Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ

Advent: The Journey to Christmas

Ọjọ́ 22 nínú 25

Ọkàn Ọlọ́run Sí Gbogbo Àgbáyé

A fi yé wa wípé àwọn Amòye ìgbàanì jẹ́ awòràwọ̀, èyí tó múu yé wa ìdí tí Ọlọ́run fi lo ìràwọ̀ láti tọ́ ipasẹ̀ wọn lọ sọ́dọ̀ Jésù. Ó mọ bí ó ti lè pe àkíyèsí wọn. Gẹ́gẹ́bí awòràwọ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé aláfọ̀ṣẹ tí ńṣe àkíyèsí àmì láti ni agbára ni àwọn amòye yìí ńṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí ló ti wáyé nípa ìlú ìbí àti ìṣẹ̀wá àwọn ọkùnrin tó wá láti ìlà oòrùn yìí, àmọ́ ohun kan wà tí a mọ̀ dájú: Wọn kìí ṣe ẹ̀yà Júù. Kèfèrí ni wọ́n íṣe.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn ènìyàn lérò wípé Olùgbàlà nì yóò wà láti gba ẹ̀yà Júù ṣílẹ̀, àní àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run. Ìrètí tó mọ́gbọ́n dání ni, nítorí lóòrè-kóòrè ni àwọn ẹ̀yà abọ̀rìṣà Kèfèrí tó wà láyìíká wọn ń pọ́n wọn lójú. Tí Ọba kan lórí gbogbo ayé bá ńbọ̀ láti wá fi ìjọba rẹ̀ lélẹ̀, ó dájú wípé nítorí ẹ̀yà Júù ni.

Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run fi pàtàkì ìbí Jésù hàn sí àwọn Amòye ìgbàanì, a ní àrídájú gbòógì wípé Ó fẹ́ mú ìbárẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ayé bọ̀sípò, láì ka ibi tí a ti ṣẹ̀wá àti àìmọ̀ọ́ṣe wa sí. Ipele tó ṣe pàtàkì ni èyí, pàápàá fún àwọn tí kìí ṣe ẹ̀yà Júù. Lótìtọ́ọ́ ni a bí Jésù gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹ̀yà Júù bẹ́ẹ̀ ló sì wá fún ìràpadà àwọn tó ti yàn láti àtètèkọ́ṣe, bákannáà ló wá láti ṣe ìlàjà láàárín gbogbo ènìyàn àti Ẹlẹ́dàá wọn.

Nínú Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 15, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé Ẹ̀mí Mímọ́ kò ṣe ìyàsọ́tọ̀ láàárín àwọn Júù àti Kèfèrí mọ́. Ẹnikẹ́ni tó bá ti gbàgbọ́ nínú Jésù ti di àyànfẹ́ Ọlọ́run nìyẹn. Pọ́ọ̀lù tẹ̀síwájú ní Kólósè 3, níbi tó ti sọ wípé, "Ninu ipò titun yìí, kò sí pé ẹnìkan ni Giriki, ẹnìkan ni Juu; tabi pé ẹnìkan kọlà, ẹnìkan kò kọlà, ẹnìkan aláìgbédè, ẹnìkan ẹlẹ́nu òdì, ẹnìkan ẹrú, ẹnìkan òmìnira. Nítorí Kristi ni ohun gbogbo, tí ó wà ninu ohun gbogbo.” Jésù mu hàn kedere nínú Ìránijáde Ńlá wípé ìfẹ́ òhun ni kí gbogbo orílẹ̀ èdè wá sọ́dọ̀ òhun. Ọ̀dọ̀ aráyé ni ọkàn rẹ̀ wà!

Àdúrà: Jésù, O Ṣeun fún wíwá sáyé láti gba àwọn ènìyàn tó ti kọ̀ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. O ṣeun tí o fẹ́ ní ìbárẹ́ pẹ̀lú mi nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́ tí mo sì jìnà sí ọ. Mo mọ̀ wípé gbogbo àgbáyé ni O fẹ́ràn, mo fẹ́ jẹ́ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ láti tẹ̀síwájú nínú ìràpadà àwọn tó ti ṣánko kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Lò mí láti tan ìfẹ́ rẹ káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè.

Ṣe àkáálẹ̀ àwòrán tòní níbí .

Àwọn ibi tí a ti fa ọ̀rọ̀ jáde: https://www.christianitytoday.com/history/2016/december/magi-wise-men-or-kings-its-complicated.html
Ọjọ́ 21Ọjọ́ 23

Nípa Ìpèsè yìí

Advent: The Journey to Christmas

Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.

More

A fé láti dúpe lówó Church of the Highlands fún ìpèsè ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i,E jòó ṣèbẹ̀wò:https://www.churchofthehighlands.com/