Dídàgbà Nínú Ìfẹ́Àpẹrẹ
Ìfẹ́ Tí Ó ń Gbèrú Ní Ìrẹ̀lẹ̀ Nínú
Ǹjẹ́ o fẹ́ràn láti máa kọ iṣẹ́-ọwọ́, tàbí ní ìmọ̀, titun? Mo ti ń kọ́ èdè Spanish lórí ẹ̀rọ alágbèéká mi fún ọdún méjì ó lé. Ó jẹ́ ìrírí tó muy divertido (ní ìgbádùn púpọ̀ nínú)!
Mo fẹ́ràn láti máa gbèrú síi nínú ìmọ̀ àti òye nípa ǹkan onírúurú. Kódà, wíwà láìní ìmọ̀ nípa ohun kan a máa bà mí lẹ́rù. Bóyá nítorí ó mú mi wà bí aláìmọ̀kan, àbí bí aláììyẹ, I like àmọ́ ìdàkejì rẹ̀, èyí tí ńṣe ìmọ̀, a máa mú ni ní ìgboyà àti ipá.
Àmọ́ àkókò náà tó láti jẹ́wọ́ ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó fún ọ. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn àmọ̀ọ̀mọ̀jù, mo sì fẹ́ràn láti máa mọ ìdáhùn tí ó tọ́ ní gbogbo ìgbà. Tí àlàyé yìí bá yé o, mo lérò wípé ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì yí ma ṣe ọ́ ní àǹfààní.
Wá gbọ́ o: Kíkọ́ ẹ̀kọ́ dára. Pàápàá jù lọ a nílò láti dàgbà síi nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Àmọ́ àwọn ìṣòro mélòó kan a máa tẹ̀lé ìmọ̀ lẹ́yìn, èyí tí a ma gbé yẹ̀ wò nínú Ìwé Mímọ́ lónìí.
Kódà, mo rọ̀ ọ́ láti ló àkókò díẹ̀ si láti ṣe àṣàrò lórí àyọkà ti òní.
Bí o tí ńṣe èyí, ṣe àgbéyèwò àwọn ìṣòro ńlá méjì tí ó jẹ mọ́ ìmọ̀ yí:
- Ó rọrùn láti gbẹ́kẹ̀lé ìmọ̀ ju Ọlọ́run lọ.
- Ó ṣeé ṣe fún wa láti gbéraga àti láti kó iga rù nípa ìmọ̀ wa.
Ìfẹ́ láti ní ìmọ̀ yìí àti láti ní ìdáhùn tí ó tọ́ á máa mú ìdánwò láti jẹ gàba lórí àwọn tí kò ronú tàbí hùwà bíi tìrẹ. Gbígbé àsíá ìmọ̀ sókè a máa ta ènìyàn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí kò mọ ǹkan tí ìwọ mọ̀.
Ibo wá ni ìfẹ́ tàbí àǹfààní láti jèrè ọkàn nípasẹ̀ ìwàásù gbé dúró pẹ̀lú gbogbo èyí tó wà nílẹ̀ yí? Tí ìbéèrè yẹn bá gún ọ lára, mọ̀ dájú wípé tèmi tìrẹ ni a jọ́ ń kọ́ ẹ̀kọ́ yìí!
Parí parí ẹ̀, ìgbéraga àti ìfẹ́ kò lè kọ́wọ̀ọ́ rìn.
Láti ní ìfẹ́ bíi Jésù—ẹni tí, gẹ́gẹ́bí Ọlọ́run, Ó mọ ohun gbogbo síbẹ̀ Ó jọ̀wọ́ ara ati ipò Rẹ̀ láti sìn, kọ́, àti gba gbogbo àgbáyé—a ma ní láti rìn nínú ìrẹ̀lẹ̀Rẹ̀.
Kí a sì tó lè ṣe èyí, a nílò láti da gbogbo ìgbéraga wa nù.
Níní ìfẹ́ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ bíi Jésù túmọ̀ sí ríri ìmọ̀-kìmọ́ tí a ní sínú ọgbọ́n àti ìrírí Ọlọ́run. Ìgbà náà ni yóò wá rọrùn fún wa láti bá àwọn èèyàn lò, bèrè ìbéèrè, àti mọ rírì wọn pẹ̀lú ìkáàánú ní ipò kípò tí wọ́n lè wà—nínú ayọ̀ tàbí ìrora, àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ tàbí àìmọ̀kan wọn. Ohun tí Jésù ṣe nìyí.
A gbọ́dọ̀ di O.A.O.: Onírẹ̀lẹ̀. Aláájò. Olùgbọ̀wọ́. Nítorí níní ìfẹ́ àwọn ènìyàn ní tòótọ́ nílò rírí wọn àti títẹ́tí dáradára, kìíṣe wí wàásù fún wọn lásán.
Ní ojojúmọ́, àṣàyàn di ọwọ́ wa. A lè ma gbé bíi wípé àwa ni a mọ̀ jùlọ, tàbí a lè ma gbé nínú ìrẹ̀lẹ̀, òtítọ́ olóore ọ̀fẹ́ àti ìfẹ́ tí ń gbani là.
Bí Kọ́ríńtì Kínní 13 ti rán wa létí, díẹ̀ ni ǹkan tí à ń rí, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ló mọ́lẹ̀ sí Ọlọ́run. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jẹ́rìí ọ̀nà ìfẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀.
Gbàdúrà: Fara balẹ̀ láti wá ojú Baba. Bèrè lọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ fún ìṣíjú sí gbogbo ìgbéraga tó farasin. Bẹ̀ Ẹ́ kí ó yín ọ ní èékánná ní nígbàkúùgbà tí ìgbéraga bá jẹyọ. Bèrè fún ìfẹ́ Ọlọ́run láti di ohun tí farahàn jùlọ nínú ìgbésí ayé rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Ohun tí ó ṣe pàtàkí ní pàtó ní fífẹ́ Ọlọ́run àti fífẹ́ ọmọlàkejì, ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe ṣe èyí dé ojú àmì? Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, a kò lè ní ìfẹ́ ẹlòmíràn dunjú nínú agbára ti ara wa. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá gbé ojú s'ókè sí Ọlọ́run tí a rẹ ara wa s'ílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀, a lè gbé ayé láti inú ògidì ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ní agbára. Kọ́ síi nípa dídàgbà nínú ìfẹ́ nínú Ètò-ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọ́jọ́-5 láti ọwọ́ Olùṣọ́-àgùntàn Amy Groeschel.
More