Dídàgbà Nínú Ìfẹ́Àpẹrẹ

Growing in Love

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ìfẹ́ Tó Ń Gbilẹ̀ Sí I Máa Ń Gbé Àwọn Èèyàn Wọ̀

Ẹ má ṣe ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tàbí láti inú ìgbéraga òfìfo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi ìrẹ̀lẹ̀ẹ máa ka àwọn ẹlòmíì sí pàtàkì ju ara yín lọ, Ẹ má ṣe máa wá ire ti ara yín nìkan, ṣugbọn ẹ máa wá ire ti àwọn ẹlòmíràn. Fílípì 2:3-4 NIV (àfikún àlàfo)

Ìfẹ́ tó ń pọ̀ sí i máa ń jẹ́ kéèyàn máa ronú nípa àwọn ẹlòmíràn. Mi ò lè nífẹ̀ẹ́ rẹ bó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbájú mọ́ ohun tí mo fẹ́ ṣe, ìtẹ́wọ́gbà mi, ohun tó wù mí, tàbí àṣeyọrí tí mo máa ṣe. Nítorí náà, ká tó lè nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí àwọn ètekéte ọ̀tá tó lè mú ká máa gbájú mọ́ tara wa.

Mo gbagbọ ìyọlẹ́nu òun ni ohun ìjà tó ṣe pàtàkì jù lọ tí ọ̀tá wa nípa tẹ̀mí ń lò. Kí ni ọ̀tá wa fẹ́ ká máa ṣe? Ohun tó ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run ni. Bí àpẹẹrẹ:

  • Pípín ìhìnrere (iṣé́ ìgbàlà Ọlọ́run)
  • Àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run
  • Bá a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ ara wa

Àní, bí ọ̀tá náà bá lè mú ká pa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì wọ̀nyí tì fún àkókò gígùn tó, ó mọ̀ pé ìpínyà, ìdálẹ̀, àti ìparun ló máa yọrí sí.

Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ohun tó ń pín ọkàn níyà. Ohun yòówù tó lè mú kí ọkàn wa fà sí nǹkan míì ni. Àpẹẹrẹ kan tó wọ́pọ̀ nípa bí ohun tó ń pín ọkàn ẹni níyà ṣe lè rí nìyí: O ní àkókò díẹ̀ láti fi ṣòfò nígbà tó o bá ń dúró de àkókò kan, dípò tí wàá fi béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kó fún ẹ ní ẹnì kan tó o lè pè tàbí tó o lè gbàdúrà fún, ńṣe lo fi àkókò rẹ ṣòfò nítorí pé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, ìsọfúnni lórí tẹlifóònù, ìkànnì àjọlò orí íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí àwọn nǹkan míì ló gba àfiyèsí rẹ tó wà ní àdádó eré ìnàjú.

Mo ti wà níbẹ̀, mo ti ṣe é! Ó rọrùn gan-an láti sọ ọ́ dàṣà nítorí pé ó wà ní ìkáwọ́ wa.

Ṣùgbọ́n mi ò fẹ́ gbé ìgbésí ayé tí kò ní nǹkan kan lọ́kàn. Mi ò fẹ́ kí nǹkan máa bá a lọ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Mi ò ní gbàgbé láti rí ẹni tó wà níwájú mi. Mo fẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ bíi ti Jésù!

Ẹ jẹ́ ká jí mọ̀ pé lóòótọ́ a nílò ara wa gan-an ni. Kódà, àwọn ìwádìí fi hàn pé àjọṣe tó dára láàárín àwọn èèyàn máa ń ṣe wá láǹfààní nípa tara, nípa ti ìmí ẹ̀dùn àti nípa ti èrò orí.

