Títẹ̀lé Jésù Olùgbèjà WaÀpẹrẹ

Following Jesus Our Mediator

Ọjọ́ 6 nínú 7

Jésù àti Àwọn Oníbàjẹ́ 

Àwọn tí àwọn oníbàjẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba ń ni lára máa ń kórìíra wọn, wọ́n sì tún máa ń bẹ̀rù wọn..

Ibi kíkà kan nínú Africa Study Bible tí àkọlẹ́ rẹ̀ jẹ́ "A Life-Altering Encounter (Alábàpàdé Mánigbàgbé Ayé Ìyípadà Kan)":

Sákíù fẹ́ fi ojú ara rẹ̀ rí Jésù. Ó sa gbogbo ipá rẹ̀ nípa sísáré gun orí igi kan kí ó lè rí Jésù kedere tí ó bá ń kọjá. Kí ó f'ojú kan Jésù nìkan ì bá ti tẹ́ Sákíù lọ́rùn. Ṣùgbọ́n Jésù fún Sákíù ní ìríríi mánigbàgbé kan.

Lẹ́hìn ìgbà tí Sákíù ti bá Jésù pàdé, kò lè tẹ̀síwájú láti máa ṣe iṣẹ́ agbowó òde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ó máa ń lu àwọn ènìyàn ní jìbìtì, ṣùgbọ́n báyìí ó ti wá mọ̀ pé òun ní láti dáwọ́ ìrẹ́jẹ dúró kí òun sì san gbogbo ohun tí òun ti jí padà. Sákíù gbà pé àìṣododo òun ló fa gbogbo òṣì t'ó yí òun ká. Ó wá ní ìmòye ọ̀tun pé òun ní ojúṣe sí àwùjọ òun báyìí.

Sákíù jẹ́ àpẹẹrẹ ẹnìkan tí ó fẹ́ mọ Jésù ní tòótọ́. Nípa tírẹ̀, Jésù fi ọ̀nà tuntun tí a fi ń gbé ayé hàn án. Sákíù gba ọ̀nà yìí tọwọ́tẹsẹ̀ nípa mímú àyípadà bá nnkan tí ó ṣe pàtàkì àti ìhùwàsí òun. Tí a bá tọ Jésù wá, ayé wa á yí padà.

È̩kọ́ míràn t'ó wà nínú ìtàn Sákíù ni pé ìhìnrere lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn, pẹ̀lú àwọn oníwà ìbàjẹ́ àti àwọn t'ó ti rẹ́ àwọn ènìyàn jẹ. Yálà o jẹ́ ẹni tí a kẹ́gàn jù lọ láàrin àwùjọ ni, tàbí ẹlẹ́wọ̀n, ẹni t'ó ń ta òògùn olóró tàbí ẹni t'ó burú jù báyìí lọ, ẹ̀bùn ìgbàlà ti Jésù àti ìgbésí ayé tuntun wà fún ọ.

Ronú tàbí Jíròrò

Jéṣù yàn láti bá Sákíù l'álejò bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn lòdì sí i. Kíló dé tí Jésù fi lọ sí ilé ògbóntarìgì ẹlẹ́ṣẹ̀?

Kí lo rò pé ó jẹ́ kí Sákíu, bí ó ti jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ tó, ṣe àfẹ́rí Jésù? 

Kínni àbáyọrí ìbẹ̀wò Jésù nínú ayé Sákíù àti àwùjọ rẹ̀?

Njẹ́ Jésù ti ní ipa lórí ayé rẹ bí? T'ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ipa wo lèyí ní lórí àwùjọ rẹ?

Ìwé mímọ́

Day 5Day 7

Nípa Ìpèsè yìí

Following Jesus Our Mediator

Oníbárà tó f'ọ́jú kan tó ń kígbe rara ní ẹ̀bá ọ̀nà, obìnrin kan tí ìgbé-ayé rẹ̀ kò tọ̀nà ní ojú mùtúmùwà tó mọ̀ọ́ṣe, òṣìṣẹ́ ìjọba kan tí gbogbo ènìyàn kórìíra – báwo ni ìkankan nínú àwọn ènìyàn yìí tí àwùjọ ti ta dànù ṣe lè ní ìrètí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run mímọ́? Pẹ̀lú àwọn ìlanilọ́yẹ̀ látinú ìwé Lúùkù nínú Bíbélì Àṣàrò fún Afrika, a ó máa tẹ̀lé Jésù bí ó ti ńṣe ìparẹ́ àwọn àlà tó wà láàárín Ọlọ́run àti àwọn tí a ti gbá sí ẹ̀gbẹ́ láwùjọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Oasis International Ltd fún mímú kí ètò yìí ṣeé ṣe. Fún ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: http://Oasisinternationalpublishing.com