Ṣíṣe Àkóso Àkókò N'ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ

Divine Time Management

Ọjọ́ 4 nínú 6

Fi àkókò rẹ̀ gbé Ọlọ́run lárugẹ 

Ọlọ́run jẹ́ bàbà tó dára àti pé ó fún wa ní ẹ̀bùn ìtọ́ni sọ́nà tí ó hàn kedere nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n Òun kò kàn fẹ́ fí ìwé ìtọ́sọ́nà fún ìgbé ayé lè wá lọ́wọ́, jẹ wá níyà tí a bá ṣé asesemáse, kó sì tún fí ojú gáàni wá ní ọ̀run.Ọlọ́run ní ìpinnu tí ó jinlẹ̀ láti bá wá gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó yẹ nínú ìrìn-àjò wá pẹ̀lú Rẹ̀Ìdí nìyí tí ó fí jẹ́ wípé ọkàn nínú àwọn ọ̀nà tí ó gá jùlọ láti ló àkókò wá ní láti nífẹ́ Ọlọ́run.

Gẹ́gẹ́bí a ṣe rí ká nínú ìwé Mátíù 22:37-38 (NIV) tí ó sọ pé: “Jesu dáhùn pé, “‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ."Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ"'.

Nítorí náà kíni ó ṣé jẹ́ gan-an láti nífẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú àkókò wá? Àwọn ọ̀nà púpọ̀ lo wá. Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ní díè nínú àwọn tí ó ṣé pàtàkì:Ìjọ́sìn, Ọ̀rọ̀, àti Àdúrà

Nígbàtí a bá fí àsìkò sílẹ́ láti jọ́sìn yálà lápápọ̀, bí ẹni ń lọ sí ilé ìjọsìn, tàbí olúkúlùkù ní àyè ara rẹ̀, tí a bá ńtẹ́tí sí orin ìyìn tí a bá wà ní inú igbó, a ń rán ara wa létí ẹni tí Ọlọ́run ìṣe àti ẹni tí á jẹ́ ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. Á rántí agbára ńlá àti ìṣe rere Rẹ̀ a sì mú wa wá sí ìrántí bí Ó ṣe fẹ́ wá to. Àṣà ìbọ̀wọ̀fúnni àti ìfẹ́ yí ń bù kún ọkàn wa àti tí Ọlọ́run pẹ̀lú

Bí àkọsílẹ̀ ṣé wá nínú Sáàmù 27:4(NIV):“Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.”

Á sì tún lè fí ìfẹ́ wá hàn fún Ọlọ́run nípa fífi àsìkò sílẹ̀ láti kà ìwé mimọ Nígbàtí a bá ká Bíbélì, a ó jèrè òye tí ó jinlẹ̀ sí nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti pẹ̀lú ohun tí Ó ń fẹ́ kí a ṣe. Ó ṣe pàtàkì fún wá láti mọ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ láti ọ̀dọ̀ wá nítorí pé apá kán bí a ṣe lè fí ìfẹ́ wá hàn sí Ọlọ́run pẹ̀lú àkókò wá ní láti gbọ́ràn sí àṣẹ Rẹ̀.

Bí a tí rí ká ní Jòhánù kini 5:2-3 (NIV) tí ó sọ bayi pe: “Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pá òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira.”

Ọ̀nà kẹta tí a lè fí nifẹ Ọlọ́run nípa àkókò wá ní láti ní àsìkò àdúrà.Àdúrà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun tí mo yàn láàyò nítorí náà oríṣiríṣi ọ̀nà ní mo fí ń gbàdúrà. Fún àpẹẹrẹ, ní òwúrọ̀ mó fẹ́ láti kọ́ èrò ọkàn mi sílẹ̀ kí ń lè fí bá Ọlọ́run sọ̀ ohun tí ó wà sí mi lọ́kàn, ńkan tó jẹ́ mi lógún, àti ìgbésẹ̀ tí ó yẹ kí ń tún gbé tẹ lè. Mó sì tún ní àtòjọ àwọn ènìyàn tí mo ń fi àdúrà rán lọ́wọ́ lójojúmọ́. Lákótán, yípo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní mó fí ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ láti bí mo ṣe máà dojú kọ iṣẹ́ tí ó nira láti ṣe títí dé ibi tí mo ti máà yín lógo fún èyí ó bá mí ṣe ní àṣeyọrí.

Nígbàtí a bá fí àkókò tí a ní fẹ́ràn Ọlọ́run, a ó ní ìrírí ìfẹ́ Rẹ̀ tí ó ga julọ sí wá

CONTEXTREQUEST   Key: day_4
Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Divine Time Management

Bá a ṣe máa ń lo àkókò wa lọ́nà tó bófin mu lè fa másùnmáwo nígbà tá a bá ń sapá láti "ṣàkóso" ìgbésí ayé wa nípasẹ̀ agbára àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ fún wa pé a máa ń ní àlàáfíà àti ìsinmi nígbà tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nípa àkókò wa. Nínú ìwéwèé ọjọ́ mẹ́fà yìí, wàá mọ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń lo àkókò rẹ ṣe lè mú kó o rí gbogbo ohun rere tó ní fún ọ gbà, títí kan ayọ̀ àti àlàáfíà Rẹ̀.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Elizabeth Grace Saunders fún ìpèsè èrò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ sii, jọ̀wọ́ ṣàbẹ̀wò: http://www.divinetimebook.com/