Ṣíṣe Okoòwò L'ọ́nà T'ẹ̀míÀpẹrẹ
Má kan ẹni tí ó ti jíǹde mọ'gi
Bí a ṣe ń ṣe okoòwò wa l'ọ́nà t'ẹ̀mí, ó ṣe pàtàkì pé kí a má tún kan ẹni tí ọ tí jíǹde m'ọ́gi..
Dúró... o ní kíni?
Bíi ẹ̀ẹ̀meje nínú Ìhìnrere, Jésù pà'ṣẹ fún àwọn ọmọẹ̀hìn rẹ̀ pé kí a di òkú sí ara wa. Mo gbà pé eléyìí túmọ̀ sí pé kí a di òkú sí ìwà ìmọtaraẹni-nìkan, ìfẹ́ búburú kí a sì fi Ìjọba àti Ọba ṣáájú.
Nínú Róòmù orí 6 sí 8, Pọ́ọ̀lù m'ẹ́nu ba gbígbé ìgbé-ayé àjíǹde bíi ìgbà ogójì. Èyí ni ìpè wa... láti gbé nínú agbára àjínde Jésù ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.
Mo gbọ́ tí ẹnìkan sọ pé “Ṣùgbọ́n dúró na”. “Jòhánù Onít ọmọ wípé, ‘Òun kò lè ṣáìmá pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹ̀hìn.’ Ṣé eléyìí kọ́ ló yẹ kó jẹ́ àdúrà wa?”
L'ákòtán, mí ò lérò bẹ́ẹ̀. Jòhánù, wòlíì tó ga jù gbogbo wòlíì lọ, gẹgẹ bí Jésù ṣe sọ, sàpẹẹrẹ òpin sáà kan. Òpin Májẹ̀mú Láíláí. Òpin sáà Òfin àti àwọn Wòlíì. Jòhánù àti iṣẹ́ tí a fi rán an ti ń k'ógbá wọ'lé.
Ikú àti àjínde Jésù ń ṣe ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ọtún nínú ìran ènìyàn. Irúfẹ́ ẹ̀dá titun ló fẹ́ wọ'lé wá: Ènìyàn tí Ọlọ́run ń gbé inú rẹ̀. Ẹni tí ó jẹ́ nìyí.
Nítorí náà bóyá àfojúsùn rẹ ní láti yípadà. Dípò kí o gbá'jú mọ́ ohun tí ọ níílò láti parun nínú rẹ, ó lè jẹ́ pé àsìkò nìyìí láti ṣàwárí ohun tí Ẹ̀mí fẹ́ mú gbòòrò síi nínú rẹ. (Kí a lo gbogbo agbára wa láti dojú kọ pípa ẹ̀ṣẹ̀ run kìí kúkú ní àbáyọrí kankan tẹ́lẹ̀. Lílo agbára wa láti mú kí ìtara wà fún Jésù gbòòrò síi ni ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀.)
Èmi àti Ìwọ ni a pè láti pa ìmọtara-ẹni-nìkan run. Ṣùgbọ́n kìí ṣe pé kí a pa ìfẹ́ tí Ẹ̀mí ń ru sókè nínú wa run. Ìwọ ní ìfarahàn àmì òde ara pé Jésù ńgbé orí ilẹ̀ Ayé lónìí. Ẹ̀mí Mímọ́ gbé ọ wọ̀ bí ẹ̀wú.
Olúwa yóò lò àwọn ohun tí o ní fẹ̀ sí, àwọn ìpòǹgbẹ rẹ àwọn ìtara re ẹ̀bùn, àbùdá, àti ìrísí rẹ. Eléyìí rú mi l'ójú ni bíi ọdún díẹ̀ sẹ́hìn. Mo rò pé ìpòǹgbẹ mi láti ṣe àṣeyọrí nínú okoòwò wà l'ára ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tí mo gbọ́dọ̀ parun. “... àti pé mo sì gbọ́dọ́ re'lẹ̀.” Àmọ́ ṣá eléyìí wà lára àwọn òfútùtùfẹtẹ̀ ìyàtò tí a fí sáàrin ohun tí kò jẹmọ́ t'ẹ̀sìn àti ohun ẹ̀mí. Ìyàtọ̀ tí ohùn ọ̀tá ní rú s'ókè.
Onígbàgbọ́ tí ọ kún fún Ẹ̀mí gbọdọ̀ wà l'ókè téńté okoòwò, ìṣẹ̀dá ñkan, ìmọ̀-ẹ̀rọ, ìmọ̀ ìṣaralóge, iṣẹ́ ọnà àti iṣẹ́ orin. Àmọ́ a kò le dé ojú ìwọ̀n yìí bí a bá kàn ń gbìyànjú láti pá Ẹni àjínde run.
A kò sì le dé'bẹ̀ láíláí bí a bá ń j'owú ẹlòmíràn. Tí ọ bá ní òye ìpè Ọlọ́run lórí ayé rẹ, ìtara Ọlọ́run fún ọ, àti agbára Ọlọ́run tí kò ní ìdiwọ̀n láti mú Ọ̀run wá sí Ayé láti ipasẹ̀ rẹ, o kò ní fẹ́ dàbíi ẹlòmíràn láíláí. Ka gbólóhùn yẹn lẹ́ẹ̀kansíi kí o sì ronú lée l'órí.
Wàyìí irúfẹ́ ìpòǹgbẹ wo ni Ọlọ́run fi sí ọ nínú? Ṣé o ti di òkú sí àwọn àlá tí Jésù fẹ́ sọjí? Àti pé irúfẹ́ àwọn àlá tuntun wo ni O fẹ́ kí o lépa wọn lónìí? Mò ń gbàdúrà pé kí o rìn nínú àyànmọ́ kíkún àti ìpè rẹ, kí o gbé ìgbé ayé rẹ ní kíkún. Òun ni yíó gba ògo, ìwọ yíò sì gbádùn ayé rẹ d'ọ́ba!
Rántí pé a kò dá A l'ọ́wọ́ kọ́ látàríi ohun tí ọ lè bèèrè tàbí ronú rẹ̀. (Éfésù 3:20-21)
ọjọ́_5Nípa Ìpèsè yìí
Mo gba irọ́ kan gbọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Irọ́ yìí wọ́pọ̀ l'ágbo Krìstìẹ́nì. Mo gbàgbọ́ nínú ìyàtọ̀ láàrin ohun tí kò jẹ mọ́ ẹ̀sìn àti ohun-mímọ́. Èyí fà mí sẹ́hìn gidi. D'arapọ̀ mọ́ mi láti ṣe àgbéyẹ̀wò bi Ọlọ́run ṣe fẹ́ẹ́ fí okun ẹ̀mí kún wa láti mú Ọ̀run wá sínú Ayé yìí àti láti ṣe àṣeyọrí nínú okoòwò atí ìgbé-ayé. A ní ànfààní púpọ̀ láti la ipa nínú ayé ju àwọn "òjíṣẹ́ Ọlọ́run orí ìjọ" lọ, ìlànà Bíbélì yìí yíò fi bóo ti rìn hàn ọ́!
More