Kò ì Tí ì Tán Fún ỌÀpẹrẹ

Bí Àkókò Ìfúrúgbìn àti Ìkórè Ti Dájú
N jẹ́ o ní àlá kan? Èrò kan? Ìpòngbẹ láti ṣe ohun kan tí ó kọ̀ láti lọ tí o mọ̀ pé Ọlọ́run ni ó fi sí ọ ní ọkàn? Nígbà tí Ọlọ́run bá fún wa ní àlá, Ó ń pe ohun tí ó ti fi sí inú wa kí á tóó bí wa sí ayé jáde ni. A kún fún agbára láti lè mú ètò àti ète Rẹ̀ fún ìgbésí ayé wa ṣẹ. Síbẹ̀, ó kù sí wa lọ́wọ́ láti bu omi rin irúgbìn àmúṣagbára yìí, kí á tún èrùpẹ̀ ọkàn wa ṣe, kí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti fi sí inú wa kí ó lè dàgbà.
Ronú sí i ní ọ̀nà yìí: Ọlọ́run fún àwọn igi ní ipá láti bí irú ara wọn nípasẹ̀ irúgbìn wọn. Tí o bá ti tú kóònù ọ̀pẹ-òyìnbó palẹ̀ rí, wàá rípé ó ní àwọn irúgbìn kékèké, ìkọ̀ọ̀kan wọn ní “ìyẹ́” kan tí ó so mọ́ ọn. Ìdí ni pé kí afẹ́fẹ́ lè gbé irúgbìn yí lọ sí ibi tí yóò ti lè bọ́ sílẹ̀ tí yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìdí múlẹ̀. Ní ilẹ̀ tí ó dára, ní agbègbè tí ó dára, írúgbìn yìí yó hù yó sì dàgbà títí tí yó fi di igi gidi. Igi tí ó dàgbà yí wà nínú irúgbìn ní gbogbo ìgbà yí, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó ríi títí tí a fi rìí bọ inú erùpẹ̀ tí ó dára lẹ́hìn ìgbà tí òjò àti òòrùn wá ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
Lọ́nà kan náà, àwọn irúgbìn tí ó wà nínú ọkàn wa—àwọn àlá àti èrò àti ètò àti ète Ọlọ́run—á máa dàgbà bí a ṣe ń bu omi rin wọ́n pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Àwọ́n irúgbìn yìí ń dàgbà bí a ṣe ń tún ọkàn wa ṣe, tí à ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wọn tí a sì ń ṣe àmúlò rẹ̀ nínú ayé wa, nípa bẹ́ẹ̀ ọkàn wa á di ilẹ̀ tí ó dára.
Èrò àti ète Ọlọ́run fún ayé wa ń dàgbà si bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú Rẹ̀, tí à ń gbilẹ̀ nínú ìfaradà, tí a sì ń dúró títí tí àwọn ètò yìí yó fi yọrí. Báyìí ni a ṣe ń bí àwọn àlá wa, pẹ̀lú àwọn èrò tí Ọlọ́run ń fún wa. Agbára yìí wà níbẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n ó wà gẹ́gẹ́ bí irúgbìn ni títí tí a ó fi ṣe ohun tí ó yẹ láti mú kí ó dàgbà.
Ọlọ́run fẹ́ kí á dàgbà bá ibi tí ó yẹ kí á lọ mu. Ìpèníjà tí ó wà ni pé kò bá àṣà mu. Ó rọrùn púpọ̀ láti yára mọ́ ohun tí a lè lò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ohun tí a lè ya fọ́tò rẹ̀ tàbí kí a ká fọ́nrán sílẹ̀, ohun tí a lè bèèrè fún kí á sì rí gbà lóòjọ́, ṣùgbọ́n kìí ṣe bí ètò Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ nìyí. Wọn kìí ṣe ohun ẹsẹ̀kẹsẹ̀. Iṣẹ́ Ọlọ́run máa ń gba àkókò. Pẹ̀lú irúgbìn kan tí ó nílò àmójútó.
Njẹ́ o mọ ètò Ọlọ́run fún ayé rẹ? Njẹ́ o lè ní ìmọ̀lára ohun àmúṣagbára kankan tí ó wà ní àìlò nínú rẹ? Ohun àmúṣagbára ni ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin ohun tí ó jẹ́ gangan àti ohun tí ó ṣeé ṣe. Ó jẹ́ ipá tí a kò fi hàn, agbára tí ó wà ní ìpamọ́, àṣeyorí tí a kò mọ̀, àwọn ẹ̀bùn tí ó ń sinmi, àti àwọn tálẹ̀ntì tí ó fi ara pamọ́ tí ó ń dúró láti dàgbà sókè. Ènìyàn tí ó kù kí o dà ni. Ó jẹ́ ibi tí o lè lọ ṣùgbọ́n tí o kò tíì dé. Ó jẹ́ gbogbo nnkan tí o lè ṣe ṣùgbọ́n tí o kò tíì ṣe. Ó jẹ́ ibi tí o lè dé ṣùgbọ́n tí o kò tíì fi ojú sí.
Kò nílò kí o mọ gbogbo ètò àti èrò Ọlọ́run fún ọ, nítorí pé pẹ̀lú àkòkò, ọ̀pọ̀ rẹ̀ ń fi ojú hàn, ṣùgbọ́n ṣé o mọ ọ̀kan nínú wọn? Bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú irúgbìn yẹn lónìí kí o sì máa wò ó bí ó ti ń bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà. Ó dájú bíi àkókò ìfúrúgbìn àti ìkórè.
Àdúrà
Bàbá Ọ̀run, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti tọ́jú àwọn irúgbin àmúṣagbára tí O fi sí inú mi. Mo fẹ́ dàgbà níbi tí O fẹ́ kí n lọ. Ní orúkọ Jésù, àmín.
Nípa Ìpèsè yìí

Ṣé o ní ohun tí o pè fún láti lọ sí ibi tí ó jìnà? Láti rìn nínú ninu èrèdí rẹ fún ìgbà pípẹ́? Àárín ìgbìyànjú èyíkéyìí— iṣẹ́-àmọ̀dá, áwọn ìbátan, iṣẹ́-ìránṣẹ́, ìlera—ní ìgbà gbogbo jẹ́ ìgbátí aibalẹ ati ifarada wa máa ń kùnà nítorí àwọn àkókò tí a bá bá ohun kan dé àárín yẹn ní ọ̀pọ̀ ìgbà kún fún réderède a sì máa nira. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn yii, Christine Caine rán wa létí pé a lè lọ sí ibi tí ó jìnà - kìí ṣe nítorí a ní agbára ṣùgbọ́n nítorípé Ọlọrun Níi.
More