Ṣíṣe Okoòwò L'ọ́nà T'ẹ̀míÀpẹrẹ

Doing Business Supernaturally

Ọjọ́ 6 nínú 6

Ẹni tó ti Kú Kìí Ṣeré Géle

Lánàá a sọ̀rọ̀ pé kí á má tún kan Ẹni tó ti jíǹde mọ́ àgbélébùú mọ́. Tí a bá ń gbé ìgbé ayé ẹni tó jíǹde...pẹ̀lú ìdánilójú pé Ọlọ́run wà fún wa àti pé Ẹ̀mí Rẹ̀ wà nínú wa...à ń rìn nínú ìgboyà yí. Ìgbésí ayé kan tí a kò le mọ̀ nìyí tí ẹ̀sẹ̀ àti ayé pálapàla bá ti gbé wa mì. 

Mo lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nínú ìjọ kan tí ká rẹ ara ẹni sílẹ̀ mu lómi. Kìí ṣe lọ́nà tó yẹ. A ò fi ọwọ́ tó ayé ènìyàn púpọ̀ fún Kríístì. Ṣùgbọ́n nígbàtí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn nínú agbára àjíǹde, mo bọ́ sí òpópónà àwárí! Mi ò tíì rí irú ara yíyá gágá tó jù báyìí lọ láti ìgbà tí mo ti ń gbé ìgbé ayé tuntun yìí. Irú ayé yìí kìí ṣe oun tí ó tayọ ẹni kẹ níwọ̀n ìgbà tí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú rẹ.

Mo fẹ́ sọ ìtàn Máàkù. Máàkù ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ tí olùdá sílẹ̀ jẹ́ alaini gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ọmọkùnrin ẹ̀yà Júù. Máàkù ńkọ́ ẹ̀kọ́ bí ó ti ṣe lè máa rìn ní ìgbésí ayé ti ati ji dide, Máàkù bèrè sí ní gbàdúrà fún àwọn alaba ṣiṣẹ́ pọ̀ rẹ̀. 

Ní ọjọ́ kan ó gbọ́ tí ọ̀gá rẹ̀ aláìgbàgbọ́ yìí ń ṣe àròyé ẹ̀fọ́rí líle. Máàkù ṣe ọkàn gírí ó sì bèèrè láti gbàdúrà fún ìmúláradá. Nínú ìpọ́njúrẹ̀, ọ̀gá yìí gbà. Máàkù gbàdúrà ní kíá ara ọkùnrin yí sì dá lójú ẹsẹ̀t! Orí ọ̀gá yìí wú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ó tíì tán síbẹ̀. 

Níwọ̀n àkókò dí ẹ̀ lẹ́yìn èyí, ilé iṣẹ́ yìí gbé ibi ìṣeré a-pọ́n-kùn-yí-kiri kan síta fun yíyá níbi àpéjọ àwọn ilé iṣẹ́ ńlá ní ìlú Las Vegas. Èyí jẹ́ àǹfààní pàtàkì fún àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ láti fi ọkàn wé ọkàn pẹ̀lú àwọn oníìbárá wọn. Ọ̀rọ̀ ò rí bóti yẹ, bí àsìkò ti ń tó láti bẹ̀rẹ̀ ni ìjì líle ṣú dẹ̀dẹ̀. Olùdarí a-pọ́n-kùn-yí-kiri sọ fún ọ̀gá àgbà wípé òun yóò palẹ̀mọ́. Nítorí ó léwu láti máa ṣeré a-pọ́n-kùn-yí-kiri nígbàtí ìjì n bọ̀. 

Ọ̀gá aláìgbàgbọ́, omo ẹ̀yà Júù fi àáké kọ́rí, ó kọ etí ikùn. “Máàkù! Wá níbí.” Ọ̀gá sọ fún Máàkù pé kí ó gbàdúrà pé kí ìjì náà kọjú sí ipa ọ̀nà míràn láì dé ibi a-pọ́n-kùn-yí-kiri yìí. 

Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n ní tèmi ó jẹ́ oun tó lè kani láyà. Iru ẹ̀fọ́rí jẹ́ ọ̀kan. Ṣùgbọ́n à ń sọ̀rọ̀ iji tó lágbára. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dáhùn èyí bí? Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni ti ṣèyí bí lẹ́yìn Jésù?

Síbẹ̀ ìfúndùn mọ́ ni yìí ń pọ̀ si. Máàkù yí sí kọ̀rọ̀ láti tẹ ọ̀rọ̀ sí ọ̀rẹ́ àti ẹbí...rárá o, láti bẹ̀ wọ́n pé kí wọn gbàdúrà. Àkókò tó fún Ọlọ́run láti Rìn! Bí o ṣe ń tẹ ọ̀rọ̀ yí, ó gbọ́ ohùn ọ̀gá rẹ̀ tí ń bú nítòsí. Ó ti pe àwọn oníìbárá jọ láti ṣe àlàyé bí wọn yóò tí ṣẹ rìn-ín fún wọn...

“Ní kò pẹ́ yìí a gbọ́ pé ìjì ń bọ̀ tí yóò mú kí fífi a-pọ́n-kùn-yí-kiri yìí má ṣeéṣẹ. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ wa, Máàkù, yóò gbàdúrà sí i. Nígbà náà ìjì náà á gba ibòmíràn lọ a ó sì padà sí eré wa. Ẹ ṣeun fún sùúrù yín.” 

