Títẹ̀lé Jésù Olùgbèjà WaÀpẹrẹ

Jésù àti Àwọn Tó Bẹ̀rù
Kò sí ìbẹ̀rù kankan tó lágbára débi pé Jésù kò lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí rẹ̀. Kò sí òkùnkùn tó jìn débi tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò fi lè wọnú rẹ̀.
Láti inú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti Áfíríkà, a rí àlàyé kan tó ní àkọlé náà “Ìmọ́lẹ̀ Ìyè“:
Ní ọ̀pọ̀ ibi, bí òru bá ti ń ṣú, ẹ̀rù máa ń bà wọ́n pé ewu ń bọ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìwà ibi àti ìwà ọ̀daràn ni wọ́n máa ń hù lábẹ́ òkùnkùn. Àwọn iṣẹ́ àjẹ́ àti iṣẹ́ òkùnkùn, olè jíjà àti ìpànìyàn, ìṣekúṣe àti ìmutípara sábà máa ń wáyé nínú òkùnkùn. Àwọn apààyàn, àwọn tó ń rìn kiri lálẹ́, àtàwọn tó ń lọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́mìílò máa ń fara pa mọ́ lábẹ́ òkùnkùn. Àwọn èèyàn kì í mọ ohun tó wà nínú òkùnkùn, torí náà wọ́n máa ń fojú sọ́nà fún òwúrọ̀.
Àmọ́ pẹ̀lú Jésù, kò sídìí fún ẹnikẹ́ni láti bẹ̀rù òkùnkùn nítorí pé nígbà tó o bá yàn láti tẹ̀ lé e, o ò ní máa rìn nínú òkùnkùn mọ́, àmọ́ wàá máa gbádùn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Kódà, Ìmọ́lẹ̀ Ayé ni wọ́n pè é nínú Ìhìn Rere Jòhánù. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ kí wíwàníhìn-ín Kristi tó ń fúnni nírètí àti ìtọ́sọ́nà fún ìgbésí ayé tànmọ́lẹ̀ lórí rẹ̀ gbọ́dọ̀ fi ìgbàgbọ́ bá Kristi dọ́rẹ̀ẹ́. Ìyẹn nìkan ló lè mú kó o "kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní sí ibi tó ṣókùnkùn... tó sì máa ń tàn yanran, bí ìgbà tí iná àtùpà bá ń tàn yanran" (Lúùkù 11:36). Tó o bá jẹ́ kí Jésù, Ìmọ́lẹ̀ Ayé, kún inú ìgbésí ayé rẹ, ìyẹn nìkan ló máa jẹ́ kó o lè yẹra fún dídi ẹni tí òkùnkùn ayé àti àwọn ìgbádùn rẹ̀ tó ń tanni jẹ ti kó sínú.
Ronú Jù Lọ Tàbí Jíròrò
1 Jòhánù 1:5 sọ pé, "Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀, kò sì sí òkùnkùn kankan nínú rẹ̀ rárá". Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé Jésù ni Bíbélì pè ní Ìmọ́lẹ̀ Ayé àti pé kò sí òkùnkùn kankan nínú rẹ̀?
Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe ìyàtọ̀ tó wà láàárín gbígbé nínú òkùnkùn àti gbígbé nínú ìmọ́lẹ̀? Ìgbésí ayé wo lo fẹ́ gbé?
Kí ni àwọn ohun tó ń bà ọ́ lẹ́rù tàbí àwọn ibi tó jẹ́ òkùnkùn nínú ìgbésí ayé rẹ tó ń mú kí ìmọ́lẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ má lè tàn? Ṣé wàá ní kó wá tàn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tó ń wẹ̀ ẹ́ mọ́ sínú gbogbo ibi tó ṣókùnkùn nínú ìgbésí ayé rẹ?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Oníbárà tó f'ọ́jú kan tó ń kígbe rara ní ẹ̀bá ọ̀nà, obìnrin kan tí ìgbé-ayé rẹ̀ kò tọ̀nà ní ojú mùtúmùwà tó mọ̀ọ́ṣe, òṣìṣẹ́ ìjọba kan tí gbogbo ènìyàn kórìíra – báwo ni ìkankan nínú àwọn ènìyàn yìí tí àwùjọ ti ta dànù ṣe lè ní ìrètí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run mímọ́? Pẹ̀lú àwọn ìlanilọ́yẹ̀ látinú ìwé Lúùkù nínú Bíbélì Àṣàrò fún Afrika, a ó máa tẹ̀lé Jésù bí ó ti ńṣe ìparẹ́ àwọn àlà tó wà láàárín Ọlọ́run àti àwọn tí a ti gbá sí ẹ̀gbẹ́ láwùjọ.
More