Bọ́ Sínú Ìgbésí Ayé Tó Ní Ìtumọ̀Àpẹrẹ
Ìdí Ìwàláàyè Tí A Mú Rọrùn
'Ìdí ìwàláàyè' jẹ́ èrò kan tí kò yé mi nígbà tí mo jẹ́ ọmọdé tò ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà nínú ìjọ.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ lò mi? Ìgbà wo ni mo máa mọ̀? Kínni ó yẹ kí n ṣe kí àsìkò yí tó tó? Àwọn ìbéèrè yí ni mo máa ń bèèrè lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà láì gbọ́ èsì kankan, èyí tó sì máa ń mú kí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì.
Èrò yí máa ń bá ọkàn mi ja ìjàkadì ṣáá ni títí di ọjọ́ kan tí mo ṣe alábàpàdé ọ̀rọ̀ kan nínú ìwé mímọ́ tí ó yí ayé mi padà - “Ohunkohun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kor. 10:31)
Ìṣípayá de.
Nítòótọ̀, Ọlọ́run ní ìdí ọ̀tọ̀ pàtàkì tó fi dá oníkálukú wa. Nítòótọ́, ìdí ìwàláàyè tìrẹ yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ìdí yìí wà fún ojúlówó àti àpapọ̀ ìdí kan: láti fi ògo fún Ọlọ́run.
Ọlọ́run kò wá kí á gbé iyì òun lárugẹ! Ìfẹ́ ńlá tí Ó ní sí wa ló wà ní'dìí pé kí á fi ògo fún Un. O mọ̀ pé nígbà tí a bá mọyì dídára Òun tí a sì fi ògo fún Òun, a ó ní ìṣípayá, a ó sì ní òye ìfẹ́ Òun lọ́nà tó jinlẹ̀. Ìfẹ́ yìí ń yí gbogbo nnkan padà.
Ọlọ́run ní ìfẹ́ wa bóyá a f'ògo fún Un tàbí a kò f'ògo fún Un, ṣùgbọ́n àfẹ́rí Rẹ̀ ni pé kí á mọ ìfẹ́ yìí lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́. Ògo ni fún Ọlọ́run. Ìdí ìwàláàyè wa nìyí.
Hannah White ló kọ ọ́
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Kí ni kókó ìwàláàyè mi? Kí ni ǹkan tí a dá mi láti gbé ṣe? Kíni ètò Ọlọ́run fún mi? Wọ̀nyí ni àwọn ìbéèrè tí púpọ̀ nínú wa ma ń bèrè nígbà kan tàbí òmíràn ní ìgbésí ayé wa. Ìlépa wa ni láti ṣe ìtúpalẹ̀ ohun tí a nílò láti ṣe fún ipa àti láti ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà. Darapọ̀ mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga ti C3 bí wọ́n ti ń tan ìmọ́lẹ̀ sí kókó náà.
More