Dídaríji àwọn tó páwa láraÀpẹrẹ

Forgiving Those Who Wound Us

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ìgbé Ayé Ìdáríjì

Lẹ́yìn tí Ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ bí a ti ń gbàdúrà, Jésù fún wọn ìtọ́sọ́nà pàtàkì nípa bí wọ́n ṣe lè jọ rìn pọ̀ ní ayé tó ti dorí kodò yí. Ó fi hàn wọ́n bí Baba ní ọ̀run ti ṣe wo ìbáṣepọ̀ wọn sí ara wọn, Ó sì fi ọ̀nà hàn wọ́n láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀ ọrẹ ọ̀fẹ́ Rẹ̀.

Kii ṣe oúnjẹ òòjọ́ wa nìkan ni Baba wa ń pèsè, bákan náà ni Ó ún pèsè ìtọ́ni ojojúmọ́. Ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ yìí ń sọ nípa àwọn àkójọ àṣìṣe ojojúmọ́, ìgúni-ọkàn, àti àìda tí wọ́n ti jẹ́ ara ìgbé ayé ìgbàgbọ́ wa nínú ayé tó ti ṣubú. Bàbá wa Ń wá ọ̀nà làti kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ ní agbọndan ayé yìí. Tí a bá sé ọkàn wa le sí àwọn ẹlòmíràn láti dárí jì (nítorí wón máa ń gún wa ní ọkàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀), Bàbá wa kún ojú òṣùwọ̀n láti fi wá sí abé ìbáwí Rẹ̀ títí a ó fi kọ́ ẹ̀kọ́ bí a ṣe ń dárí jì. Ó jẹ́ aláàánú ní bí bá ìgbéraga ọkàn wa wí àti láti rán wa létí àwọn àléébù wa.

Rín rìn nínú ìdáríjì túmọ̀sí pé ó yá wa lára láti gba ẹ̀bi sí ọmọnìkejì ká sì bèrè fún ìdáríjì wọn láì fi fa'lẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó tún túmọ̀sí pé àwa náà ṣe tán lati dárí jì àwọn tó ṣẹ̀ wá. Irú ìdáríjini yìí ṣeé ṣe nígbàtí a bá ṣe àṣàrò oun tí Bàbá ṣe nípa dí dárí jì wá nípasẹ̀ Kristì (Ephesians 4:32). Àwọn èébú àti ọgbé tí a gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn wọ́n kéré lẹgbẹ èyí tí Kristì f'ara gbà nítorí ẹ̀sẹ̀ wa lòdì Síi.

Gbígbé ìgbé ayé ìdáríjì fún wa ní àǹfààní láti fi ojú fo àwọn ìkọlù kéékèèké àti láti ní ìbáṣepọ̀ tí ó lè dojú kọ àwọn ẹ̀sẹ̀ ẹni sí ara ẹni ní ọ̀nà tí ó ní àláfíà. Irú ìgbésí ayé yìí pàápàá le rán wá lọ́wọ́ láti ayé tó kún fún àìṣòdodo bí Bàbá wa ti ríi—ayé tó nílò Olùgbàlà. Lẹ́yìn èyí, a lè kópa nínú ètò nílá Rẹ̀ láti ra ayé padà nípa jíjẹ́ àpẹẹrẹ òtítọ́ ìhìn rere ni ayé àwa tìkára wa.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Forgiving Those Who Wound Us

Bóyá a nje ìrora ojú ogbé okàn tàbí tí ara, ìdaríji ní ìpìlê ìgbé ayé Kristẹni. Jésù Kristi nírírí onírúurú ohun tí kò tọ̀nà àti hùwàsí ti kódà títí dé ikú àìtó. Síbè ní wákàtí tó kéyìn, o daríji olè tó ṣe yèyé é lórí àgbélèbú àti bákan náà àwọn múdàájọ́ṣẹ e.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Joni and Friends, International àti àwọn Olùtẹ̀jáde Tyndale House, àwọn tó ṣẹ̀dá Beyond Suffering Bible, fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.beyondsufferingbible.com/