Àgbàrá Ìyìn Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀: Ètò Ìfọkànsín Olóòjọ́ Márùn-ún Láti Inú Ìwé Orin DáfídìÀpẹrẹ

The Extraordinary Power of Praise: A 5 Day Devotional From the Psalms

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ìyìn Sí Ọlọ́run A Máa Pa Ẹ̀rù Wa Lẹ́nu Mọ́

Ọdún 2020 dàbí èyí tó ṣókùnkùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Àrùn COVID-19 sọ ara rẹ̀ di àjàkáyé. Ogunlọ́gọ̀ ló pàdánù ènìyàn, iṣẹ́ àti ilé-ìgbé wọn. Ìgbésí ayé wá ṣókùnkùn bí a ti ń gbọ́ ìròyìn nípa ìrẹ́nijẹ ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ìwọ́de, ìdàrúdàpọ̀ l'ágbo òṣèlú àti ìpànìyàn l'ójúmọmọ. Ìbẹ̀rùbojo òhun àníyàn wá wọ́pọ̀ lóde. felt like a dark year for many.

Dáfídì olórin náà ní ìrírí irú àkókò tó ṣókùnkùn bí èyí. Ọ̀tá tirẹ̀ kìíṣe àjàkálẹ̀ àrùn bíkòṣe Ọba kan tó wà lórí àpèlè tó ń jowú tó sì gbìyànjú láti pa Dáfídì ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Nígbà tí ẹ̀rù mu Dáfídì lómi, ó gbé gbogbo àníyàn rẹ̀ tọ Ọlọ́run lọ, lẹ́yìn èyí ló wá fi ìyìn sí Ọlọ́run ṣe àfojúsùn rẹ̀. Irú ìhà yí ni Dáfídì kọ sí Ọlọ́run jálẹ̀ ayé rẹ̀.

Nínú ayé tìrẹ àti èmi, ó rọrùn fún ẹ̀rù láti yọjú nígbàtí òkùnkùn bá bolẹ̀. Kàkà kí a tàdí-sẹ́yìn fún ẹ̀rù, Ọlọ́run ń pè wá láti jọ̀wọ́ gbogbo àníyàn ọkàn wa síwájú Rẹ̀ àti láti fi ìyìn ṣe àfojúsùn wa. Bí a ti ń yin Ọlọ́run fún ìwàláàyè Rẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ a máa pa ẹ̀rù wa lẹ́nu mọ́ yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa láti lè ní òye nípa ìwàláàyè Ọlọ́run síwájú síi. Yíyin Ọlọ́run a máa tún ìgbàgbọ́ wa ṣe èyí tí yóò mú iyèméjì kúrò, yóò mú ìgboyà tó borí ẹ̀rù wá, pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ tó borí àníyàn. Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, o kò lè yin Ọlọ́run láì rí àyípadà sí rere.

Ìdánudúró - T'ẹsẹ̀ dúró láti gba èyí rò: L'ọ́pọ̀ ìgbà jálẹ̀ Orin Dáfídì ni a ti rí ọ̀rọ̀ yí “Ìdánudúró” èyí tó túmọ̀ sí mímú sùúrù láti ṣe àṣàrò. Lo ìṣẹ́jú mélòó kan láti ro àròjinlẹ̀. Nígbà tí òkùnkùn bá ṣú nínú ìgbésí ayé rẹ, ọ̀nà wo ni o máa ń gbà làájá?

Àdúrà Ìyìn: Jésù Olúwa, mo yìn Ọ́ nítorí O jẹ́ ìmọ́lẹ̀ àti ìgbàlà mi. Mo yìn Ọ́ nítorí nígbàkúùgbà tí mo bá páyà, Ìwọ ma pè mí láti kó gbogbo ẹ̀rù mi sí ẹsẹ̀ rẹ. O ṣeun nítorí wípé òkùnkùn tí mò ń là kọjá kò leè borí ìmọ́lẹ̀ àti ògo ìwàláàyè Rẹ. Mo túbá fún Ọ gẹ́gẹ́bí Ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn nínú òkùnkùn. Mo yìn Ọ́, wípé O tún jẹ́ ibi ìsádi àti àbò mi tí mo lè sá tọ̀ nígbà gbogbo. Kódà lákòókò yí, tí ẹ̀rù ń rìn lóòjọ́, ìwàláàyè Rẹ rọ̀gbà yí mi ká. Mo yìn Ọ́ fún ìdánilójú àti ìgboyà tó ń ru jáde nínú mi bí mo ti ń sìn Ọ́ pẹ̀lú òtítọ́. Olúwa Ọlọ́run mi, Ìwọ ni gbogbo ìyìn mi yẹ fún.

Orin Dáfídì 27:1, “OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi – tali emi o bẹ̀ru? Oluwa li agbara ẹmi mi – aiya tali yio fò mi?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

The Extraordinary Power of Praise: A 5 Day Devotional From the Psalms

Àníyàn, ìfọ̀yà, ìdánìkanwà àti ìsoríkó tí dìde gidi gàn láàárín ọdún mélòó kan tó kọjá. Àwọn èrò ìmólárá wonyìí kìí ṣe tuntun si àwọn Onísáàmù. Àmó, wón kó láti tú àgbàrá ìyìn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jáde láti bórí. Ṣàwárí àṣírí láti fọkàn rẹ̀ balẹ̀ nínú àwọn ìfọkànsin yìí láti ìwé Orin Dáfídì.

More

A fé dúpẹ lówó ilé ìṣẹ́ Moody Publishers fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.moodypublishers.com/the-extraordinary-power-of-praise/