Dídaríji àwọn tó páwa láraÀpẹrẹ
Mímú Ojú Kúrò Nínú Àṣìṣe
Ojoojúmọ́ ni à ǹṣe àkíyèsí àwọn ìrírí tí à ń lá kọjá kí a baà lè rántí wọn lọ́jọ́ iwájú- n'írètí pe pẹlú ìdùnnú ni. Sùgbọ́n nígbà míràn àwọn àjálù burúkú á ṣẹlẹ̀ tí yíò ní ipa láíláí nínú ayé wa. Nígbà míràn àléébù á wáyé látàrí ìgbésẹ̀ tó mẹ̀hẹ tí ẹlòmíràn ṣe. Ọ̀mùtí awakọ̀ lè má f'ara káása ohunkóhun tí ẹni tó gbé sínú ọkọ̀ lè f'ara gb'ọgbẹ́ láíláí nínú ara tàbí kí ọkàn wọn má rí bákannáà mọ̀ láí. Ẹnìkán lè mú ìfarapa ńlá bá ènìyàn látàrí àìkíyèsára rẹ̀ tàbí ìwà ànìkànjọpọ́n rẹ̀. Báwo ni a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí níí r'onú àti ṣe àforíjì irú àwọn àṣìṣe wọ̀nyí?
Ìdáríjì ni kí á mọ̀ọ́mọ̀ jọ̀wọ́ àwọn àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn. O yàn láti má rántí àṣìṣe ẹlòmíràn. Sáàmù 103:8-12 ṣe àfihàn bí Ọlọ́run tí ń f'inú fíndọ̀ d'áríjì ni. “Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí” (bíótilẹ̀jẹ́pe Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀), àti “Bì ìlà-õrùn ti jìnà sí ìwọ̀-õrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ìrékọjá wa jìnà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Èyí jẹ́ ìjìnnà síra ayérayé; ààlà ayé méjèèjì tí kìí pàdé. Ọlọ́run f'inú fín'dọ̀ mú éṣẹ̀ wa kúrò níwájú Rẹ̀ kò sì rántí wọn mọ́ láí! Báwo ni a ṣe lè ṣe àmúlò irú ìdáríjinni yìí? Ìfẹ́ tí Ẹ̀mí-mímọ́ fi kún ọkàn wa nìkan ló lè yí wà l'ọ́kàn padà láti má "rán oró l'ára ẹni tó ṣẹ̀ wa” (1 Kọ́ríntì 13:5). Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nìkan ló máa ń mú irú Ìdáríjì yìí wà lọkàn wa a sì máa ruú sókè nípa ìfẹ tòótọ sí ọmọlàkejì.
Ó ṣòro kí a dáríji ẹlòmíràn nígbàtí àfojúsùn wa bá dá lórí ìnira àti ìṣòro tí ó d'ojú kọ wá. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ìwòye ìhà tí Ọlọ́run kọ sí ìkọ̀sẹ̀: “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16). Ìfẹ̀ Ọlọ́run sí wa ló mú kí Ó fi ọmọ Rẹ̀ ṣe ìrúbọ kí Ìdáríjì baà lè wà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ṣé báyìí náà ni o yẹ k'áwa náà máa d'áríjì? Bẹ́ẹ̀ni! Ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa agbára wa! A ò le ṣàì má rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá láyé wa. Àwọn nkán míràn wà tí a kò le "gbàgbé" láíláí. Ṣùgbọ́n ṣé à ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn "àṣìṣe” ẹlòmíràn ni? Ṣé ní gbogbo ìgbà tí a bá rí ẹni tó ṣẹ̀ wà ní a máa ń rántí gbogbo ohun búburú tó ti ṣe s'íwa?
Ìdáríjì bíi ti t'Ọlọ́run kìí mú wa n'íyè lọ, ṣùgbọ́n a máa mú kí á gbàgbé gbogbo àṣìṣe tó ti kọjá, kí a sì gbé ìgbé ayé tí àjọṣepọ̀ rẹ̀ dánmọ́rán. Láì pẹ́ láì jìnnà, àti pẹlú Ẹ̀mí Ọlọ́run, a ó ṣàkíyèsi pé ìfẹ ti d'ípò gbogbo èròkerò àti dúnkùú tí a lè ní lọkàn sí àwọn tó ṣẹ̀ wá.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bóyá a nje ìrora ojú ogbé okàn tàbí tí ara, ìdaríji ní ìpìlê ìgbé ayé Kristẹni. Jésù Kristi nírírí onírúurú ohun tí kò tọ̀nà àti hùwàsí ti kódà títí dé ikú àìtó. Síbè ní wákàtí tó kéyìn, o daríji olè tó ṣe yèyé é lórí àgbélèbú àti bákan náà àwọn múdàájọ́ṣẹ e.
More