Dídàgbà Nínú Ìfẹ́Àpẹrẹ

Growing in Love

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ìfẹ́ Tí Ń Dàgbà Sinmi Lé Ọlọ́run

Ó rọrùn fún ayé wa láti kún fún onírúurú ìgbòkègbodò kí á sì pàdánù àwọn ohun tí ó ṣe kókó gan-an. Ṣúgbọ́n ní àkókò yìí, Ọlọ́run ń fi bí ìbáṣepọ̀ àti dídàgbà nínú ìfẹ́ ṣe ṣe pàtàkì tó hàn mí.. Ní bíi àwọn ọjọ́ mélòó kan, a ó ṣe àgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè dàgbà nínú ìfẹ́ wa sí Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn kí á baà lè ní ìrírí ìfẹ́ àti ìpè Ọlọ́run tí ó ga jù fún wa—kí á ní ìrírí, kí á sì gbé nínú ìfẹ́ Rẹ̀.

Kódà Ìwé-mímọ́ sọ fún wa nínú Mátíù 22:37-40 pé fífẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ohun gbogbo tí a jẹ́ àti fífẹ́ ọmọlàkejì bí ara wa mú gbogbo òfin àti àwọn wòlíì ṣẹ.

O tilẹ̀ ti le mọ èyí tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ó rọrùn láti sọ ọ́ ju àti ṣe é lọ, àbí?

Kàkà kí n wá ẹgbẹ̀rún àwáwí fún ìdí tí èyí kò fi lè ṣeéṣe, mo yàn láti dàgbà nínú àwọn ìpè tí ó ṣe pàtàkì jù yìí. Mo sì ní èrò pé ìwọ náà fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.

Nítorínáà, how ǹjẹ́ a lè ní ìfẹ́ bíi irú èyí nítòótọ́? A kò lè ṣe èyí—fúnraara wa.

A ní láti wó ọ̀dọ́ Ọlọ́run—orísun ìfẹ́! Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run nìkan kọ́ ni orísun ìfẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ni Ọlọ́run (wo 1 Jòhánù 4:16). Gẹ́gẹ́ bíi Krìstìẹ́nì, a lè ní ìfẹ́ tòótọ́ nítorí a ní ìrírí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ Rẹ̀ sí wa (wo Fílípì 2:1-2).

Bí ó tilẹ́ jẹ́ pé a kò lè ní ìfẹ́ pípé ní ayé yìí, a lè dàgbà nínú agbára wà láti ní ìfẹ́. Àti pé gbígbé láti inú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣeéṣe nígbàtí a bá kọ́ láti mọ̀ Ọ́ àti láti gbé ara lé E ní àkókò kọ̀ọ̀kan.

Rántí bí ayé rẹ ti rí kí o tóo ní ìrírí oore-ọ̀fẹ́ àti ìdáríjì Ọlọ́run? D'ásẹ̀ dúró kí o sì dárúkọ àwọn ìbùkùn àtinúwá mẹ́ta tí ò ń gbádùn báyìí gẹ́gẹ́ bíi Krìstìẹ́nì.

Nígbàtí a bá ní òye, tí a fí ara mọ́, tí a sì ní ayọ̀ nínú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, ìfẹ́ òtítọ́ á jẹ jáde!

Ẹ jẹ́ kí á wo àpéẹrẹ Jésù Olúwa wa:

Jésù sọ fún àwọn tí ó kẹ́gàn tí wọ́n sì ṣiyèméjì nípa Rẹ̀ pé ohun gbogbo tí Òun ṣe tí Òun sì sọ wá láti ìpa ìtọ́sọ́nà ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run. Látàrí èyí, ohun tí àwọn ènìyàn rí nínú ayé Rẹ̀ ni ìfẹ́ tí ó ń yí ìwàláàyè padà, tí ó sì ń fi ìyọ́nú hàn pátápátá.

Bí a ó bá dàgbà nínú ìfẹ́, kò níí wá látàri pé à ń tiraka síi tábí gbẹ́kẹ̀lé ara wa. A ní láti kọ́ àpẹẹrẹ Jésù kí a sì lépa ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run nípa àdúrà.

A ó nìí láti ní òye Bíbélì kí a tó lè ní òye àti rìn nínú ìfẹ́, a sì ní láti kọ́ láti wò, kí a sì gbé ara lé ìyè Rẹ̀ nínú wa. Nígbàtí a bá ṣe èyí, ìfẹ́ yíó jẹ́ ìtújáde ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìṣoore Rẹ̀ nínú ayé wa.

Gbàdúrà: Lo àsìkò díẹ̀ láti bá Ọlọ́run ṣọ̀rọ̀. Jẹ́wọ́ ìpòǹgbẹ rẹ láti gbé ara lé E síi. Sọ fún Ọlọ́run irú ayọ̀ ńlá tí ó jẹ́ láti jẹ́ ọmọ Rẹ̀, kí o sì bèèrè àwọn ọ̀nà pàtó láti gbé pẹ̀lú Ẹ̀mímímọ́ Rẹ̀ nínú ayé rẹ.

Kọ́ síi nípa Àwọ̀n Arábìrin Life.Church kí o sì wo ọ̀rọ̀-àfiránṣẹ́ Olùsọ́-àgùntàn Amy, Ní Ìfẹ́ Bíi Jésù.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Growing in Love

Ohun tí ó ṣe pàtàkí ní pàtó ní fífẹ́ Ọlọ́run àti fífẹ́ ọmọlàkejì, ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe ṣe èyí dé ojú àmì? Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, a kò lè ní ìfẹ́ ẹlòmíràn dunjú nínú agbára ti ara wa. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá gbé ojú s'ókè sí Ọlọ́run tí a rẹ ara wa s'ílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀, a lè gbé ayé láti inú ògidì ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ní agbára. Kọ́ síi nípa dídàgbà nínú ìfẹ́ nínú Ètò-ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọ́jọ́-5 láti ọwọ́ Olùṣọ́-àgùntàn Amy Groeschel.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/