Bọ́ Sínú Ìgbésí Ayé Tó Ní Ìtumọ̀Àpẹrẹ

Step into Purpose

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ìforítì Nínú Ìgbàgbọ́

Òpó akọni àràmàndà lọ ti wà tí wón ti lo sáájú wa, wón gbé ìgbésí ayé tó ní ìtumọ láti ṣe ohun tó yàtò, wón yí ayé padà dì ohun tí a mò lónìí.

Àwọn orúkọ jankan-jankan bíi Nelson Mandela, Mother Teresa, kódà Bethany Hamilton (ẹní tó jé pé láìka àléébù ara ékò juwọ́ sílẹ̀ lórí ìdí ìwàláàyè àti ìpè é).

A lè rí èkọ́ kọ́ lára àwọn aṣáájú àràmàndà wọ̀nyí, àtìpé òpó ànímó ìwà ní o mú wọn di akọni tó dá yàtọ̀. Àmó sa o, Mo fé jé kí akíyèsi mi dà lórí ànímọ́ ìwà tí àwọn méta yìí ni, èyí tó se pàtàkì sí‘gbigbé ìgbése sínú ìdí ìwàláàyè’, - ìyẹn sí jé Ìforítì nínú ìgbàgbó!

Ìforítì lè jé isé tó lè nígbà tí a ń gbé ní ilé ayé tó kún fún ohun búburú - àgàgà sí àwọn Kristẹni àti Olórun. Àmó ohun kan ti o lè dá ọ lójú nipé Ọlọrun ń mbè pèlú e! Tí Olúsèdá é bá pè ọ tí O sí sèdá ìdí ìwàláàyè é, O gbèrò fún ọ láti dé bé . O lè dàbí ohun tó tóbi jù é lọ nísìsiyìí… njé o mò nńkan, O TÓBI JÙ É LỌ! Jé kín fún ọ ní ìsirì pèlú ìtàn bí wòlíì Jeremáyà, se jé àti bí Ọlọrun se pè é.

Ní Jeremáyà orí 1 (ni kúkúrú), a ríi pé Ọlọrun pè Jeremáyà láti jé wòlíì kìí ṣe sí àwọn èèyàn é nìkan àmó sí ORÍLÈ ÈDÈ - isé tó ń báni lérù àbí? Ní àfikún Olórun tún dá a lójú àti mú Jeremáyà gbára dì fún ète e (Jer. 1:9-14). Ni tòótọ, kò rọrùn fún Jeremáyà ní abala ìdí ìwàláàyè e, àmó Ọlórun se ìlérí fún Jeremáyà pé Òun kò ní fi sílè tàbí pa a tì .

Láti àyọkà a lè ní ìdánilójú pé Ọlọrun fé jé kí o dé bí ète e, kódà ti isé náà bá lẹ kọkọ. A lè sákíyèsí ifòrítì Jeremáyà láti ṣáṣeyọrí pèlú Olórun! Òta kò lè fọwọ́ kàn ohun Olórun tí yàn, àyàfi tí a bá gbà láàyè. Olórun tí pè é láti ṣáṣeyọrí nínú ìdí tó fi dá é sáàyè nítorí O gbàgbó nínú é Ọ sí dá é fún ìdí yẹn pàtó. O wa pèlú e ọ sí ní àwọn òrun tín tìlẹ́hìn! Tolórí náà bèrè iṣé, máa tẹ̀ síwájú má ṣe fetí sí àwọn ìrò àti àwọn òrò ìrèwèsì. Ìforítì se pàtàkì láti rí kókó ìwàláàyè tí Olórun fún é wa sí ìmúse!

Ìwò gangan, tó ń kà ètò yìí, lè jé àtìpé wa jẹ́ akọni tí ayé nílọ, tórí náà s ọkàn gírí kí o fetí sí ìlérí tí Ọlọrun se fún Jeremáyà - "'Wón máa dojú ìjà kọ ọ àmó won ko ní borí e, nítorí Mo wa pèlú è Mo máa gbà o ,' Olúwa so èyí.” (Jer. 1:19)


Ashleigh Meyer Lọ Ko Ìwé Yìí

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Step into Purpose

Kí ni kókó ìwàláàyè mi? Kí ni ǹkan tí a dá mi láti gbé ṣe? Kíni ètò Ọlọ́run fún mi? Wọ̀nyí ni àwọn ìbéèrè tí púpọ̀ nínú wa ma ń bèrè nígbà kan tàbí òmíràn ní ìgbésí ayé wa. Ìlépa wa ni láti ṣe ìtúpalẹ̀ ohun tí a nílò láti ṣe fún ipa àti láti ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà. Darapọ̀ mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga ti C3 bí wọ́n ti ń tan ìmọ́lẹ̀ sí kókó náà.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ C3 Church Sydney Pty Ltd fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.c3college.com/