Ìdánilójú ní Àwọn Àkókò Tí Kò Sí ÌdánilójúÀpẹrẹ
Nkàn ò kín fi gbogbo ìgbà rí bí ati ṣètò rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbẹ̀yìn wọ́n á jásí bí Ọlọ́run ti ṣètò rẹ̀.
Ìgbé ayé kò ṣe gbé láì ní àwọn ìkọlù kéékèèké lójú ọ̀nà. Ìkùnà ò sí nínú àwọn ìkọlù yìí, a leè rí nígbàtí a bá gba àwọn ìkọlù yí láàyè láti dábùú òpópónà wọn. Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú ìdádúró tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi já wọ́ lẹ́nu ìlépa rẹ. A ò lè darí oun tó ún ṣẹlẹ̀ sí wa, ṣùgbọ́n a lè darí bí a ṣe dojú kọọ́. Oníwàásù Charles R. Swindoll sọ rí nígbà kan pé gbígbé ayé jẹ́ ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún oun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ àti ida àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún bí o ti ṣe fèsì síi.
Èrò inú rẹ jẹ́ oun tó lágbára. Mo gbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn tó ṣẹ àṣẹyọrí kì iṣẹ́ nítorí pé wọ́n ní ẹ̀bùn jù tàbí nítorí wọ́n ní ìmọ̀. Àwọn ènìyàn Aláṣẹ yọrí ń ṣàṣeyọrí nítorí wọ́n ní ọkàn fun àṣeyọrí pàápàá nínú ìjákulẹ̀.
A gbọ́dọ̀ gbára lé ètò ìlànà, pàápàá nígbàtí ìrìn àjò yẹn bá rí gbọ́gun gbọ́gun. Ọlọ́run Ń pèsè rẹ fún ètò tí Òùn ti dá ọ láti rìn. Ọlọ́run Ń mú wa kọjá nínú oun tí mo pè ní “ìgbà fífá tàn tàn” láti pèsè wa pẹ̀lú ọpọlọ tó pé fún ibi tí Ó ún mú ọ wá lọ.
Níní ìdánilójú ní àkókò tí kò dájú yìí kò túmọ̀sí pé kí á dijú sí oun tó ún ṣẹlẹ̀ láyìíká wa. Kò túmọ̀sí pé óò ní ní ìmọ̀lára ìfòyà, nítorí èèyàn ṣáà niwá. Ó túmọ̀sí pé, bíi ọmọ lẹ́yìn Jésù, yàn láti ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ẹ̀rù ati àìda tó lè yí wa ká. Ó túmọ̀sí pé botilẹ̀jẹ́pé ẹ̀rù wà nínú ọkàn, a mọ̀ pé Ọlọ́run Yóò pèsè ohunkóhun táa nílò láti tẹ̀ síwájú.
Ní àkókò tí kò dájú, Bíbélì rẹ dájú.
Ọlọ́run dájú.
Jésù ti ṣe ìpinnu ọkàn Rẹ̀ gírí.
Ǹjẹ́, a lè máa gbé nínú ayé tó ní pẹ̀kun ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí à ń sìn kò ní ìpẹ̀kun.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú àìnídánilójú, Ọlọ́run dájú! Darapọ̀ mọ́ David Villa nínú ètò ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Ó wò kọjá àwọn àìdájú àtẹ̀yìnwá àti àìda kí ó bàa lè mú òun tó dára jù lọ.
More