Àgbàrá Ìyìn Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀: Ètò Ìfọkànsín Olóòjọ́ Márùn-ún Láti Inú Ìwé Orin DáfídìÀpẹrẹ

The Extraordinary Power of Praise: A 5 Day Devotional From the Psalms

Ọjọ́ 3 nínú 5

Yínyin Ọlọ́run Yíò Fún Ọ Ní Ààfàní Láti Ṣe Àtúpalẹ̀ Ìpòrúúru Ọkàn Rẹ

Ìgbà kan wà tó dàbí pé ayé mi ṣ'ókùnkùn. Àrùn jẹjẹrẹ pin mi l'ẹ́mìí tán põ. Mo wòye nígbà náà pé, “Ṣe ènìyàn lè yín Ọlọ́run tọkàntọkàn nígbàtí ara ní mí tó yìí?” Àní, ara mi kò gba kí n máa fò sókè sódò pariwo, “Hallelujah, mo ní àrùn jẹjẹrẹ o!” Bí mo ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú ìwé Sáàmù, mo rí mọ̀ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ìwé Sáàmù jẹ́ ìdárò. Àdúrà ìdárò jẹ́ àdúrà tí ó kún fún ìbéèrè, ìpòrúurù ọkàn àti iyèméjì. Ohun tí mo ṣ'àkíyèsí nípa àwọn Onísáàmù nipé wọn kò f'arapamọ́ fún Ọlọ́run. Nígbàtí ó bá t'ojú sú wọn, wọn á tú ọkàn wọn palẹ̀. L'ọ́pọ̀ ìgbà, ìjọsìn wọn ni ẹkún tí wọn ńsun (Orin Dáfídì 42:3). Nígbà míràn wọn a tú àròyé palẹ́ fún Olúwa. Fún àpẹẹrẹ, ní àsìkò kan nínú ayé rẹ̀, nkán polúkúrúmusu fún Dáfídì tó bẹ̀ẹ̀ tó gbàdúrà nínún Orin Dáfídì 58:6, pé “Fọ́ eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run!” Mo rántí pé nígbàtí mo kọ́ ka ọ̀rọ̀ yìí, ohun tí ó kọ́ wá sí mi l'ọ́kàn ni pé, “Ǹjẹ́ a gbà wá láyè láti gba irú àdúrà báyìí?”

Ọlọ́run fẹ́ ìjọsìn àtinúwá rẹ. Tí ọkàn rẹ bá pòrúurù, tí ò ń bínú tàbí ò ń banújẹ́, Ó ń pè ọ́ láti kó gbogbo rẹ̀wá sọ́dọ̀ Òun. K'érora lórí gbogbo rẹ̀ níwájú Rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, tèlé àpẹẹrẹ Onísáàmù. Dojúkọ ìyìn. Ọlọ́run ṣ'èlérí láti wà l'étí lọ́dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn àti láti gba irú àwọn tíi ṣe onírora ọkàn là (Orin Dáfídì 34:18). Yín ín kí o sì jọ́sìn fún Un lónìí Ẹni tíí pa àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́.

Selah – Ronú kí o ṣ'àṣàrò: Ṣé o l'érò pé láti jẹ́ "Krìstìẹ́nì tòótọ" o ní láti máa l'áyọ̀ ní gbogbo ìgbà? Ìgbà wo ni Ọlọ́run tí bá ọ pàdé rí nínú ọ̀gbun ìròbìnújẹ́ ọkàn rẹ?

Àdúrà Ìyìn: Jésù Olúwa, mo yìn Ọ́ pé O jẹ́ Ẹni tí a bà nínú jẹ́ púpọ, O sì mọ bí ìròbìnújẹ́ ṣe rí nígbàtí O wà nínú ayé yìí (Àìsáyà 53:3). O seun nítorí O rí gbogbo omijé ojú mi O sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ ìbínú tí mo sọ. Mo yìn Ọ́ pé O pè mí láti fi òtítọ inú bá Ọ lò nípa àwọn ohun tí mò ń là kọjá. Mo dúpẹ́ pé bí mo ti ń tú ìbànújẹ ọkàn mi jáde nínú ìjọsìn níwájú Rẹ, Ìwọ yíó wo ọgbẹ́ ọkàn mi sàn. Mo yìn Ọ́ Olúwa nítorípé Ò ń tù mí nínú gẹ́gẹ́ bíi Bàbá Onífẹ̀ jùlọ tí O je. O ṣeun nítorí O wà nítòsí nígbàtí mo bá ké. Mo júbà Rẹ Baba Oníyọ́nú jùlọ!

Orin Dáfídì 34:18, "Olúwa ńbẹ létí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn, Ó sì gba irú àwọn tíi ṣe onírora ọkàn là."

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

The Extraordinary Power of Praise: A 5 Day Devotional From the Psalms

Àníyàn, ìfọ̀yà, ìdánìkanwà àti ìsoríkó tí dìde gidi gàn láàárín ọdún mélòó kan tó kọjá. Àwọn èrò ìmólárá wonyìí kìí ṣe tuntun si àwọn Onísáàmù. Àmó, wón kó láti tú àgbàrá ìyìn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jáde láti bórí. Ṣàwárí àṣírí láti fọkàn rẹ̀ balẹ̀ nínú àwọn ìfọkànsin yìí láti ìwé Orin Dáfídì.

More

A fé dúpẹ lówó ilé ìṣẹ́ Moody Publishers fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.moodypublishers.com/the-extraordinary-power-of-praise/