Dídàgbà Nínú Ìfẹ́Àpẹrẹ

Growing in Love

Ọjọ́ 3 nínú 5

Ìfẹ́ Tí Ó ń Gbèrú Nílò Àtúntò Ọkàn

Láti ní ìfẹ́ bó ti yẹ, a nílò ìrunú-sókè tó mú òtítọ́ àti àyà funfun lọ́wọ́. Fún ìdí yìí, ìfẹ́ tó ń gbèrú nílò ìdáraẹnimọ̀ tó múná dóko.  

Ǹjẹ́ ìfẹ́ tìrẹ ní òtítọ́ nínú—ṣé kò ní àgàbàgebè tàbí ibọ́n nínú? Báwo ni o ṣe lè mọ̀? Wá àkókò fún àtúntò ọkàn rẹ. Ẹ gbà mí láyè láti ṣàlàyé. 

 Ní ìgbà dé ìgbà ni mo máa ń lọ sí ọ̀dọ̀ dókítà egungun fún àtúntò ọ̀pá éyìn mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Dókítà Lisa ma ṣe àwárí ohun kàn tó ti kúrò ní ipò rẹ̀—fún ìdí yí ó máa wọ́ ọ, raá, tẹ̀ẹ́ tí gbogbo rẹ̀ ma fi bọ̀ sípò. Àtúntò tí mo ṣe àpèjúwe rẹ̀ yí a máa mú àlàáfíà bá ara mi ní onírúurú ọ̀nà. 

Ní ọjọ́ kínní Ètò Bíbélì kíkà yí, a kọ́ wípé ní gbogbo ọ̀nà ni a ti nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nípa níní ìfẹ́ Rẹ̀ àti àwọn tó yí wa ká. Àti wípé ọ̀kan lára àwọn àǹfààní dídúró de, àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú, Ọlọ́run lójojúmọ́ ni wípé ó máa ń sábà ṣe àfihàn ohun kan pàtó tí ó nílò àtúnṣe—tàbí àtúntò ọkàn. 

Nígbà míràn, Ọlọ́run a fi hàn mí wípé ìmọ̀lára tó ní ẹ̀rù nínú ni mo fi ń tọ́ àwọn ọmọ mi dípò ìfẹ́ òtítọ́, àti wípé mo nílò láti jọ̀wọ́ ohun gbogbo sí ọwọ́ Rẹ̀. Nígbà míràn, mo lè bínú, tí Ẹ̀mí Mímọ́ sì ma ṣe àfihàn ìgbéraga tí mo ní láti ronúpìwàdà kúrò nínú rẹ̀ àti àwọn ìdáríjì tí mo ní láti ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, ni mo gbẹ́kẹ̀lé ara mi tí mo sì fi agídí gbìyànjú láti wá ọ̀nà àbáyọ ti ara mi kúrò nínú ìṣòro kàn pẹ̀lú ìpinnu láti ṣe ìrànwọ́ pẹ̀lú ìfẹ́. 

Mo lè tẹ̀síwájú pẹ̀lú onírúurú àpẹẹrẹ, àmọ́ ohun tí mò ń retí fún ọ láti ní òye rẹ̀ ni wípé a kò lè fẹ́ràn àwọn tó yí wa ká láìṣe pé a jọ̀wọ́ ara wa fún ìbáwí kí a sì tẹ́ ara wa sílẹ̀ lórí tábìlì ìyẹ̀wò ní iwájú Oníṣègùn Mímọ́ nì. 

Èmi kò lè fẹ́ràn pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ìbínú, ìmọ-tara-ẹni-nìkan, tàbí orí kunkun. Èyí sì ṣẹ́ ìwo mọ́ ìwọ náà lára. Mọ èyí dájú.

Ìṣòro ibẹ̀ ni wípé púpọ̀ nínú ǹkan tí èmi àti ìwọ máa ńṣe lè ní ìfarajọ̀ ìwà òdodo. Ohun tí ó rọrùn fún wa ní láti máa rán ǹkan tí ara wa, ní òdodo ara wa, àti láti dá ara wa lare. Àmọ́ ìfẹ́ jinlẹ̀ jú ohun tí a lè fojú rí lọ. 

Ohun tí ó dára kì í sábà jẹ́ èyí tí ó mú ìfẹ́ lọ́wọ́. Nípa ti ìfẹ́ òtítọ́, èrò inú wa ló ṣe pàtàkì jù lọ. 

Ìdí nìyí tí a fi gbọ́dọ̀ tọ Ọlọ́run lọ pẹ̀lú ọkàn tó rọ̀, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ èyí tó máa lé gbogbo ìtan-ra-ẹni-jẹ jìnà sí sàkání wa. Bí ìgbà tí a bá lọ sí ọ̀dọ̀ dókítà egunegun, lílo àkókò tí ó ní ìtumọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run níbi àdúrà a máa mú ìdáraẹnimọ̀ tí ọkàn wa nílò jẹyọ.

Nítorí náà lónìí, wá àkókò láti bèrè lọ́wọ́ ara rẹ: Kíni ǹkan tí mò ń ṣe tó fara jọ ohun tí ó tọ́, àmọ́ tí èrò tó bíi kò dára? 

Gbàdúrà: Bèrè pé kí Ọlọ́run ṣe àfihàn àwọn èrò tí kò tọ́, tí o ní láti jọ̀wọ́ rẹ̀ kí o ba lè ní ìfẹ́ pẹ̀lú inú kan. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Growing in Love

Ohun tí ó ṣe pàtàkí ní pàtó ní fífẹ́ Ọlọ́run àti fífẹ́ ọmọlàkejì, ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe ṣe èyí dé ojú àmì? Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, a kò lè ní ìfẹ́ ẹlòmíràn dunjú nínú agbára ti ara wa. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá gbé ojú s'ókè sí Ọlọ́run tí a rẹ ara wa s'ílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀, a lè gbé ayé láti inú ògidì ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ní agbára. Kọ́ síi nípa dídàgbà nínú ìfẹ́ nínú Ètò-ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọ́jọ́-5 láti ọwọ́ Olùṣọ́-àgùntàn Amy Groeschel.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/