Pinnu lónìí láti dá àjọṣepọ̀ tó nípọn àti ìbálòpọ̀ tó dúró sán-ún ṣe. Pinnu pé ojoojúmọ́ ni wàá máa fún àwọn èèyàn tó o bá pàdé níṣìírí. Pinnu láti gbé ìgbésí ayé tó fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn, kó o sì gbájú mọ́ iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

Ọkọ mi, Craig, ló ń fún mi níṣìírí tó bá dọ̀rọ̀ gbígbé ìgbésí ayé tó dá lórí àwọn ẹlòmíràn. Mo ṣe àkọsílẹ̀ bí mo ṣe máa ń rí i nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀. Mo nírètí pé yóò fún ìwọ náà níṣìírí:

  • Gbogbo ìgbà ló máa ń pè wá láti wádìí nípa ẹni tó ń jìyà.
  • Ó ń fi tọkàntọkàn gbàdúrà fún àwọn èèyàn.
  • Ó máa ń fi sùúrù kọ́ni tàbí kó fetí sílẹ̀.
  • Ó máa ń ṣe ohunkóhun tó bá yẹ kó ṣe láìka ohun tó máa ná an sí.
  • Ìdílé wa àti èmi ni ohun tó ṣe pàtàkì jù sí i.
  • Ó máa ń jẹ́wọ́, ó sì máa ń tọrọ àforíjì nígbà tó bá ṣàṣìṣe.
  • Ó máa ń ronú nípa ọ̀nà tó lè gbà jẹ́ ọ̀làwọ́.
  • Ó máa ń fi ìmọrírì àti ìmoore hàn nígbà gbogbo.
  • Ó fi ara rẹ̀ sí ìgbẹ̀yìn.
  • Ó máa ń fún ẹnìkan níṣìírí pẹ̀lú àwọn ìsọfúnni pàtó.
  • Ó máa ń rántí, ó sì máa ń mọyì ọjọ́ pàtàkì tí ẹnì kan pàdánù.
  • He asks engaging questions instead of talking about himself.
  • Gbogbo ìgbà ló máa ń pín oúnjẹ tó wà nínú àwo rẹ̀ fáwọn èèyàn!

Ìgbésí ayé Craig fi èso ti ẹ̀mí mímọ́ hàn. Àwọn ìgbésẹ̀ tí ó dàbí ẹni pé ó kéré ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ìṣòtítọ́ ti ìfẹ́ ìrúbọ jẹ́ èyí tí ó dúró ṣinṣin nítorí pé ó máa ń yàn láti tẹ̀lé ìwàláàyè Ẹ̀mí nínú ara rẹ̀. Ojoojúmọ́ làwa náà máa ń láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, wá àkókò láti ronú lórí àwọn ọ̀nà tó o lè gbà jẹ́ ẹni tó ń gba tàwọn ẹlòmíì rò.

Gbàdúrà:Bàbá, ṣí ọkàn àti ojú wa sí bí a ṣe lè gbé ìgbésí ayé tí ó dá lórí Ọlọ́run, tí ó dá lórí àwọn ẹlòmíràn. Ní pàtàkì, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa fiyè sí àwọn tó sún mọ́ wa jù lọ. Ǹjẹ́ kí a fi hàn pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a sì mọyì wọn nípa ìwà àti ọ̀rọ̀ wa. Ní orúkọ Jésù, ámín.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Growing in Love

Ohun tí ó ṣe pàtàkí ní pàtó ní fífẹ́ Ọlọ́run àti fífẹ́ ọmọlàkejì, ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe ṣe èyí dé ojú àmì? Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, a kò lè ní ìfẹ́ ẹlòmíràn dunjú nínú agbára ti ara wa. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá gbé ojú s'ókè sí Ọlọ́run tí a rẹ ara wa s'ílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀, a lè gbé ayé láti inú ògidì ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ní agbára. Kọ́ síi nípa dídàgbà nínú ìfẹ́ nínú Ètò-ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọ́jọ́-5 láti ọwọ́ Olùṣọ́-àgùntàn Amy Groeschel.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/