Títẹ̀lé Jésù Olùgbèjà WaÀpẹrẹ

Jésù àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀
Jésù kò ka ẹnikẹ́ni sí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò lè dárí jì í. Kódà ó tẹ́wọ́ gba àwọn tí wọ́n kò láwùjọ.
Látinúàkíyèsí Bíbélì Ìkẹ́kọ̀ọ́ ní Áfíríkà tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “orùn Ìdáríjì”:
Gbogbo wa ni a kùnà láti gbé gẹ́gẹ́ bi Ọlọ́run ti sọ fún wa láti gbé. Àwọn ẹ̀sẹ̀ wa dun Àwọn ẹlòmíràn, nígbà míràn ó pò gaan, Àwọn onígbàgbọ́ tòótọ́ ń hára gàgà láti rí ìdáríjì gbà, lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ẹni tí a ti ṣẹ̀.
Nínú ìtàn yìí, obìnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ kan hára gàgà láti rí ìdáríjì débi pé ó gbójúgbóyà láti wọ ilé aṣáájú ẹ̀sìn pàtàkì kan. Kò pè é, kò yẹ, kò sì tẹ́wọ́ gbà á. Ní ìrẹ̀lẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú Jésù. Ó sunkún. Omijé rẹ̀ sì bà lé ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́sẹ̀, ó sì fi irun orí rẹ̀ gbẹ omijé náà. Bí ó ti ń da òórùn olówó iyebíye lé ẹsẹ̀ rẹ̀, òórùn náà kún inú yàrá náà.
Àwọn ènìyàn mìíràn le dárí jì tàbí kò láti dárí jì wa nígbàtí a bá ti ṣẹ̀ wọ́n. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bà fi ara wa sílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀ sí ẹsẹ̀ Jésù pẹ̀lú ọkàn tí o bàjẹ̀ nít'orí àwọn ẹ̀sẹ̀ wa, kò ta wá dànù. Ó sọ fún wa pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́".
Ronú kí o jíròrò
Arábìnrin náà nínú ìtàn yìí ti gbé ìgbé sì ayé ẹlẹ́sẹ̀ púpò ó sì ti ṣe búburú ńlá níwájú Ọlọ́run. Kí nìdí tó o fi rò pé Jésù dárí jì í?
Ṣé o lérò pé kò yẹ láti maa pè é ní ọmọ Ọlọ́run bí? Kí lódé tàbí kò yẹ kó rí beẹ̀
Bí ìwọ bá jẹ́ wó ẹ̀sẹ̀ rẹ fún Jésù, yíò ha dárí jì rẹ bí? Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa ìmúratán Ọlọ́run láti dárí jì wá?
Báwo ló ṣe yẹ ká dáhùn sí ìdáríjì yẹn
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Oníbárà tó f'ọ́jú kan tó ń kígbe rara ní ẹ̀bá ọ̀nà, obìnrin kan tí ìgbé-ayé rẹ̀ kò tọ̀nà ní ojú mùtúmùwà tó mọ̀ọ́ṣe, òṣìṣẹ́ ìjọba kan tí gbogbo ènìyàn kórìíra – báwo ni ìkankan nínú àwọn ènìyàn yìí tí àwùjọ ti ta dànù ṣe lè ní ìrètí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run mímọ́? Pẹ̀lú àwọn ìlanilọ́yẹ̀ látinú ìwé Lúùkù nínú Bíbélì Àṣàrò fún Afrika, a ó máa tẹ̀lé Jésù bí ó ti ńṣe ìparẹ́ àwọn àlà tó wà láàárín Ọlọ́run àti àwọn tí a ti gbá sí ẹ̀gbẹ́ láwùjọ.
More