Ṣíṣe Okoòwò L'ọ́nà T'ẹ̀míÀpẹrẹ
Ìwọ̀n Ara-ẹni Tí Kò Lẹ́gbẹ̀
Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ̀ wípé o gbé-ìwọ̀n?
O lè má mọ̀, àmọ́ o pójú òṣùwọ̀n ju Bill Gates lọ! Ká pa t'àwàdà tì. Ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tó lọ́rọ̀ jùlọ lí àgbáyé ní àwọn ìdáwọ́kọ́ ńlá tí kò lè ká ìwọ lọ́wọ́ kò níwọ̀n ìgbà tí o bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. Jẹ́ kí a ṣe ìtúpalẹ̀ ọ̀rọ̀ yí...
1. Ní àwòrán Ọlọ́run ni a dá Bill Gates. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Inú dígí kan ni Aṣẹ̀dá wa ti ń wò ara Rẹ̀ nígbàtí Ó ń mọ Bill. Bill wá ṣe àmúlò èyí ní gbogbo ọ̀nà! Àmọ́ ó, bákan náà ni ọmọ ṣ'orí lọ́dọ̀ rẹ, arákùnrin àti arábìnrin.
2. Kristi ń gbé nínú rẹ, ìyẹn ìrètí ògo nì. (Kólósè 1:27) Nípa àwọn ǹkan díẹ̀ tí a wòye nípa Bill, kò ní àǹfààní yìí.
3. Ìwọ ní ọkàn Kristi. (Kọ́ríńtì Kínní 2:16) Lẹ́ẹ̀kan síi, ń kò rò'pé Bill ní èyí pẹ̀lú.
4. Ìwọ ní Ẹ̀mí Mímọ́! Ọlọ́run tó ń gbé nínú rẹ. (Kọ́ríńtì Kínní 3:16) Lẹ́ẹ̀kan síi, àǹfààní mìíràn tí ìwọ ní ju Ọ̀gbẹ́ni Gates nìyí.
Ǹjẹ́ a lè wá sọ wípé ìdá-kan-nínú-mẹ́rin ìgbéléwọ̀n Bill ni ó ń lò? Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, a ní láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba ìgbàlà wa gbọ́! Àti ipa rẹ̀ lóríi ìgbésí-ayé àti iṣẹ́-ọwọ́ wa.
Tí Bill àti àwọn mìíràn bá lè ṣe àṣeyọrí nínú ìdáwọ́lé wọn láìní ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Ọlọ́run, àti láìsí àjàgà ìyàsọ́tọ̀ láàárín ǹkan tara àti t'ẹ̀mí tí wọn dì lé ara wọn, jókòó kí o ro ǹkan tí ìwọ pẹ̀lú lè gbé ṣe! Kàn tiẹ̀ ronú nípa àwọn àǹfààní tí ìwọ ní sí ọgbọ́n àtọ̀runwá àti ìmọ̀ láti gbé ǹkan rọ.
Àkókò ti tó láti gbé ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́-ọwọ́ wa sójú ewé kan náà. Àkókò ti tó fún èmi àti ìrẹ láti ṣe àmúlò àwọn ọgbọ́n àpilẹ̀rọ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí Ọlọ́run fún wa láti tán àwọn ìṣòro tí à ń kojú ní àgbáyé. Kò síbi tí ìṣòro kò sí. Àwọn ìṣòro kan ń jà káàkiri àgbáyé, àwọn mìíràn lè má gbajúmọ̀ lọ títí. Àmọ́ tí ó bá ṣe pàtàkì sí ọ, ó ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run pẹ̀lú nìyẹn.
Matt McPherson jẹ́ ajíhìnrere àti adarí orin ìjọsìn. Ó tún wá fẹ́ràn láti máa dọdẹ ẹran-ìgbẹ́. Ní ọjọ́ kan, ó gbọ́ kedegbe tí Ọlọ́run ń sọ fún un wípé “Mo ní ojútùú sí gbogbo wàhálà tó wà ní àgbáyé. Kání àwọn ẹ̀dá ènìyàn ń gbìyànjú láti béèrè, n kò bá fún wọn ní ìdáhùn. ”
Wàyí o Matt ní àǹfààní láti bèrè fún ojútùú sí ebi tí ń pa ogunlọ́gọ̀ ní àgbáyé. Tàbí bí ó ti lè dá iṣẹ́ ìránṣẹ́ ńlá kan sílẹ̀. Àmọ́ kò ṣe èyí. Níṣeni ó bèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti rọ ọrún tó lágbára.
Ṣé ẹri, wọn ti ṣẹ̀dá àwọn ọrún tó lágbára yìí láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, èyí tóní ọ̀pá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́ àwọn tó rọ ọ́ tí gbìyànjú fún ọdún-mẹ́wàá-ó-lé láti mú kí ọ̀pá méjì yí ta ọfà lẹ́ẹ̀kan náà, àmọ́ pàbó ló jásí. Àìlètafà láì tàsé wá di ìṣòro kan gbòógì fún àwọn ọdẹ.
Lẹ́yìn bíi ọ̀sẹ̀ méjì Matt tají lóru ọjọ́ kan. Ó ní òhun rí ǹkan tó fara jọ ìwé ńlá kan tí a tẹ́ sí iwájú rẹ̀. Ó sì rí àwòrán ọrún ìgbàlódé, tí a fọwọ́ yà, kan lóríi rẹ̀. Ló bá ta kọ́ún tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní da àwòrán yí kọ. Ó wá ṣe àkíyèsí wípé ọrún yí kò jọ irúfẹ́ àwọn èyí tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí. Ọ̀pá kan péré ní ọrún eléyìí ní.
Ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ wípé ilé-ìṣe Honda máa ńṣe ogunlọ́gọ̀ ọkọ̀ ayọkẹ́lẹ́ pẹ̀lú èrè kéréje lórí ìkànkan. Àti wípé ilé-ìṣe Rolls Royce máa ńṣe ọkọ̀ ayọkẹ́lẹ́ péréte àmọ́ pẹ̀lú èrè gọbọi lórí ọkọ̀ ẹyọ kan. Matt McPherson wá bẹ̀rẹ̀ ilé-ìṣe tíó pé ní Mathews Inc., lónìí wọ́n jẹ́ ilé-ìṣe tó tóbi jù tí ń pètò ọfà, ọrún àti àwọn èròjà rẹ̀. Bíi Roll Royce, èrè ńlá ni wọn ǹjẹ́ lóríi ọrún ìgbàlódé tí wọ́n ń tà.
Matt tẹ̀síwájú láti pilẹ̀rọ dùrù ìgbàlódé kan pẹ̀lú, àwọn McPherson Guitars yí sì wá jẹ́ ojúlówó káàkiri àgbáyé. Iṣẹ́-ọwọ́ Matt wá di iṣẹ́-ìránṣẹ́ rẹ̀. Dòní Matt sì máa ń rìn káàkiri àwọn ilé-ìtajà àdúgbò rẹ̀ ní ìlú Wisconsin láti wàásù ìhìn rere. Ó sì fi Ọlọ́run ṣe ìṣáájú síbẹ̀ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ̀.
Kí ló wá dí ìwọ lọ́wọ́? Kíló fàá tí Ọlọ́run ò ṣe rí ìwọ lò láti wá ojútùú sí ìṣòro kan ní orílẹ̀ èdè rẹ... tàbí ní agbègbè tàbí ibiṣẹ́? Gbogbo àgbáyé ló ń kérora fún àwọn ojútùú tí wọ́n nílò, àwọn ènìyàn Ọlọ́run sì ní àǹfààní sí àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá tó lè mú ìwòsàn àti àlàáfíà dé bá orílẹ̀-èdè. Àkókò ti tó láti béèrè.
Nígbàtí mo kọ́kọ́ mẹ́nu ba àdúrà Matt McPherson lẹ́ẹ̀kan, njẹ́ ara fu ọ́ bí? Ṣékọ́ni o wòye wípé ẹni tó bá jẹ́ onígbàgbọ́ ní tòótọ́ ìbá bèrè fún ǹkan tó nííṣe pẹ̀lú...ǹkan t'ẹ̀mí? Tó bá ríbẹ̀, bóyá ìwọ náà ti kósí páńpẹ́ ṣíṣe ìyàsọ́tọ̀ láàárín ǹkan tara àti ti ẹ̀mí.
Nípa Ìpèsè yìí
Mo gba irọ́ kan gbọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Irọ́ yìí wọ́pọ̀ l'ágbo Krìstìẹ́nì. Mo gbàgbọ́ nínú ìyàtọ̀ láàrin ohun tí kò jẹ mọ́ ẹ̀sìn àti ohun-mímọ́. Èyí fà mí sẹ́hìn gidi. D'arapọ̀ mọ́ mi láti ṣe àgbéyẹ̀wò bi Ọlọ́run ṣe fẹ́ẹ́ fí okun ẹ̀mí kún wa láti mú Ọ̀run wá sínú Ayé yìí àti láti ṣe àṣeyọrí nínú okoòwò atí ìgbé-ayé. A ní ànfààní púpọ̀ láti la ipa nínú ayé ju àwọn "òjíṣẹ́ Ọlọ́run orí ìjọ" lọ, ìlànà Bíbélì yìí yíò fi bóo ti rìn hàn ọ́!
More