Bọ́ Sínú Ìgbésí Ayé Tó Ní Ìtumọ̀Àpẹrẹ
Èrèdí Ìdádúró
Ìgbé ayé òde òní, ìgbé ayé kánmọ́-ń-kíá ni. Ohun gbogbo ní láti ṣẹlẹ̀ ní kánkán. A ò le mú sùúrù, àbájáde èsì ní láti jẹ́ lójú ẹsẹ̀. L'ọ́pọ̀ ìgbà, báyìí ni a ṣe ń máa ńwo ìdáwọ́lé wa.
A lè gbàgbọ́ pé Ọlọ́run pè wá fún ohun kan - láti darí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn nínú ìjọ́sìn, láti ní okoòwò tí ó ńlọ déédéé àti kí a gba owó lẹ́gbẹ̀lẹ́gbẹ́ ní owó oṣù, láti ṣàwárí ìfẹ́ ẹni bíi ọkàn wa kí a sì gbé wọn níyàwó, láti lọ káàkiri ayé kí a máa kéde ìhìnrere... àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Kò sí ohun tó burú nínú kí a gbàgbọ́ pé àwọn ǹkàn yìí lè ṣẹlẹ̀. Àmọ́ ṣá, l'ọ́pọ̀ ìgbà ó máa ǹgba àsìkò àti pé kí a mú sùúrù kí a tó rí wọn gbà!
Àfojúsùn ní pé Dáfídì tó ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dògún nígbàtí Sámúẹ̀lì fi òróró yàn-án l'ọ́ba Ísráẹ̀lì, síbẹ̀ Dáfídì kò gbà ipò tí ó fi di ẹni ọgbọn ọdún (2 Sámúẹ̀lì 5:4)! Ní gbogbo ọdún tí ó fi ńdúró yìí, Ọlọ́run ńpèsè Dáfídì sílẹ láti di ọba. Nínú aginjù ni Dáfídì tí kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí o l'apa rere jùlọ nínú ayé rẹ̀, n'íbi tó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ló lè gbẹ́kẹ̀lé.
Ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ìwé Sáàmù fi irú ìbànújẹ tí Dáfídì là kọjá hàn wá, àwọn ẹkún tó sun, ṣùgbọ́n a tún rí bí ó ti kọ́ nípa òtítọ́ Ọlọ́run, nípá ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ àti bí Dáfídì ṣe rí okun àti ààbò nínú Rẹ̀. Ka Sáàmù 25. Líla àwọn àkókò yíì kọjá mọ Dáfídì láti jẹ́ ẹni ńlá àti èèyàn Ọlọ́run tí Ọlọ́run tí yàn láti jẹ́ ọba Ísráẹ́lì
Gẹ́gẹ́ bíi Dáfídì, àsìkò ìdádúró jẹ́ àsìkò tí ohun gbogbo lè má lọ déédéé, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ àsìkò tí Ọlọ́run ńmúra wa sílẹ̀ fún ohun gbogbo tó wà níwájú wa bí a ṣe ń d'ásẹ̀ wọ inú àwọn ohun tó ní l'étò fún wa! Fọkànbalẹ̀ pé Ọlọ́run ńlọ pẹ̀lú rẹ bí o ṣe ń d'ásẹ̀ wọ inú àwọn ohun ńlá tí Ó ní l'étò fún ọ.
A kọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ Joshua Sijl
day_2 https://my.bible.com/reading-plans/16177 https://my.bible.com/reading-plans/16177-step-into-purpose/day/1Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Kí ni kókó ìwàláàyè mi? Kí ni ǹkan tí a dá mi láti gbé ṣe? Kíni ètò Ọlọ́run fún mi? Wọ̀nyí ni àwọn ìbéèrè tí púpọ̀ nínú wa ma ń bèrè nígbà kan tàbí òmíràn ní ìgbésí ayé wa. Ìlépa wa ni láti ṣe ìtúpalẹ̀ ohun tí a nílò láti ṣe fún ipa àti láti ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà. Darapọ̀ mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga ti C3 bí wọ́n ti ń tan ìmọ́lẹ̀ sí kókó náà.
More