Ìdánilójú ní Àwọn Àkókò Tí Kò Sí ÌdánilójúÀpẹrẹ
Ina kàn wà nínú wà tí o nduro lati tàn. Iná yi le tàn káàkiri sí àwọn tí ó wà ní àyíká wa tí a bá fún ní oun tí yíò fí máà jo dáradára. Iná náà sì lágbára jù àwọn ìdánwò tí ó ṣokunkun sí ọ̀, tí ó lé ní ìmọ̀lára rẹ. Ó ní agbára láti borí àwọn àwọn àbùkù tí o yí ọ ká ní àkókò yí.
Iná náà, itara náà, àti agbára inú jẹ oun tí Ọlọrun fí sí inú wà fúnra Rẹ. Ìtara láti ṣe ohun tí ó yẹ lati ṣe, ohunkóhun tí ìyẹn lè jẹ. Agbára inú láti fún wà ní ifòrítì àti láti gbé orí wà soke lai bìkítà gbogbo atako tàbí idojukọ tí ó lè ní.
Mo lè má mọ ohun tí ọjọ ọlá yíò mú wà, ṣugbọn mo mọ dájú mo ní látí jẹki nkán ṣẹlẹ l'oni.
Mo lè mà ní ìdánilójú bí mo ṣe máà dé ibí afojusun mí, ṣugbọn mo ní ìdánilój ohun tí ó jẹ afojusun mí.
Kò yé mí tó ọnà tí mo lè gbà láti ṣe àṣeyọrí, ṣugbọn ó dá mí lójú pé èmi yíò ṣe àṣeyọrí.
Ó dá mí lójú gbangba.
Mo tí pinnu nínú ọkàn mí.
Ọlọrun mi tí pèsè àwọn ohun èlò àmúyẹ láti mú àwọn àlá mí wá sí ìmúṣẹ. Ó tí ńfi ìṣọ́ Rẹ ṣọ́ láti ìgbà ìṣẹ̀dá mí wà, ifẹ Rẹ sí ńwá sí ìmúṣẹ lórí mí nígbà gbogbo.
Kò yé mí bí mo ṣe lè ṣe, ṣugbọn ó tún yé mí. Èmi kò mọ ìgbà tàbí àkókò tí èmi yíò dé ibí afojusun mí, ṣugbọn mo mọ pé yíò ṣe ṣe.
Ó dá mí lójú.
Ohunkóhun ti ó lè máà làkọjá kò ṣòro fún Olúwa. Ohunkohun tó wù kó jẹ, yálà, ìrora ni, ẹ̀rù ní, ìbànújẹ ní, másùnmáwo ni, àníyàn ní, tàbí aidaniloju ní, á ó mú dání lójú nipasẹ Jésù Kristi.
Ní àkókò ainidaniloju, má ṣe bẹrù, jẹ kí ìdánilójú kí ó jẹ tirẹ.
Láti kàn sí David Villa, Tẹ ibí yìí!
Láti forúkọ sílẹ̀ fún podcast látẹnu David, Tẹ ibí yìí!
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú àìnídánilójú, Ọlọ́run dájú! Darapọ̀ mọ́ David Villa nínú ètò ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Ó wò kọjá àwọn àìdájú àtẹ̀yìnwá àti àìda kí ó bàa lè mú òun tó dára jù lọ.
More