Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ
Oba, Olórun, àti Olùgbàlà
Ní Mátíù 2:11, Awòràwọ̀ mú àwon èbùn olókìkí mẹ́ta wa fún Jésù: wúrà, tùràrí, àti òjíá. Ñjé ó mò pé àwon èbùn yìí ní àkànse tó se pàtàkì nínú Májẹ̀mú láéláé àtipe wòye Ènì tó wá se ìjọsìn Rè?
Wúrà dúró fún oloba ní Orin Dáfídì 72:15, àti èbùn wúrà fi ìdánilójú sọ pé Jésù Loba àwon Oba. Tùràrí tán mo ìjọsìn Olórun ní Ẹ́kísódù 30:34, àti èbùn tùràrí fi mọrírì pé Jésù ní Olórun. Ní Ékísódù 30:22-25, òjíá tá àmì òróró lè orí àwon ènìyàn fún àwon ète àkànse. Ìgbà àkókó ti Jésù gba òjíá gégé bí èbùn ní ìgbà ìbí Rè.Àwon Ìgbà ìkèyín ti a fún Jésù ni òjíá lórí igi àgbélébùú àti láàárìn ìsìnkú Rè. Èbùn yìí tóka sí ète àkànse ti ayé tí Jésù: Yóò kú lórí igi àgbélébùú láti gbà wa là lówó àwon èsè wa àtipe lèyín náà jíǹde sí ìyè àjàségun lórí ikú.
Ese Mátíù ní 2 dárúko pé nígbà tí àwòràwo rí Jésù, “wón wólè àtipe wón se ìjọsìn Rè.” A se ìjọsìn Jésù gégé bí Oba nítorí Ó ní “gbogbo àse lórí òrun àti ayé” (Mátíù 28:18-20). A se ìjọsìn Jésù gégé bí Oba nítorí “ nípasè Rè ni a dá ohun gbogbo; láìsi Òun kòsóhunkóhun tá dá ní a má tí dá” (Jòhánù 1:3). Àti a se ìjọsìn Jésù gégé bí Olùgbàlà wa nítorí “Olórun nífèé ayé tó béè géé Tó fí Omo bíbí Rè kan soso fún wa, kí olúkúlùkù ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun(Jòhánù 3:16). Béèrè lówó Olórun láti lo àkókó Bíbọ̀ yìí láti mú ó sún mò Jésù nípasè ìjọsìn, bí ìràwo se mú àwon àwòràwo wa láti wa sìn Jésù.
Àdúrà: Bàbá, È se fún jijé aṣáájú mi sí Yín. Bí È se mú àwon àwòràwo sún mo Jésù,È jòwó mú mi sún mo Jésù sí i ju bí mo ti sún mo O télè. Jésù, Mo sìn Yín gégé bí Oba mi, Olórun mi, àti Olùgbàlà mi! Èmí Mímó,È ràn mi lówó láti se atọ́nà àwon elómìrán tó jìnnà láti sún mò àti sìn Jésù.
Gbá àwòrán tónìí jáde nibi.
Àwon àyọlò ọ̀rọ̀: John MacArthur, Mátíù 1–7, William Hendriksen, Síṣàlàyé Ìhìn Rere gégé bí Mátíù, David Platt, Gbígbé Jésù Gbà nínú Mátíù, Grant R. Osborne, Mátíù, (Zondervan “Awọn aláwìíyé Oríṣiríṣi àlàyé lórí Májẹ̀mú Tuntun).
Nípa Ìpèsè yìí
Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.
More