Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ
Ìgbàgbọ́ Láìsí Lilọ́ Tìkọ̀í
Ronú nípa ìgbà kan tí o gbó láti òdó Olórun, bóyá o jé ìllérí, ìfìdí òtítọ́ ohun múlẹ̀, tàbí ìdánilójú. Kí ni ìdáhùnpadà rè lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Se ó gbé ìgbésẹ̀ lórí ohun Tó so, tàbí o jókòó àtipe ó simẹ̀dọ̀ ronú lórí yálà o jé ohùn Rè gan-an? Bóyá ó mò dájúdájú pé ó gbó ohun Tó so àmó síbè o lọ́ tìkọ̀. (Ìkéde: kò séwu—gbogbo wa lo tí se!)
Lúùkù orí kejì so pé nígbà tí àwon ángẹ́lì sò ìhìn rere fún àwon olùṣọ́ àgùntàn nípa ìbí’ Jésù, wón “sáré lo ” láti wá A. Dípò didúró kárí àti jé kí iyèméjì yó wolé, wón dáhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Èyí gbà ìgbàgbọ́ tó ńlá! Dájúdájú, wón fé bá Jésù pàdé, sùgbón wón tún ní aájò tí ayé. Kí ni wón máa se pèlú agbo eran wón? Se kí wón kókó so fún àwon ebí wón? Se wón múra lọ́nà tó yẹ? Se olùṣọ́ àgùntàn lásán ye léni gan láti pàdé Ọba àwon Ọba? Wón kò jé kí èyíkéyìí ìbéèrè wònyí tí a lè tí béèrè ní ìpo kaánnà fà wón sẹ́yìn láti dáhùn kíákíá sí Olórun.
Gégé bí a ti ń tèlé Jésù, a nílò láti wémó irú ìgbàgbọ́ yìí. Nígbà tí a ba lọ́ tìkọ̀ pèlú Olórun, a sèdá Ohun tó ń yọrí sí iyèméjì, ìfòyà, àti àìsí ìfọ̀kànbalẹ̀—àwon èyí tí kò wá láti òdó Rè. Nígbà tí o gbó òrò kan pàtó láti òdó Rè, gbẹ́kẹ̀lẹ́ ìtọ́sọ́nà Rè. Yóò fún ó lókun láti se ohun Tó ni kí o se. Gbogbo ohun tó nílò láti se ní láti fèsì. Ru ìgbàgbọ́ rè sókè lónìí àti pinnu ṣáájú pé o máa gbéra nígbà tí Olórun so pé gbéra, kò sí ohun yóò wù!
Àdúrà: Bàbá, Ẹ ṣeun fún sùúrù Yín pèlú mi. È dáríjì mi fún àwon ìgbà tí mo ti lọ́ tìkọ̀ nígbà tí È ba mi sòrò. Mo fé tèlé ètó Yín fún ayé mi. È kún ìgbàgbọ́ mi ní agbára, àtipe È ràn mi lọ́wọ́ láti dáhùn kíákíá nígbà tí mo ba gbó láti ódó Yín.
Gbà àwòrán tónìí jáde níbí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.
More