Ìdánilójú ní Àwọn Àkókò Tí Kò Sí ÌdánilójúÀpẹrẹ
A kò lè fi gbogbo ìgbà mọ̀ dájú ohun tí yíó ṣẹlẹ̀. Kò sí bí a ṣe le mọ ohun tí ọjọ́ ọ̀la yíó mú wá fún ẹnikẹ́ni. A lè wo sàkun àwọn ohun wọ̀nyí. A lè fojú inú ṣ'òdinwọ̀n. A lè gb'ìyànjú láti ṣ'àkíyèsí àwọn àpẹẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ kí a sì dà wọ́n rò, ṣugbọ́n kò sí ẹni tó mọ ilẹ̀ tí yíó mọ́ ọ̀la. Òní nìkan la ní.
Òní sì tó fún wa.
O ti jàjàbọ́ lọ́wọ́ àwọn ọjọ́ burúkú dé bii gẹ́ẹ́. Gbogbo àyídáyidà àti ìfàsẹ́hìn. Wọn kò b'orí rẹ. O ti d'ojúkọ òkè ìṣòro púpọ̀ s'ẹ́hìn, o sì ti d'ojúkọ àwọn àtakò abanilẹ́rù tí ó dàbíi wípé wọ́n ńm'ókè, sùgbọ́n síbẹ̀ o yọ jáde gẹ́gẹ́ bíi olúborí.
Ní àsìkò àìsídanilójú, a yàn làti ní ìdánilójú
Ìdánilójú tí a ní kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀ àyíká wa bíkòṣe nínú Ọlọ́run wà, tí Ó ń pèsè fún wa tí Ó sì ń dáàbò wá.
Ìdánilójú – Ìgbàgbọ́ tó f'ẹsẹ̀ múlẹ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ǹkán rí. Àmúyẹ jíjẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé. Kókó ọ̀rọ̀ tó jẹ́ òtítọ́ tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí kò le ṣàì má w'áyé.
Àìnídánilójú – Ipò kámi-kàmì-kámi. Ohun tí kò dájú tàbí tí ó ń mú ènìyàn ṣiyèméjì.
Àìnídánilójú á wípé, “Mi ò mọ bí ọjọ́ ọ̀la mi yíó ṣe rí.”
Ìdánilójú a wípé, “Mo mọ ẹni tí ó ní ètò ọjọ́ ọ̀la mi lọ́wọ́!”
Wíwà láìní Jésù ni wíwà láìní àlááfíà. Wíwà láìní ìdánilójú. Gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀rí-ọkàn tí a gbọ́dọ̀ kún ojú òṣùwọ̀n rẹ̀ kí a tóó lè l'áyọ̀ tòótọ́. Ohun kanṣoṣo ló lè fún ẹ̀rí-ọkàn ní àlááfíà, òhun náà ni níní ìbáṣepọ̀ tó gúnmọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.
Jà fún ohun tó ṣe pàtàkì sí ọ jùlọ. Jà fún ìgbàgbọ́ rẹ. Jà fún ẹbí rẹ. Jà fún ẹ̀mí rẹ. Má gba ìṣelòdì àti àìnììdánilójú láàyè láti gùn sínú ọkàn rẹ. Ọlọ́run ṢÌ WÀ nínú okoòkòwò à ń bùkún ni.
Àsìkò tó làti lé àìnídanilójú dànù kí a sì wá ààyè fún ìfọkànmúlẹ̀. Ìṣelòdì ti dúró pẹ́ jù, àsìkò ti tó fún ìṣerere làti wọlé wá!
A ní làti fi Jésú tó dánilójú han ilé-ayé tó kún fún àìnídánilójú.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú àìnídánilójú, Ọlọ́run dájú! Darapọ̀ mọ́ David Villa nínú ètò ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Ó wò kọjá àwọn àìdájú àtẹ̀yìnwá àti àìda kí ó bàa lè mú òun tó dára jù lọ.
More