Ìdánilójú ní Àwọn Àkókò Tí Kò Sí ÌdánilójúÀpẹrẹ
Ní ojoojúmọ́, àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé máa ń tan ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán wọn láti gbọ́ ìròyìn.
Púpọ̀ nínú àwọn ilé-iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ ló máa ń fi ọ̀rọ̀ léde nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ káàkiri àgbáyé.
Onírúurú ìròyìn láabi ló kún orí ìtàkùn ayélujára.
Bí wọn kò tilẹ̀ wọ́pọ̀ bíi tẹ́lẹ̀, onírúurú àtẹ̀jáde àti ìwé ìròyìn ṣì wà ní àwùjọ.
Àti wípé ìpayà àti ìròyìn aburú pẹ̀lú gbilẹ̀ ní àwùjọ wa.
O kò lè sá fún un. Ó hàn kedegbe l'ójú wa. Bíi àjàkálẹ̀ àrùn ni ìròyìn aburú ti rí.
Èsì wo ni a wa ń fi?
À ń yí ẹ̀rọ tí a fi ń gbọ́ ìròyìn sókè.
À ń tẹ ọ̀rọ̀ àsopọ̀ tí ń gbéwa lọ sí ibi tí ìròyìn yí wà lóríi ayélujára.
À ń ṣí ìwé ìròyìn náà sójú ewé mìíràn.
A sì ń gba ìròyìn aburú yìí láàyè láti gbilẹ̀ lọ́kàn wa. À ń gba àwọn ǹkan bíi ogun tí ń jà lọ́wọ́, àìsàn titun tí ń tàn, tàbí ìdẹnukọlẹ̀ ọrọ̀-ajé láàyè láti fa ìdààmú fún ọkàn wa.
Èé ṣe tí a fi ń gba irú ǹkan báyìí láàyè? Kí ni à ń rí gbà gan-an nínú àwọn ìròyìn láabi yìí?
Àyà ń fò wá.
Kìíṣe ǹkan tí ó pamọ́ wípé òkùnkùn birimù ló wà nínú ayé, tí ó sì ṣetán láti fi àwọn tó bá tẹ́'tí síi s'ábẹ́ ìgbèkùn.
Àmọ́ ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú wà.
Àti wípé, ibikíbi tí ìmọ́lẹ̀ bá wà, òkùnkùn kò leè borí.
Ìmọ́lẹ̀ tó ń fi ìgbà gbogbo tàn sí mi pàápàá ní àwọn àkókò òkùnkùn ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí láì fi ipò tí o bá ara rẹ ṣe, Bíbélì ma tọ́ ìṣíṣẹ̀ rẹ láti la ìpèníjà náà kọjá. Ìdẹnukọlẹ̀ ọrọ̀-ajé, ìdojúkọ nínú ìgbéyàwó tàbí ìbáṣepọ̀, àwọn ìṣòro tó ń jẹyọ ní ibiṣẹ́, ní ilé-ìwé, àbí àjálù káàkiri àgbáyé, gbogbo rẹ̀ ni yóò dà bíi eré-modé ní àfiwé sí Olúwa, àti sí àkókò aláìlópin. Bíbélì rẹ ni orísun ìmọ́lẹ̀ aláìlópin.
Kódà nínú yàrá tó ṣókùnkùn birimù birimù, tí a bá fi lè tan àtùpà kan, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò lé òkùnkùn dànù. Kódà lákòókò ìpọ́njú, nínú àjálù àti àìní ìdánilójú, ìmọ́lẹ̀ tí Olúwa tàn fún wa ma padà borí. Kò sí ohun tó lágbára tó o. Kò sí ohun tó mọ́lẹ̀ tó o.
Nínú òkùnkùn, èmi pinu láti fà súnmọ́ ìmọ́lẹ̀. Láti gba ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ láàyè láti mọ́lẹ̀ sínú ayé mi àti láti darí mi sí ọjọ́ ọ̀la tó dára.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú àìnídánilójú, Ọlọ́run dájú! Darapọ̀ mọ́ David Villa nínú ètò ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Ó wò kọjá àwọn àìdájú àtẹ̀yìnwá àti àìda kí ó bàa lè mú òun tó dára jù lọ.
More