Àwọn Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́Àpẹrẹ
DÀRÍJÌ
Tí o bá yàn láti máa tọ Jésù lẹ́yìn, kì í ṣe pé wàá kàn máa rìn ní ọ̀nà tuntun; ó tún túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ò ní máa bínú sí ẹ nítorí ohun tó o ti ṣe sẹ́yìn. Lédè mìíràn, ó dárí jì ẹ́.
Ìrírí ńlá ló jẹ́ láti rí ìdáríjì gbà. Tá a bá ń gbé láìsí ìtìjú tàbí ẹ̀dùn ọkàn, ìyẹn túmọ̀ sí pé a lè máa gbé ìgbésí ayé tó rọrùn.
Èyí tó tún dára jù ni pé: kò dìgbà tó o bá rí ìdáríjì gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run; kó o tó lè rí i gbà.
Ohun méjì ló pọn dandan kéèyàn tó lè rí ìdáríjì gbà.
- Ó yẹ kó o fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé o nílò ìdáríjì.
- Ó yẹ kó o máa dárí ji àwọn èèyàn.
A ò lè rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run gbà, ká wá máa fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹlòmíì. Tí Ọlọ́run bá dárí jì ẹ́, ìyẹn túmọ̀ sí pé o lè dárí jini. O kò ní láti máa gba àmì mọ́. Ọlọ́run ti mú ìwà àìtọ́ kúrò lọ́kàn rẹ, ó sì gbà ọ́ níyànjú pé kó o ṣe bákan náà.
Bó o bá ṣe tètè dárí jini tó, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe tètè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Jẹ́ bíi ti Jésù: Ó dárí jì ẹ́, nísinsìnyí o máa ń dárí ji àwọn ẹlòmíràn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
O ti pinnu láti tẹ̀lé Jésù, kí lo wá ku? Ètò yìí kì ń ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa gbogbo nǹkan tó níṣe pẹ̀lú ìpinnu náà, ṣùgbọ́n yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́.
More