Ṣíṣe Àkóso Àkókò N'ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ

Divine Time Management

Ọjọ́ 2 nínú 6

Fífi Àkókò Rẹ Lé Ọlọ́run Lọ́wọ́

A le túmọ̀ ìgbekẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí "ìgbàgbọ́ tó rinlẹ̀ tí a ní nínú ìfọkàntán, òtítọ́, àti agbára ẹnìkan tàbí ohun kan” A lo ọ̀rọ̀ yíi ju ìgbà 150 lọ nínú Bíbélì. Ọ̀kan nínú àwọn àkòrí gbòógì nínú Bíbélì ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run. Nínú Bíbélì, a ríi pé nígbà tí àwọn ènìyàn gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, wọ́n jẹ ìgbádùn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì tún gbẹ́kẹ̀lé nnkan mìíràn lòdì sí Ọlọ́run, wọ́n jìyà rẹ̀.

Jeremaya 17:7-8 (YCE) ṣ'èlérí àwọn ìbùkún yìí fún àwọn t'ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:

“Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, 

tí ó fi OLUWA ṣe àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò

tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò. 

Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé;

nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini. 

Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀

nígbà gbogbo ni yóo sì máa so.”

Báwo ni ìgbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run pẹ̀lú àkókò wa nítòótọ́ ṣe rí ganan? Gẹ́gẹ́ bí Krìstẹ́nì, a máa ń sábà ronú pé kí á bèèrè ìtọ́ni lọ́dọ̀ Ọlọ́run tí a bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó ṣe pàtàkì bíi irú iṣẹ́ tí k'á ṣe, ibo ni k'á máa gbé tàbí tani kí á jọ ṣe lọ́kọ láya. Ṣùgbọ́n ó máa ń ṣeé ṣe fún wa láti gbàgbé láti bẹ Ọlọ́run pé kí ó darí wa lórí bí a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́.

Àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a fi leè fi ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run sí àrin gbùngbùn ìṣàkóso àkókò wa nìyí:

  • :Gbọn àwọ̀n ètò re wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́: F'ojú sùnnùkùn wo gbogbo àwọn nnkan tí ò ń ṣe pátápátá. Gbàdúrà dé'bi pé o ri ìdáhùn gbà lórí ohun tí ó yẹ kí o lo àṣikò púpọ̀ tàbí kékeré sí.
  • Mú ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run lọ́kùnúnkúndùn: Ya àkókò sọ́tọ̀ fún ẹ̀kọ́ Bíbélì àti àdúrà lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú Bàbá rẹ l'Ọ́run kí o sì gbé gbogbo àjàgà rẹ lé E lọ́wọ́. 
  • Sinmi lé Ọlọ́run: Mú ọjọ́ kan fún Ìsinmi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti ní àsìkò míràn tí ó bá yẹ gẹ́gẹ́ bí àmì pé o gbàgbọ́ pé Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ. 
  • Tú ọwọ́: Tí ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn bá máa ń ká ọ lára ganan, sọ fún Ọlọ́run pé kí Ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ pé Ó fẹ́ràn àwọn tí ó ṣe pàtàkì sí ọ. Tí ó bá ṣe pé o máa ń fẹ́ kí iṣẹ́ ṣá jẹ́ ṣíṣe ni, bèèrè pé kí Ọlọ́run ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lè gba mímójútó àìní àwọn ènìyàn láàyè nínú ọkàn rẹ.

Gẹ́gẹ́ bí Krìstẹ́nì, bí a ṣe ń lo àkókò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wa pẹ̀lú àkókò yẹ kí ó fi hàn pé fún ìṣàkóso àkókò, Ọlọ́run ni a gbẹ́kẹ̀lé kìí ṣe ara wa. 


Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Divine Time Management

Bá a ṣe máa ń lo àkókò wa lọ́nà tó bófin mu lè fa másùnmáwo nígbà tá a bá ń sapá láti "ṣàkóso" ìgbésí ayé wa nípasẹ̀ agbára àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ fún wa pé a máa ń ní àlàáfíà àti ìsinmi nígbà tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nípa àkókò wa. Nínú ìwéwèé ọjọ́ mẹ́fà yìí, wàá mọ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń lo àkókò rẹ ṣe lè mú kó o rí gbogbo ohun rere tó ní fún ọ gbà, títí kan ayọ̀ àti àlàáfíà Rẹ̀.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Elizabeth Grace Saunders fún ìpèsè èrò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ sii, jọ̀wọ́ ṣàbẹ̀wò: http://www.divinetimebook.com/