Àgbàrá Ìyìn Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀: Ètò Ìfọkànsín Olóòjọ́ Márùn-ún Láti Inú Ìwé Orin DáfídìÀpẹrẹ
Yíyin Ọlọ́run Nmú Ìṣẹ́gun Wá
Aní ọ̀tá kan tí ó ún fẹ́ láti jà wá lólè, pa, àti parun. Ó ún ṣiṣẹ́ kára kára láti jà wá lólè ìgboyà wa àti ìfẹ́ ọkàn wa. Ó jẹ́ òpùró àti olùfisùn. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sátánì. Síbẹ̀, Ọlọ́run ti fún wa ní àwọn ohun ìjà tí a lè fi kọjú ìjà sí Sátánì tí ó ún ha ilẹ́ mọ́ wa. A lè wó orí ọ̀tá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti Ìyìn. Àwọn oun ìjà méjèèjì yìí, tí a bá pa wọ́n pọ̀ won yóò rún Sátánì búrú lábé ẹsẹ̀. Oun kan dájú, Sátánì kò le dúró lẹ́bàá ìyìn wa. Nígbàtí ó bá dàbí pé ó ún ṣẹ́gun rẹ tàbí ó tilè ti kó ọ láyà je, bẹ̀rẹ̀ sí ní yìn ní orúkọ Jésù Kríístì. Bí o ti ṣe ń gbé Jésù Kíístì ga nítorí Ẹni tí Ó jẹ́, Sátánì yóò fi eré ge bíi ojo.
Irú ìlànà-àmúlò yí ni a rí nínú ìtàn Jèhóṣáfátì bí ó ti ṣáájú àwọn ọmọ ogun Júdà jáde láti kọjú àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn ká. Dípò kí ó kọ́kọ́ rán àwọn ọmọ ogun jáde, Oba Jèhóṣáfátì rán àwọn akọrin tí wọ́n ń kọrin, “Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí àánú Rẹ dúró láíláí” (2 Kíróníkà 20:21). Bí àwọn akọrin ṣe ń kọrin, Ọlọ́run gba ẹ̀bùrú yọ sí àwọn ọ̀tá O sì ṣẹ́gun wọn. Ìtàn tí ó lágbára nìyí tí ó ún ṣe àfiwé bí yí yín Ọlọ́run ṣe ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ayé wa.
Selah – Sinmi kí ó sì ṣe àṣàrò Ní agbọndan wo ni o ti ń pò ńgbẹ láti rí ìṣẹ́gun ní ayé rẹ? (i.e. ìṣẹ́gun lóríi ìfòyà, ẹ̀rù, ìkúndùn, àti àwọn nǹkan tó nííṣe pẹ̀lú oúnjẹ..) Kíni ó jọ sí ọ láti yin Ọlọ́run pé, a ti jà gba ìṣẹ́gun nípasẹ̀ Jésù Kríístì?
Àdúrà Ìyìn: Jésù Olúwa, mo gbéỌga, nítorí pé pẹ̀lú agbára Rẹ mo lè la ohunkóhun kọjá tó dàbí ẹni pé kò ṣeé borí. Nípa agbára Rẹ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀. Ẹ ṣeun, nítorí nígbàtí ẹ̀rù ń bà mí O wà pẹ̀lú mi. Mo yìn Ọ́ nítorí pé O ṣèlérí pé Oó tọ́ mi lo sí ìṣẹ́gun, bí mo ti ún gbẹ́kẹ̀ lé Ọ. Bàbá Olúwa, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ pé nípasẹ̀ Kristì mo ní ìṣẹ́gun nínú ohunkóhun. Kòsí ohun ìjà tí a kọ sí mi tí yóò ṣe rere. Mo yìn Ọ́, Jésù Olúwa, pé lónìí mo lè dúró nínú ìṣẹ́gun Rẹ.
Orin-Dáfídì 18:46-49, “Olúwa wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi! Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi. Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi, tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi, tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí. Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ; lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí. Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa; Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.”
Fún ìrànlọ́wọ́ síi láti borí ìfòyà, darapọ̀ Becky Harling fún ètò ẹ̀kọ́ lóríi Orin-Dáfídì fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà lóríi ayélujára Agbára Tó Tayọ Tó Wà Nínú Ìyìn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àníyàn, ìfọ̀yà, ìdánìkanwà àti ìsoríkó tí dìde gidi gàn láàárín ọdún mélòó kan tó kọjá. Àwọn èrò ìmólárá wonyìí kìí ṣe tuntun si àwọn Onísáàmù. Àmó, wón kó láti tú àgbàrá ìyìn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jáde láti bórí. Ṣàwárí àṣírí láti fọkàn rẹ̀ balẹ̀ nínú àwọn ìfọkànsin yìí láti ìwé Orin Dáfídì.
More