Dídaríji àwọn tó páwa láraÀpẹrẹ

Forgiving Those Who Wound Us

Ọjọ́ 6 nínú 7

"Aṣọ Ẹgbẹ́jọdá" ti Krìstẹ́nì

A máa ń rí àwọn ènìyàn tí ó ń wọ aṣọ ẹgbẹ́jọdá ní oríṣìrísi ilé iṣẹ́. Gbogbo mọkálìkì, alásè, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìdúró ní ilé ìjẹun, òsìṣẹ́ ilé ìwòsàn, ọlọ́pàá àti àwọn panápaná ló máa ń wọ aṣọ àjọdá. Ní pàtó, àwọn ilé iṣẹ́ wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ tiwọn ni láti pèsè àti láti máa fọ̀ wọ́n. N jẹ́ nnkan kan wà tí ó ń jẹ́ "aṣọ ẹgbẹ́jọdá" Krìstẹ́nì? O dára, kìí ṣe aṣọ ti ara, ṣùgbọ́n nípa bí a ṣe ń tọ́jú ara wa! Ibi kíkà yìí gbà wá níyànjú láti "gbé ẹ̀wù wọ̀", èyí tó túmọ̀ sí pé kí á mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é pẹ̀lú ìdí. A ní láti múra bákannáà ní àwọn ọ̀nà kan pàtó. A ní láti wọ ara wa ní ẹ̀wù àánú, oore, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ àti sùúrù. Kí ló dé? Nítorí pé olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú àṣìṣe wọn ló wà lábẹ́ àwọn aṣọ ẹgbẹ́jọdá yìí. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àwọn àṣìṣe yìí fi ń wá. Nítorí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ṣèètò àwọn èròjà tí yóò mú kí Krìstẹ́nì yàtọ̀, O sì tún fún wa ni ohun èlò ìhùwàsí pàtàkì kan láti lè kápá àwọn àṣìṣe yìí - ìdáríjì.

Ìdáríjì jẹ́ ìhùwàsí ojoojúmọ́ àwọn àgbà onígbàgbọ́. Ọlọ́run ti yàn wá láti jẹ́ mímọ́. Jíjẹ́ mímọ́ túmọ̀ sí pé "kí á yà sọ́tọ̀" tàbí "kí á yà sí mímọ́" fún ìdí pàtàkì kan - kí ó dàbí Krístì. Ní ibi kíkà yìí, a yà wá sọ́tọ̀ láti fi ìfẹ́ Ọlórun hàn sí ọlúkúlùkù wa. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run mọ̀ pé gbogbo wa ni a máa ń ṣe àṣìṣe. Ọlọ́run ní àṣẹ lórí àwọn àṣìṣe yìí, ìrètí Rẹ̀ sì ni pé kí á gba àìpé olúkúlùkù wa! Ètò Ọlọ́run ni láti sọ àwọn onígbàgbọ́ di mímọ́ (yà sí mímọ́, yà sọ́tọ̀) nípa ìbáraẹniṣepọ̀ láàrin ara wọn. Nígbà tí a bá dáríjì, a wà ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ọmọ Ọlọ́run, Jésù Krístì. Àṣìṣe wa àti àṣìṣe ti àwọn ẹlòmiràn wá jẹ́ àńfààní láti lo ìwà rere ti ìdáríjì.

Ṣé o ṣetán láti jẹ́wọ́ àṣìṣe rẹ̀ (Jákọ́bù 5:16)? Ṣé o ṣetán láti wọ ẹ̀wù àánú, oore, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ àti sùúrù? Ṣé o ṣetán láti dàbí Krístì, kí o dárí ji àwọn tí ó ṣẹ̀ ọ́?

Ìdáríjì yẹ kí ó jẹ́ àmì ìdàpọ̀ àwọn onígbàgbọ́. À ń jẹ ànfààní gẹ́gẹ́ bí olóríjorí nígbà tí a bá ń gbé ìgbé ayé ìdáríjì. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ohun rere ló máa ń ti ẹ̀hìn dídáríji ara ẹni jáde: A ó ṣe Ọlọ́run lógo, a ó gbé Jésù ga, yóò sì di mímọ̀ fun gbogbo ayé tó ń wòye Rẹ̀. A jọ Krístì!

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Forgiving Those Who Wound Us

Bóyá a nje ìrora ojú ogbé okàn tàbí tí ara, ìdaríji ní ìpìlê ìgbé ayé Kristẹni. Jésù Kristi nírírí onírúurú ohun tí kò tọ̀nà àti hùwàsí ti kódà títí dé ikú àìtó. Síbè ní wákàtí tó kéyìn, o daríji olè tó ṣe yèyé é lórí àgbélèbú àti bákan náà àwọn múdàájọ́ṣẹ e.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Joni and Friends, International àti àwọn Olùtẹ̀jáde Tyndale House, àwọn tó ṣẹ̀dá Beyond Suffering Bible, fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.beyondsufferingbible.com/