Títẹ̀lé Jésù Olùgbèjà WaÀpẹrẹ

Jésù Onílàjà Wa
Ní gbogbo ọ̀sẹ̀ yìí, a rí Jésù tí Ó ń kàn sí àwọn òtòṣì, àwọn tí a tẹ̀ lórí ba, àwọn ojo, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àti gbogbo àwọn tí a d'ẹ́yẹ sí ní àwùjọ. Nínú iṣẹ́ ìlàjà tí ó ga jùlọ, ìyẹn ikú àti àjíǹde Rẹ̀, Ó rú gbogbo ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a baà lè mú wa padà bọ̀ s'ípò pẹ̀lú Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kanṣoṣo àti pátápátá.
Láti inú ìwé Ẹ̀kọ́ Bíbélì Áfíríkà kan tí àkólé rẹ̀ ńjẹ́ “Jésú, Onílàjà Ẹ̀dá”:
Ìlàjà jẹ́ ohun tí ó sopọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ àṣà Áfíríkà bí ohun-èlò ìpẹ̀tù-s'ááwọ̀. Ní t'àṣà-t'ìṣe, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbéyàwó ní ilẹ̀ Áfíríkà ní wọ́n maá ńṣètò pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn aṣojú-òbí. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tọkọ-tìyàwó yíó lọ ké bá bí wọ́n bá kojú ìṣòro tó níílò ìpẹ̀tùsí. Bí àwùjọ bá kojú aáwọ̀ lóde òní, àwọn àgbààgbà láti igun méjéèjí yíó pàdé lọ́dọ̀ alàgàta láti dúnàá-dúraà lórí bí àlááfìa yíó ṣe wáyé. Bí àwọn orílẹ̀-èdè bá ń bá ara wọn ja'gun, Àjọ Ìsọkan Àgbáyé yíó rán àwọn oníṣẹ́-àlááfíà láti gbìyànjú àti f'òpin sí ìgbóguntì náà. Àwọn aṣojú-òbí, alàgàta, àti oníṣẹ́-àlááfíà ń ṣiṣẹ́ bíi onílàjà. Wọ́n ń l'àjà láàrin igun kìńní-kejì tí wọ́n ńjà láti dá àlááfíà àti ìṣọ̀kan padà.
Krístì wá gẹ́gẹ́bí onílàjà—onílàjà tó péye. Kò ní ẹ̀ṣẹ̀, kò sì jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa dá. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́bí onílàjà láàrin alágbára àti aláìlàgbára, Ó gba ipò wa.
Krístì san ìdíyelé tí ó ga júlọ, Ó sì ṣ'èlérí pé enikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Òun kò ní gba ìjìyà yẹn mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá gbàá gbọ́ gba ìyè àìnípẹ̀kun. Nípasẹ̀ Jésù, àti nípasẹ̀ Rẹ̀ nìkan ni ènìyàn fi le wà ní àlááfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. “Nítorí Ọlọ́run kan ní ḿbẹ, Onílàjà kan pẹ̀lú láàrin Ọlọ́run àti ènìyàn—Òun pàapàá ènìyàn, àní Krístì Jésù. Ẹnití Ó fi ara Rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn.” (1 Timothy 2:5-6).
Ronú tàbí Jíròrò
Kíni ìdí rẹ̀ tí a fi níílò Jésù láti jẹ́ onílàjà wa?
Jésù ṣiṣẹ́ bíi onílàjà tó péye, Ó gba gbogbo ìjìyà tó tọ́ sí wà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kíni o rò pé ó jẹ́ ìdí tí Jésù fi ṣe èyí fún wa?
Ṣé o wà l'álààfíà pẹ̀lú Ọlọrun? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kíni ọ̀nà kanṣoṣo tí ó lè gbà láti bá A làjà?
Bí o kò bá í tíì fi ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ rẹ sínú Jésù, onílàjà ẹ̀dá, má jẹ̀ kí ọjọ́ míràn kọjá láì wá ẹnìkan tí yíó gbàdúrà pẹ̀lú rẹ nípa èyí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Oníbárà tó f'ọ́jú kan tó ń kígbe rara ní ẹ̀bá ọ̀nà, obìnrin kan tí ìgbé-ayé rẹ̀ kò tọ̀nà ní ojú mùtúmùwà tó mọ̀ọ́ṣe, òṣìṣẹ́ ìjọba kan tí gbogbo ènìyàn kórìíra – báwo ni ìkankan nínú àwọn ènìyàn yìí tí àwùjọ ti ta dànù ṣe lè ní ìrètí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run mímọ́? Pẹ̀lú àwọn ìlanilọ́yẹ̀ látinú ìwé Lúùkù nínú Bíbélì Àṣàrò fún Afrika, a ó máa tẹ̀lé Jésù bí ó ti ńṣe ìparẹ́ àwọn àlà tó wà láàárín Ọlọ́run àti àwọn tí a ti gbá sí ẹ̀gbẹ́ láwùjọ.
More