Kò ì Tí ì Tán Fún ỌÀpẹrẹ

Ìgbàgbọ́ fún Agbede-méjì
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé nígbàtí àwọn eléré-ìje pàtàkì bá ṣe ìgbáradì fún èrè-ìje kan, wọ́n ń gbáradì fún agbede méjì ni? Bí ó ṣe yéni si, agbede méjì èyíkéyìí eré-ije jẹ apákan ti o nira jùlọ. O jẹ ibi tí okun àti agbára olùsáré tí bẹ̀rẹ̀ sí ní pin, bákannáà ìrẹ̀wẹ̀sì ọpọlọ láti tẹ́ síwájú. Bóyá arákùnrin tàbí arábìnrin jẹ olùsáré ibi kúkurú tàbí ọ̀nà tí ó jìnnà, ti wọn kò bá ṣiṣẹ́ tọ agbede méjì, wọn kì yóò lè dé ìparí ìlà. Ó dàbí pé ó rọrùn gidi, ṣùgbọ́n ó nílò ìgbáradì tó múná dóko láti ṣe àṣeyọrí.
Ní ìwòye tí ẹ̀mí, ṣé kò ṣe àìjẹ́ fún agbede-méjì ni ọ̀pọ̀ ìgbà láyé wa ni ẹ̀kọ́ àti ìgbáradì wa dúró lé? Ronú nípa rẹ̀ lọ́nà yìí: a bí wa ní ọ́jọ́ kan, ní sísọ̀rọ̀ nípa ti ẹ̀mí, lẹ́yìn náà a bẹ̀rẹ̀ eré ìje yìí, èyí tí í ṣe ìrìn àjò wa nínú Krístì ní órí ilẹ̀ ayé, gbogbo rẹ̀ ní ìrètí láti kọjá ìlà àṣeyọrí lọ́jọ́ kan, kí á sì gbọ́ pé a ṣe dáadáa nínú eré-ije ti a sá. 1 Àlàyé yìí lè dàbí àsọjẹ, ṣùgbọ́n ó ṣe kòkárí ìgbésí ayé wa dáadáa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Ní ọjọ́ kan, nígbàtí mó bá parí eré ìje mi, mo fẹ́ láti sọ bí í ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé,“Mo ja ìjà rere náà, mo ti parí eré náà, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.” (2 Tímótì 4:7), ṣugbọn lati ṣe bẹ, mo ni lati kọ́kọ́ la agbedé méjì kọjá.
Láti lá agbedé méjì—ohun gbogbo kọjá—o nílò ìfaradà. Òǹkọ̀wé ìwé Hébérù kọ̀wé pé: “Nítorí ẹ nílò ìfaradà, pé nígbà tí ẹ bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ lè gba ohun tí a ṣe ìlérí fún yin.” (Hébérù 10:36).
Ìfaradà ni a túmọ̀ sí déédéé bí “okun tàbí agbára láti tẹ́ síwájú láì bìkítà àárẹ̀, wàhálà tàbí àwọn ipò búburú. “2 Ó jẹ agbára láti fara dà lábẹ́ àwọn ipò ti o nira. Agbára láti kojú ìrora tàbí àwọn ìnira. O jẹ ìgboyà ìrètí tí ó dúró de òpin. Nínú èdè Gíríìkì tí a fi kọ Májẹ̀mú Tuntun, ó jẹ́hupomone, àkópọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó túmọ̀ sí “láti wà lábẹ́.”3 Ójẹ́ ààmì ìdá-yàtọ̀ tí ó ń gbilẹ̀ nígbàtí a bá dúró sṣinṣin nínú ìdààmú—ohun kan tí ìṣẹ́dá wa ma ń fẹ́ láti sá fún—ó sì dà bí ẹnipé ó ni ipá púpọ̀ lórí wá ní ipò agbedé méjì wa.
Ní àárín àwọn ọrẹ wa.
Ní àárín ìbásepọ̀ gẹ́gẹ́ bí takọ-tabo.
Ní àárín àwọn ìgbéyàwó wa.
Ní àárín bí òbí ṣe ń tọ́ ọmọ.
Ní àárín bí a ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ́ wa.
Ní àárín fífi ẹsẹ̀ àwọn iṣẹ́ wá múlẹ̀.
Ní àárín ìdùbúlẹ̀ àìsàn.
Ní àárín ọ̀ràn ni ilé-ẹjọ́.
Ní àárín àjàkálẹ̀àrùn kan.
Ní àárín ìyípo padà.
Ní àárín ohun kan ti a ni ìrètí pé àdúrà wa yóò wá sí ìmúṣẹ.
Ní àárín dídúró de àwọn ìdáhùn ẹ̀bẹ̀ àdúrà wa.
Àárín ohunkóhun jẹ, ibi ti o nira jùlọ, à tún ma jẹ́kí ohun gbogbo sú ni pátápátá. O jẹ ibi ti a ti ni ìdojúkọ púpọ̀ jùlọ, ṣe kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni? Ó jẹ́ ibi ti gbogbo ǹkan ti a fẹ ni láti dáwọ́ ohun gbogbo dúró.
Ṣùgbọ́n bí a bá mú ìfaradà dàgbà si, agbára yẹn tí òǹkọ̀wé Hébérù sọ fún wa pé a ó nílò, bí a bá fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ ara wa, àti nípa agbára ti Ẹ̀mí Mímọ́ lẹ́yìn náà a ó níó èròjà tí ó yẹ láti kọjá ipò àárín. Ati pe kìí ṣe agbedemeji kan yìí ṣoṣo, ṣugbọn gbogbo àárín yó wù tí a lè là kọjá.
Àdúrà
Baba Ọrun, jọ̀wọ́ ràn wá lọ́wọ́ láti ni ìfaradà dáradára bí a ṣe ń lọ la àárín ohun gbogbo tí a ó lá kọjá. Rán wa lọ́wọ́ láti sá èrè-ìje wá dáradára, pé ní ìgbà ti a bá sì ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, a ó lè gbà ohun ti a ti ṣe ìlérí rẹ fún wa. Ní orúkọ Jésù, Àmín.
Àwọn Ìtọ́kasí:
1. Hebrews 10:36
2.Merriam-Webster, s.v. “endurance,” https://www.merriam-webster.com/dictionary/endurance.
3. J. Strong, A Concise Dictionary of the Words in the Greek Testament and the Hebrew Biblel (Bellingham, WA: Logos Bible Software, 2009), 1:74.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ṣé o ní ohun tí o pè fún láti lọ sí ibi tí ó jìnà? Láti rìn nínú ninu èrèdí rẹ fún ìgbà pípẹ́? Àárín ìgbìyànjú èyíkéyìí— iṣẹ́-àmọ̀dá, áwọn ìbátan, iṣẹ́-ìránṣẹ́, ìlera—ní ìgbà gbogbo jẹ́ ìgbátí aibalẹ ati ifarada wa máa ń kùnà nítorí àwọn àkókò tí a bá bá ohun kan dé àárín yẹn ní ọ̀pọ̀ ìgbà kún fún réderède a sì máa nira. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn yii, Christine Caine rán wa létí pé a lè lọ sí ibi tí ó jìnà - kìí ṣe nítorí a ní agbára ṣùgbọ́n nítorípé Ọlọrun Níi.
More