Ìdánilójú ní Àwọn Àkókò Tí Kò Sí ÌdánilójúÀpẹrẹ
Ní àkókò ayé ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìròyìn n tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní kíákíá ju tàtẹ̀yìn wá lọ.
A lè béèrè oun koun tí a fẹ́ lọ́wọ́ Google anything, o sì lè máà kà nkan lórí àkọlé tí o ṣí fún ọ̀sẹ̀ pípẹ́. Lọ́wọ́ kan tí o bá titẹ bọ́tìnì atọ́ka ẹ̀rọ ayára-bí-àṣá (kọ̀mùpútà), tàbí ká tàka lásán, o le è kọ́ ẹ̀kọ́ yòówù tí o nílò nípa ohunkóhun. Bó ti ṣe pé nǹkan tó dára ló yẹ kí èyí jẹ́ ní ayé tí a wà yìí, kìí rí bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Pẹ̀lú ìmọ̀ ní jaburata náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ tó ń ṣini lọ́nà. Àwọn ìròyìn tí a fi igbá kan bọ̀ kan nínú tó bẹ́ẹ̀ tí a kò mọ irọ́ yàtọ̀ sí òótọ́.
Ìlà tó wà láàárín òkodoro ọ̀rọ̀ àti èròńgbà ti rẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ àwọn oníròyìn àti ilẹ̀ iṣẹ́ ìròyìn tí kò lépa òtítọ́ bíi ìwọ àti èmi.
Ìràwọ̀ kú-iṣẹ́ ni wọ́n ń lé.
Nígbàtí ẹ̀rù bá nba àwọn ènìyàn, wọn á tọ ìròyìn lọ. Wọ́n ń fẹ́ ìfọkànbalẹ̀ tàbí ní ìmọ̀ síi lórí oun tó ún já wọn là yà. Síbẹ̀, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni à ń gba ọ̀rọ̀ ènìyàn ní òkodoro ọ̀rọ̀. À ń kà a ṣì ń gbọ́ a sì ń lérò pé ohunkóhun tí kọ sílẹ̀ tàbí wọ́n sọ fún wa ni òtító, láì rò pé àwọn agódo ìròyìn tí à ń lò náà lè gba ìròyìn irọ́.
ÒTÍTỌ́ kan ṣoṣo tí a mọ̀ ni pé Jésù Kríístì kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Òtítọ́ kan ṣoṣo tí a mọ̀ yìí ni a ti jẹri, tọ́ka, ṣe àwárí rẹ̀ ni pé Ọlọ́run Yóò wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí. Fún ṣíṣí àti pípadé. Òun ni Oun kọ ati atunHe is the author and the editor, and his word is final. Kò sí oun koun láti pọn dandan láṣọ. Kò sí òtítọ́ kan tí Ọlọ́run Kò í tí tú síta.
Mi ò sọ pé kí ẹ má ka ìròyìn mọ́. Láti máa fi ọkàn tán àwọn tó yíi yín ká. Oun tí mò ń sọ fún un yín ni pé, ju oun táa ti kọ sílẹ̀ lọ, ju oun táa tí ròyìn, Ọlọ́run mọ̀. Èròńgbà Ọlọ́run fún ọ kọ̀ lè yípadà nítorí ìṣe ènìyàn. Èròńgbà Ọlọ́run kìí ṣe ségesège, kò sì dúró lórí oun tó ún ṣẹlẹ̀ láyìíká wa.
Ní àkókò tí kò dájú, Ọlọ́run dájú. Nígbàtí àwọn èròńgbà wa bá já kulẹ̀ tí ó sì yí, ìlànà tí Ọlọ́run ti ṣe sílẹ̀ fún wa ni Yóò mú ṣe.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú àìnídánilójú, Ọlọ́run dájú! Darapọ̀ mọ́ David Villa nínú ètò ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Ó wò kọjá àwọn àìdájú àtẹ̀yìnwá àti àìda kí ó bàa lè mú òun tó dára jù lọ.
More