Ṣíṣe Àkóso Àkókò N'ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ
Lò àkókò tí ó ní láti fì ìfẹ́ hàn sí ara rẹ̀
Tí a bá ní agbára láti fẹ̀ran àwọn ẹlòmíràn dáradára, a nílò láti fi àkókò silẹ láti fẹ́ràn ara wá dáradára pẹ̀lú. Ìyẹn fí ye wá pé kìí se ara nìkan ní a ní láti tún ṣe ṣùgbọ́n ìtọ́jú tí ó péye ní láti wá fún ohun tí ó jẹ mọ́ ẹ̀mì, ẹ̀dùn ọkàn, àti ọpọlọ wá pápá. Nígbàtí a bá bù ọlá fún ara wá pẹ̀lú àsìkò tí a ní, èyí túmọ̀ sí wípé a ní agbára tí ó gá jù láti ṣe àfihàn àwọn èso tí Ẹ̀mí ní ìgbésí ayé wá. Nígbàtí a kò bá nífẹ̀ ara wa pẹ̀lú àsìkò tí a ní, àwọn èso Ẹ̀mí lè dá bí ẹni pé a ń bá ara wa jíjà kádì láti jẹ yọ“Ṣugbọn eso ti Ẹmí ni ifẹ, ayọ̀, alafia, ipamọra, ìwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ́, Ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni". ~Gálátíà 5:22-23(KJV)
Bí a ṣe tọju ara wá dáradára sì kó lè mú ìyípadà tí ó yẹ kí ó yani lénu wá Ó kàn jẹ́ mọ ká fí àṣà kékèké díẹ múlẹ̀ yóò sì di ohun tí ó mọ̀ wá lára láti máà ṣe nígbàkúùgbà
Fún àpẹẹrẹ nípa bí a ṣe ń ṣe itọju tí Ẹ̀mí, ó lè fí ara jìn fún Bíbélì kíkà àti àdúrà ní ọjọ kọ̀ọ̀kan. Mo fẹ́ràn láti fi àkókò ìdákẹ́jẹ́ ṣe ohun àkọ́kọ́ ní òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ó lè ṣe àwárí àsìkò tí ó rọrùn fún ara rẹ̀. Lẹ́hìn náà kì ó jẹ kí ó mọ̀ ọ lára irú àfikún àkókò tí ó nílò pẹ̀lú Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, nígbàtí mo bá ńlá òkè ìṣòro kọjá, mo nílò àfikún àkókò láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn n kánkán.
Fún àtúnṣe ara, orun sísùn, ouńje jíjẹ, àti eré ìdárayá ní àwọn kókó ipilẹ tí ó ń mú ara jí pé pé. Orun sísun lóòre kóòre, jíjẹ ouńjẹ tí ó ń fún ara ní ìlera tí ó péye, àti fífi àyè silẹ láti ṣe ohun tí ó lè mú wá làágùn kí ara lè ní àlàáfíà tí ó yàtọ̀. Láti bẹ̀rẹ̀, gbìyànjú ńkan tí ó rọrùn bí í láti fi agogo sì àsìkò ìtanijí "gbara dì láti sún" sì orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ tí yóò máà dùn lóòre kóòre. Lẹ́hìn èyí fi ọkàn sì láti tètè sún kí ó lè ní àkókò tí ó tó fún orun rẹ.
Pẹlu ìtọ́jú ẹ̀dùn ọkàn, a nílò láti mọ ohun tí ó jẹ àníyàn ẹ̀dùn ọkàn wá tí a ń gbé kiri kí a bàá kò wọn lé Ọlọ́run lọ́wọ́ lóòre kóòre.
“Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.” ~1 Peter 5:7 (NLT)
Fún èmi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtúsílẹ̀ àwọn àníyàn ọkàn bayi ní ó máà ń wáyé ní àkókò àdúrà òwúrọ̀ mi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà míràn ẹ̀wẹ̀, mo ní àwọn nkan míràn láti ṣíṣẹ́ lè lórí, àti pé mo nílò àfikún àkókò nínú àdúrà nígbà míì tàbí kí máà bá ọ̀rẹ́ jíròrò.
Lákòótán ará, pẹ̀lú ìtọ́jú ọpọlọ wá, a nílò láti ní òye ohun tí a gbà láyé nínú ọkàn wá àti ohun a gbà láyé láti dúró síbẹ̀.
Gẹ́gẹ́bí ìwé Romu 12:2 (NIV) ṣe ṣàlàyé pé à kò gbà ìpalọ́lọ́ láyè nígbàtí ó bá kan èrò ọkàn wa: “Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.”
Ìyẹn túmọ̀ sí pé à ní láti lòdì sí àwọn irọ́ àti ìfiránsẹ́ òdì láti inú ayé kí a sì dojú kọ ẹni tí Ọlọ́run ní a jẹ́ nínú Kristi. Bí èròkerò bá wà sínú ọkàn rẹ tó ń jẹ ki o lérò pé ó jẹ́ aláìyẹ, ẹni tí kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ẹni tí a kò fẹ́ tàbí alábùkù, ó nílò láti fi òdodo ọ̀rọ̀ láti inú ìwé mímọ kò lójú pé ní òtítọ́ ní ó jẹ ẹni pípé àti àyànfẹ́!
“Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fi fẹ́ wa, tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ ni a sá à jẹ́” ~1 John 3:1a (NIV)
Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ, àti pé Òun pápá fẹ́ kí ó fẹ́ràn ara rẹ̀.
Bí ó bá gbádùn ètò ẹ̀kọ́ kíkà yí, ìwọ yóò nífẹ́ Ìṣàkóso àkókò tí Ẹ̀mí: Ayọ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ní eto fún yín
Ìṣàkóso àkókò tí Ẹ̀mí, ìwé náà, fi ojú ìjìnlẹ̀ wo báwo ní a ṣe lè fí Ọlọ́run ṣe ẹni tí mbẹ ní àárín gbùngbùn ìṣàkóso àkókò. Ìrora dínkù àti ìbùkún sì pọ́ sì!
Ṣe ìwádí díẹ̀ sì nípa ìwé náà kì ó sì ṣe àwárí àfikún àwọn ọrọ̀ tí ńbẹ́ nínú rẹ̀ http://www.DivineTimeBook.com
ÌDÀGBÀSÓKÈ Bọtini: ọjọ_6 ọjọ_6Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bá a ṣe máa ń lo àkókò wa lọ́nà tó bófin mu lè fa másùnmáwo nígbà tá a bá ń sapá láti "ṣàkóso" ìgbésí ayé wa nípasẹ̀ agbára àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ fún wa pé a máa ń ní àlàáfíà àti ìsinmi nígbà tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nípa àkókò wa. Nínú ìwéwèé ọjọ́ mẹ́fà yìí, wàá mọ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń lo àkókò rẹ ṣe lè mú kó o rí gbogbo ohun rere tó ní fún ọ gbà, títí kan ayọ̀ àti àlàáfíà Rẹ̀.
More