Ṣíṣe Àkóso Àkókò N'ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ

Divine Time Management

Ọjọ́ 5 nínú 6

Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ̀ pẹlu àkókò tí Ẹlẹ́dà fún ọ 

Li ló àkókò rẹ̀ láti nifẹ ẹlòmíràn jẹ́ ohun tí ó gá julọ tí ó sì dára jù lọ ní bí a ṣe ń lò àkókò wá. Ó sì tún jẹ apá kán pàtàkì fún wá láti fí hán pé ọmọlẹ́yìn Kristi ní àwa ìṣe.

Ìhìnrere Jòhánù 13:35 (NIV) ṣe àkọsílẹ̀ bayi pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin ń ṣe, nígbà tí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ sí ọmọ ẹnìkejì yín.”

Ó jẹ ńkan tí kò bójú mú gẹ́gẹ́bí Kristẹni pé ìgbà gbogbo kọ́ ní a máà ń ṣe àfihàn ìbásepọ̀ wá pẹ̀lú Kristi nínú àjosépọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. 

Ṣùgbọ́n ìgbà ọ̀tun tí dé bayi, àti pé ó lè farajìn láti fí ìfẹ́ hàn sí àwọn míràn pẹ̀lú àsìkò tí ó ní nísinsìnyí. Ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní láti wá àlàáfíà àwọn ènìyàn àti láti fí ọ̀rọ̀ ró ara wá wo. 

Nínú ìwé Romu 12:18 (NIV) ó sọ pé: “Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” Àti nínú ìwé Òwe 15:1 (NIV) ó sọ fún wá pé: “Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà. ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.”

Apákan wá tí ó nípọn tó ń ṣiṣẹ́ bí onílàjà ní bí a ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ kalẹ. . Ṣe a fí ohùn líle sọ̀rọ̀ tàbí a sọ èrò inú wá jáde ní ọ̀nà tí ó bọ̀wọ̀ fún ènìyàn? Ṣé a kà ara wa sí ẹni tí ó dára jù lọ tàbí ẹni tí ó burú jáì? A le yàn láti ní èrò tí ó lè mú kọ́núńkọ́họ́ kúrò àti gbígbé ọrọ kalẹ lọ́nà tó yẹ kí a lè mú àlàáfíà jáde pàápàá kúrò nínú ìkùnsínú tí ó lè fà ìjà. 

A tún lè nifẹ àwọn míràn nípa fífi ọ̀rọ̀ ró ara wá wo. dípò kí a na ìka àbùkù sí ẹlòmíràn nígbàtí ìṣe àti ọrọ àwọn míràn bá gbé wa nínú. Àwọn míràn tí lè ṣe àṣìṣe tàbí ṣe ìselòdì. Ṣùgbọ́n àwọn ìfèsì òdì wá tí ó lágbára ní ìṣe pẹ̀lú ìṣe wọ́n irúfẹ́ èyí tí ó lè mú ìpalára tàbí irọ́ dání nínú wá àti nínú wọn pẹ̀lú.

Gẹ́gẹ́bí a ṣe rí kà nínú ìwé Mátíù 7:3 (NIV) tí ó sọ pé: “Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ?"

Ọ̀nà tí ó nípọn tí ó fí lè fí àsìkò rẹ nifẹ àwọn míràn ní ṣíṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́, àti láti fí ojú inú wò ó: Mọ̀ ohun tí ó sẹ́lẹ̀ gangan. Béèrè lọ̀wọ́ ara rẹ̀ ìdí tí ó fí fá ọkàn rẹ. Ronúpìwádá kí ó sì dárí jì. Béèrè fún ìwòsàn lọ́wọ́ Ọlọ́run. Lehin náà tí ó bá yẹ, bá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀.

Àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí ń gbá àsikò àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsúnrákì ṣùgbọ́n ó jẹ ìyọrísí wá tí ó jẹ agbára Kristi nínú ìfẹ́ àti àlàáfíà dípò agbára tí ó lè mú ìparun wá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé áàrin òkè ìṣòro ní a wà

IDAGBASOKE   Bọtini ọjọ _5 Ọjọ́ _5
Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Divine Time Management

Bá a ṣe máa ń lo àkókò wa lọ́nà tó bófin mu lè fa másùnmáwo nígbà tá a bá ń sapá láti "ṣàkóso" ìgbésí ayé wa nípasẹ̀ agbára àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ fún wa pé a máa ń ní àlàáfíà àti ìsinmi nígbà tá a bá g...

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Elizabeth Grace Saunders fún ìpèsè èrò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ sii, jọ̀wọ́ ṣàbẹ̀wò: http://www.divinetimebook.com/

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa