Ṣíṣe Okoòwò L'ọ́nà T'ẹ̀míÀpẹrẹ
Ní Ayé Bí Ó Ti Wà L'Ọ́run
Ní ànọ́ a kọ́ wípé gẹ́gẹ́bí onísòwò, ìpèe wa wá tààrà látọ̀dọ̀ Olúwa. A ní àǹfààní láti ṣe àfihàn agbára Ọlọ́run ní ọ̀nà àrà-ọ̀tọ̀ fún àwọn ìpèníjà àgbáyé tó ń kérora fún ojútùú. Ó sì yẹ kí èyí mú àyípadà dé bá ìṣọwọ́ gbàdúrà wa.
A máa ń gba àdúrà tí Jésù fi kọ́wa nínú Bíbélì. Àmọ́ kíni ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an? Àti wípé kíni ó nííṣe pẹ̀lú òwò wa?
Ó túmọ̀ sí wípé tí ǹkan náà kò bá sí ní Ọ̀run kò gbọ́dọ̀ sí ní Ayé pẹ̀lú. Tí kò bá sí ní Ọ̀run, kò gbọ́dọ̀ sí nínú ayé mi, ẹbí mi, tàbí okòwò mi. Nínú àwọn ǹkan tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ni àìní-ìdáríjì, ìjà, àti ìdẹnukọlẹ̀ okòwò. Lára rẹ̀ tún ni òṣìṣẹ́ tàbí ọ̀gá tí kò dára. Bẹ́ẹ̀ni kò yọ ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àti àìlẹ́tọ́jú oníbàárà sílẹ̀. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ǹkan yìí tó wà nínú ètò Ọlọ́run.
Báwo wá ni yóò ti rí nígbà tí Ìjọba Ọ̀run bá borí Ìjọba Ayé yìí?
Ní ṣeni ìfẹ́ Ọlọ́run yóò wá sí ìmúṣẹ ní Ayé, bí ó ti wà ní Ọ̀run. Àwọn ènìyàn, àwọn okòwò, àti àwùjọ máa gbèrú síi. Àṣà ma ní ìfọwọ́tọ́ sí rere. Àwọn oníbàárà ma rí ọjà àti iṣẹ́ tó pójúowó rà, bẹ́ẹ̀ni oníṣòwò àti àwọn òṣìṣẹ́ ma kó èrè tabua.
Ògo, ìfẹ́ àti agbára Jésù yóò wá bú jáde. Àwọn òṣìṣẹ́ á máa ṣiṣẹ́ kárakára wọ́n ó sì di ọkọ tàbí aya, òbí, ọ̀rẹ́ àti olùjọsìn dáradára. Pẹ̀lú èyí, ayé yóò wá súnmọ́ ìpinnu àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run ní fún àwa ènìyàn nínú ọgbà Édẹ́nì.
Nígbàtí òye wa, nípa ǹkan wọ̀nyí, bá pé yéké, ìṣọwọ́ gbàdúrà wa yóò yàtọ̀. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí mo ti di ádárì okòwò, máà gbàdúrà nípa ìjèrè-ọkàn, àìsàn àti ìdàgbàsókè ìjọ. Mo máa ń gbàdúrà fún ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́. Àmọ́, a máa lọ́ mi lára láti gbàdúrà fún àṣeyọrí okòwò mi. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn páńpẹ́ tí mo mẹ́nu bà nínú ètò t'àná. Ǹjẹ́ ìṣọwọ́ gbàdúrà rẹ kò máa rẹ̀wẹ̀sì nítorí irúfẹ́ irọ́ yìí?
