day 1Day 3

Nípa Ìpèsè yìí

You're Not Finished Yet

Ṣé o ní ohun tí o pè fún láti lọ sí ibi tí ó jìnà? Láti rìn nínú ninu èrèdí rẹ fún ìgbà pípẹ́? Àárín ìgbìyànjú èyíkéyìí— iṣẹ́-àmọ̀dá, áwọn ìbátan, iṣẹ́-ìránṣẹ́, ìlera—ní ìgbà gbogbo jẹ́ ìgbátí aibalẹ ati ifarada wa máa ń kùnà nítorí àwọn àkókò tí a bá bá ohun kan dé àárín yẹn ní ọ̀pọ̀ ìgbà kún fún réderède a sì máa nira. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn yii, Christine Caine rán wa létí pé a lè lọ sí ibi tí ó jìnà - kìí ṣe nítorí a ní agbára ṣùgbọ́n nítorípé Ọlọrun Níi.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christine Caine - A21, Propel, CCM fún ìpèsè ètò yìí. Tí o bá fẹ́ mọ̀ sí, lọ sí: https://www.christinecaine.com