Ọkàn Máàkù pò ruru. Ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n àkókò dí ẹ̀ sí ìgbà yí, ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fèsì wípé òún rí àwòrán kan “òrùlé ààbò” tó bo orí ibi a-pọ́n-kùn-yí-kiri nínú ojú inú òun. Nínú ìgboyà yí, Máàkù jáde síta o sì gbàdúrà kí ìjì gba ibòmíràn lọ. 

Ìjì yí ń sún mọ́ wọn síbẹ̀. Ṣùgbọ́n lójú kaná oun kan tó yàtọ̀ ṣẹlẹ̀. Àwọsánmà ìjì tó sú jọ pé ó pín sí méjì. Ìjì yí gba apá ọ̀tún àti òsì. Ibi eré a-pọ́n-kùn-yí-kiri ò sì rí óhóró òjò kan. Ẹnìkan tó dúró lọ́kàn kán ya àwòrán tí ó sì jọ lóòótọ́ bí ẹni pé òrùlé wà lórí ibi a-pọ́n-kùn-yí-kiri. Àgbègbè tí òjò ò rọ̀ sí. 

Ọlọ́run gba ògo. Ọ̀pọ̀lọpọ ènìyàn ní a tí fi ọwọ́ tọ́ tí ìtàn yí sì ti tàn káàkiri. Máàkù pàápàá ti wúwo síi níwájú ọ̀gá rẹ̀. Ta ni o lérò pé ọ̀gá yí yóò sáré pé tí ó bá ní ìpinnu tó ta kókó láti ṣe? 

Ǹjẹ́ o ṣe àkíyèsí pé Máàkù kò nílò láti jẹ́ ọ̀gá pátápátá kí ó tó lè ní ipá pàtàkì? Gẹ́gẹ́ bíi Dáníẹ́lì, Jósẹ́fù, àti Ẹ́sítérì nínú ìwé Májẹ̀mú Láíláí, o kò ní lò láti jẹ́ ọ̀gá pátápátá kí o tó lè kó ipa pataki. 

Ipa tí Máàkù ní tún lè kó ipa pàtàkì lóríi àwọn ọjà tuntun, àwọn ìlànà àmúlò ilé ìṣẹ́, àti irúfẹ́ tí ilé iṣẹ́ yóò jẹ́. Bíi àwọn ènìyàn nínú ìwé Májẹ̀mú Láíláí, Máàkù lè jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ọ̀gá yóò kọ́kọ́ pè ní àkókò rúkè rúdò. 

Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ òún fi ara rẹ sí ipò àti kó ipa tó I tẹ ìwọ̀n lóríi àṣà? Ǹjẹ́ òún gba Ọlọ́run gbọ́ pé Yíò bá ọ ṣiṣẹ́ láti mú ọ̀run sọ̀kalẹ̀ sí ayé? Ayé yìí ń kígbe síta fún àtúnṣe sí àwọn ìṣòro kékeré àti ńláńlá ọlọ́kanòjọ̀kan. Àwọn ìṣòro bàntà bàntà yí tó bá àjàkálẹ̀ àìpẹ́ yí. 

Ọlọ́run Ń retí wa láti mú ìmọ̀ràn àti ojú inú Rẹ̀ lò kí á bá lè fi àmúlò ọgbọ́n ọ̀run ṣe àtúnṣe l'aye ká sì lè kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ àtúnṣe ọ̀run fún ìṣòro ayé. Oun tí Jésù ṣe ní àpẹẹrẹ nípa mímú àwọn ènìyàn lára dá náà ni agbára tí a fi ń yí oko òwò padà…àti àgbègbè…àti àwọn orílẹ̀-èdè. 

Ìbẹ̀rẹ̀ lásán lèyí. Tí o bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ àkójọpọ̀ àwọn onígbàgbọ́ alágbára tí ó ún fi okun ọ̀run dá oko òwò, tẹ ojú òpó yìí Ọ̀NÀ ÀSOPỌ̀ láti le mọ̀ SÍI. A lè jùmọ̀ ṣeé papọ̀! 

Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Doing Business Supernaturally

Mo gba irọ́ kan gbọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Irọ́ yìí wọ́pọ̀ l'ágbo Krìstìẹ́nì. Mo gbàgbọ́ nínú ìyàtọ̀ láàrin ohun tí kò jẹ mọ́ ẹ̀sìn àti ohun-mímọ́. Èyí fà mí sẹ́hìn gidi. D'arapọ̀ mọ́ mi láti ṣe àgbéyẹ̀wò bi Ọlọ́run ṣe fẹ́ẹ́ fí okun ẹ̀mí kún wa láti mú Ọ̀run wá sínú Ayé yìí àti láti ṣe àṣeyọrí nínú okoòwò atí ìgbé-ayé. A ní ànfààní púpọ̀ láti la ipa nínú ayé ju àwọn "òjíṣẹ́ Ọlọ́run orí ìjọ" lọ, ìlànà Bíbélì yìí yíò fi bóo ti rìn hàn ọ́!

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Gateway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ ṣ'àbẹ̀wò sí: http://dbs.godsbetterway.com/