Ó ní ọkùnrin kan tó jẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, tó sì máa ńṣe àtúnṣe àwọn ohun-ọ̀ṣọ́-ilé gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ òjọ̀ọ́. Ó ṣe àkíyèsí wípé àwọn kẹ́míkà tí ó fi ńṣe àtúnṣe àwọn ohun-ọ̀ṣọ́ yìí lè pànìyàn lára, ó wá pinu láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ tí kò bá sí ọ̀nà àbáyọ mìíràn. Ó ṣáà ń po àwọn ǹkan mélòó kan pọ̀ láti ṣe ìṣẹ̀dá kẹ́míkà titun tí a lè fi ṣí ọ̀dà lára igi tí kò sì ní pani lára. Àmọ́ ó fẹ́ ṣe àpilẹ̀rọ̀ èyí tó dára bíi àwọn ẹ̀yà tó wà l'ọ́jà tẹ́lẹ̀. Òhun àti aya rẹ̀ wá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìdáhùn.
Lọ́jọ́ kan, ó wálé láti gbé oúnjẹ ọ̀sán fún aya rẹ̀. Obìnrin náà wà nínú oyún lákòókò yí, bó sì ti tají látojú orun ráńpẹ́, ni ọmọbìnrin yí sọ fún ọkọ rẹ̀ nípa àlá kan níbi tí ó ti rí àwọn lẹ́tà onírúurú tó yani lẹ́nu. Ọkùnrin yìí wá ní ìtanijí wípé orúkọ àwọn kẹ́míkà kan ni àwọn lẹ́tà náà jẹ́. Nígbà tí ó padà dé ibiṣẹ́, ó po àwọn kẹ́míkà inú àlá ìyàwó rẹ̀ papọ̀.
Kẹ́míkà titun yìí wá jẹ́ ojúlówó kẹ́míkà tí a lè fi sí ọ̀dà lára igi tí kò sì ní pani lára. Iṣẹ́ kẹ́míkà náà tún wá dáa bíi àwọn ẹ̀yà tí a pètò ní àwọn ilé-iṣẹ́ ńlá. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní tà á ní erékùṣù rẹ̀. Lọ́kọ-láya yìí wá padà ta ìmọ̀ àpilẹ̀rọ̀ yìí fún ilé-iṣẹ́ ńlá kan. Wọ́n ra oko-ayọ́kẹ́lẹ́ tí ènìyàn lè fi ṣe ibùgbé èyí tó wá gbà wọ́n láàyè láti máa jíhìn rere káàkiri Amẹ́ríkà.
Ǹjẹ́ o nílò ọgbọ́n fún okòwò rẹ lónìí? Àbí ìpèníjà kan wà ní àyíká rẹ tó nílò ojútùú? Mo lè fi dá ọ lójú wípé Ọlọ́run ní ìdáhùn tó tọ́ fún wọn, àti wípé Ó ṣetán láti tipasẹ̀ rẹ fà wọ́n wá sí Ayé, láti Ọ̀run. Iṣẹ́ rẹ ni láti bèrè...àti láti retí ìdáhùn.
“Ṣugbọn nígbà tí Ẹ̀mí òtítọ́ tí mo wí bá dé, yóo tọ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo. Nítorí kò ní sọ ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀; gbogbo ohun tí ó bá gbọ́ ni yóo sọ. Yóo sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fun yín.” Jòhánù 16:13
Nípa Ìpèsè yìí
Mo gba irọ́ kan gbọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Irọ́ yìí wọ́pọ̀ l'ágbo Krìstìẹ́nì. Mo gbàgbọ́ nínú ìyàtọ̀ láàrin ohun tí kò jẹ mọ́ ẹ̀sìn àti ohun-mímọ́. Èyí fà mí sẹ́hìn gidi. D'arapọ̀ mọ́ mi láti ṣe àgbéyẹ̀wò bi Ọlọ́run ṣe fẹ́ẹ́ fí okun ẹ̀mí kún wa láti mú Ọ̀run wá sínú Ayé yìí àti láti ṣe àṣeyọrí nínú okoòwò atí ìgbé-ayé. A ní ànfààní púpọ̀ láti la ipa nínú ayé ju àwọn "òjíṣẹ́ Ọlọ́run orí ìjọ" lọ, ìlànà Bíbélì yìí yíò fi bóo ti rìn hàn ọ́!
More