Dídàgbà Nínú Ìfẹ́Àpẹrẹ
Ìfẹ́ Tó Ń Gbilẹ̀ Sí I Ń Tan Ìmọ́lẹ̀
Ní ọlá àyájọ́ àádọ́ta ọdún tí àwọn èèyàn gúnlẹ̀ sí òṣùpá, àjọ Harris Poll (ohun tí wọ́n ń pè ní iléeṣẹ́ tó ń ṣe ìwádìí nípa ọjà) ṣe ìwádìí kan láàárín àwọn ọmọdé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wọ́n béèrè ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Òkìkí YouTube ló wà nípò kìíní.
Àwọn èèyàn ń wá ògo ara wọn ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, a ké sí àwọn Kristẹni láti máa tàn yòò fún ògo Ọlọ́run. Báwo ló ṣe rí gan-an?
Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tá a máa kà lónìí ká lè mọ ohun tó fà á.
... máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí ... nítorí ọlọ́run ni ẹni tí ń ṣiṣẹ́ nínú yín ... Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti àríyànjiyàn, kí ẹ lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti aláìní ẹ̀bi ... Nígbà náà ni ìwọ yóò tàn... Fílípì 2:12-15 NIV
...ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún baba yín ... Mátíù 5:16 NIV
Ṣugbọn ẹ jẹ́ olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ẹ̀yin tí ń tan ara yín jẹ. Ṣe ohun tó sọ. James 1:22 NIV
... Ohun kan ṣoṣo tó ṣe pàtàkì ni pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tó ń fara hàn nípasẹ̀ ìfẹ́. Gálátíà 5:6 NIV
Àwọn àyọkà wọ̀nyí fi hàn pé ìmọ́lẹ̀ Kristẹni jẹ́ ọ̀nà láti dàgbà nínú ìfẹ́ nípa ìgbàgbọ́ àti ìfọ̀rọ̀sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ẹmí Mímọ́.
Báwo wá ni Kristẹni kan tó ń tàn yòò ṣe máa ń rí? Ṣé ẹni tó máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́ nígbà gbogbo, tí kì í sì í ṣàníyàn? Ṣé ẹnì kan tó jẹ́ èèyàn dáadáa ni àbí ẹni tó máa ń lawọ́ gan-an?
Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó sì lè máà jẹ́ bẹ́ẹ̀. Rántí ọjọ́ kẹta, ọkàn wa bákan náà, ìṣe wa bákan náà àti ìdí tá a fi ṣe é ṣe pàtàkì.
Fún ìṣẹ́jú kan, ronú lórí ọ̀rọ̀ tí ò ṣeé já ní koro yìí látinú ìwé kan tó gbajúmọ̀ Ọ̀dọ́mọkùnrin Náà, Ẹlẹdẹ Náà, Ẹranko Náà àti Ẹṣin Náà:
"Ṣé kì í ṣe ohun tó ṣàjèjì? Ojú òde nìkan la fi ń wo ara wa, àmọ́ inú lọ́hùn-ún la ti máa ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀."
Ìfẹ́ tó ń tàn yòò kì í wo ibi tí nǹkan wà. Kì í fi ara rẹ̀ wé àwọn ẹlòmíràn mọ́, kì í dáni lẹ́jọ́, kì í ṣàríwísí, kì í sì í ṣe ẹ̀tanú, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń wojú Ọlọ́run.
À ń fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nígbà tá a bá mọ̀ pé òkùnkùn tẹ̀mí là ń bá jà, tá a sì ń fi tìfẹ́tìfẹ́ bá àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi yòókù jagun fún ìṣọ̀kan. A máa ń tàn yòò nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀, tá a sì ń gbé ìgbésẹ̀ nítorí àìṣẹ̀tọ́, tá à ń fi ìwà ọ̀làwọ́ àti ìmọrírì gbé ìgbé ayé wa, tá à ń ṣe gbogbo ohun rere tá a bá lè ṣe, tá a sì ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa.
Àṣà ayé ń gbìyànjú láti tàn wá ká lè máa wá ìgbádùn, ìmọ̀ ọgbọ́n orí, òkìkí, àti ète tara wa láìsí Ọlọ́run. Ó bani nínú jẹ́ pé ẹ̀kọ́ èké ló ń mú kí àwọn èèyàn máa ronú pé àwọn ò lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Wọ́n ti kùnà láti gbé Ọlọ́run ga, tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ gbé e ga.
Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, àwọn tó ń fi ògo fún Ọlọ́run jù lọ mọ̀ pé Ọlọ́run ló fún wọn ní irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àti ìjẹ́pàtàkì wọn.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi, kí ìfẹ́ Kristi lè máa tàn kálẹ̀ nígbà gbogbo, a gbọ́dọ̀ rántí pé a ní ààbò pátápátá àti pé a ṣe pàtàkì ní àìlópin nípa Kristi. Òun ni ìwàláàyè wa, òun ni ààbò wa, òun sì ni olórí ohun tá a ní.
Nígbà tí ẹ̀mí rẹ̀ bá sì ń gbé wa, tí ọkàn wa sì balẹ̀ nínú ẹni tí a jẹ́ nínú rẹ̀, ìfẹ́ yóò máa tàn yòò láti inú wa, Ọlọ́run yóò sì gba gbogbo ògo.
Ẹ bá mi gbé Olúwa ga, ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga! Orin Dáfídì 34:3 RSV
Gbàdúrà:Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti ìmọ́lẹ̀ tí ó lẹ́wà àti àgbàyanu, mo rẹ ara mi sílẹ̀ níwájú Rẹ. Ìwọ nìkan ni èmi yóò máa yìn. Mo kọ irọ́ àìdánilójú. Ìwọ ni ìjẹ́pàtàkì mi, inú rẹ sì ni mo wà ní ààbò. Ràn mí lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ mi lè máa dàgbà nínú ìfẹ́ rẹ tó mọ́, tó ń múni yááfì nǹkan, tó sì ń tàn yòò. Ní orúkọ Jésù, ámín.
Nípa Ìpèsè yìí
Ohun tí ó ṣe pàtàkí ní pàtó ní fífẹ́ Ọlọ́run àti fífẹ́ ọmọlàkejì, ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe ṣe èyí dé ojú àmì? Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, a kò lè ní ìfẹ́ ẹlòmíràn dunjú nínú agbára ti ara wa. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá gbé ojú s'ókè sí Ọlọ́run tí a rẹ ara wa s'ílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀, a lè gbé ayé láti inú ògidì ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ní agbára. Kọ́ síi nípa dídàgbà nínú ìfẹ́ nínú Ètò-ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọ́jọ́-5 láti ọwọ́ Olùṣọ́-àgùntàn Amy Groeschel.
More