Àwọn Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́Àpẹrẹ
ÒTUN
Nígbà tí mo wà ní kilaasi kẹrin, mo wà nínú eré-ìje ònkà ti ilé-ìwé kan, mọ ṣì wà ní ọ̀kan nínú ipò kíní àkọ́kọ́. Láì pẹ́ ni a bi mí ní ìbéèrè mi, èyí tí ó nira jù lọ nínú gbogbo ìbéèrè tí a ti bi mí ní ọjọ́ yen.
Mo sì ṣì í.
Èyí tí ó burú jù lọ nínú rẹ̀ ni wí pé mo mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè méjì tí ó tẹ̀lé e, àwọn ìbéèrè tí yíò díwọ̀n ipò ìkúnní àti ìkejì. Mbá jẹ́ pé àwọn ìbéèrè náà wá ní ònà tí ó yàtọ̀ ni, mbá ti yege.
Ọjọ́ yìí ni ó wù mí jù láti ni ànfàní kejì.
Nígbà tí o bá yàn láti tẹ̀lé Jésù, o máa ní ju ànfàní kejì lọ, wà á ní ayé ọ̀tun.
Nígbà tí o bá yàn láti tẹ̀lé E, ayé ògbó rẹ máa ṣí lọ, ayé ọ̀tun á sì bẹ̀rẹ̀.
Kò kàn ní jẹ́ ànfàní kejì - ayé ọ̀tun ni ó máa jẹ́.
Njẹ́ èyí túnmọ̀ sí wí pé o kò ní láti d'ojú kọ àwọn àbájáde ìgbésẹ̀ tí o ti gbé sẹ́yìn? Rárá o. Ṣùgbọ́n ó túnmọ̀ sí wí pé ẹni tuntun tí o jẹ́ yìí, pẹ̀lú ìṣẹ̀dá titun yìí ti ní ànfàní láti tẹ̀síwájú.
Gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ kíní rẹ nínú títẹ̀lé Jésù á sọ é di ẹni ọ̀tun pátápátá. T'ẹ́wọ́ gba àmì ìdánimọ̀ tuntun rẹ, ṣe àjọyọ̀ ayé tuntun rẹ, kí o sì fi hàn fún aráyé wí pé Jésù dára ju ànfàní kejì lọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
O ti pinnu láti tẹ̀lé Jésù, kí lo wá ku? Ètò yìí kì ń ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa gbogbo nǹkan tó níṣe pẹ̀lú ìpinnu náà, ṣùgbọ́n yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́.
More