Àwọn Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́Àpẹrẹ
GBÀDÚRÀ
Mo kẹ́kọ̀ọ́ ìṣirò nígbà kan rí níbi tí a sọ̀rọ̀ nípa alugọ́rídíìmù àti kóòdù kíkọ. Tó bá fẹ́ kọ kóòdù, o láti kọ ní pàtó. Láti lè jẹ́ kó yé wa, olùkọ́ wa ní kí a ṣàpèjúwe, ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé, bí a ṣe ń ṣe sandwich elẹ̀pà lílọ̀ àti jam.
Láti lè ṣàṣeyọrí, a ní láti mẹ́nu kan àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó fara sin...
Ṣí ìṣà ẹ̀pà lílọ.
Fi ìdérí rẹ̀ sórí káńtà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìṣà ẹ̀pà lílọ.
Mú ọ̀bẹ bọ́tà.
Fi ọ̀bẹ náà sínú ìṣà ẹ̀pà lílọ.
Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
Kò yẹ kí sandwich ṣíṣe díjú tó báyìí!
Nígbà míì, a máa ń jẹ́ kí àdúrà díjú. Bí o bá ń tẹ̀lé Jésù, àdúrà gbọ́dọ̀ di apá kan ìgbésí ayé rẹ, láìjẹ torí ẹ̀sìn, àmọ́ nítorí ohun tí àdúrà jẹ́ lóòótọ́.
Àdúrà jẹ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀; ó jẹ́ fífara balẹ̀ bá Ọlọrun sọ̀rọ̀ (tọkàntọkàn) lórí àwọn nǹkan tó ń kojú.
Àdúrà jẹ àṣàrò; ó jẹ ìparọ́rọ́, fífiyè sí àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run fi ń bá ẹ sọ̀rọ̀ àti ṣiṣẹ́ layé rẹ.
Àdúrà jẹ ìmọrírì; ó jẹ ìdúpẹ́ fún ayé tí Ọlọ́run ti fún ọ.
Àdúrà jẹ ìgbàgbọ́; ó jẹ ìṣètò ayé rẹ rọ̀gbà yíká ìfẹ́ Ọlọ́run dípò ìfẹ́ ọkàn wa.
Má jẹ́ kó díjú; jẹ́ kó jẹ́ látọkànwá. Àdúrà kò ní láti gùn, bó bá ṣe ń gbàdúrà déédéé, bẹ́ẹ̀ ni yóò túbọ̀ máa wù ẹ láti wà pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
O ti pinnu láti tẹ̀lé Jésù, kí lo wá ku? Ètò yìí kì ń ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa gbogbo nǹkan tó níṣe pẹ̀lú ìpinnu náà, ṣùgbọ́n yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́.
More