Ìyípadà Ọmọ Onínàkúnàá pẹ̀lú Kyle IdlemanÀpẹrẹ

Prodigal Son Transformation With Kyle Idleman

Ọjọ́ 7 nínú 7

“Ọ̀rẹ́-Ọ̀fẹ́ fún Ọmọkùnrin Méjèèjì”

Ọmọkùnrin àgbà ń bínú nígbà tí ó rí ìgbésẹ̀ bàbá rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n yìí lè ti ṣiṣẹ́ takuntakun pẹ̀lú ìtọ́jú oko pẹ̀lú ìṣòòótọ́, àmọ́ ó ti sọnù nínú ilé bàbá rẹ̀.

Kòní ìsọjí kan. Kòní ìṣòdodo kan. Kòní ìgbésẹ̀ kan ṣoṣo.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, ọmọ onínàkúnàá ni òhun tìkálárarẹ̀. Ọkàn tirẹ̀ náà jìnà sí bàbá rẹ̀. Òhun náà ti sọnù, àmọ́ kò ṣe àkíyèsí rẹ̀. Tim Keller ṣe àpèjúwe rẹ̀ báyìí, “Ọmọ búburú náà sọnù nínú aburú rẹ̀, àmọ́ ọmọ dáradára sọnù nínú ìṣe rere rẹ̀.”

O lè má tíì ṣáko lọ sí Ìlú Àjèjì. O lè ní ìwé-ẹ̀rí tó pegedé nípa ìjọsìn. O lè ti tẹ̀lé gbogbo ìlànà. O lè tí ka ìwé yìí dé ìparí tí àwọn tí ó wà ní Ìlú Àjèjì tí ìwé yìí lè ṣ'àǹfàní fún sì ń wá sí ọ lọ́kàn. Àmọ́ taló mọ̀ bóyá ìwọ gan ni Jésù ti ń kọsí látòní.

Orí-ire kan tí ọmọkùnrin àgbà yí wá ṣe ni wípé, nígbà tí ó wà nínú oko, bàbá rẹ̀ fi ayẹyẹ tí ń lọ lọ́wọ́ sílẹ̀ ó sì tọ̀ọ́ lọ. Ó ní ìbápàdé pẹ̀lú rẹ̀.

Kíni èyí ń fi yé wa nípa Ọlọ́run? Ọlọ́run ń nọ̀gà láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Rẹ̀. Bóyá bíi ọmọ àgbà yí ni ìwọ rí ni àbí bí àbúrò.

Láì wo àwọn ìpinnu àti ìgbésí ayé àbúrò yí tó lòdì, bàbá yìí dìrọ̀ mọ́ọ. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ kòbá-kùgbé ọmọ àgbà àti àìní-ìbọ̀wọ̀ tí ó fi hàn, bàbá náà fi ìfẹ́ ṣàlàyé fún un. Láyé àtijọ́, kò wọ́pọ̀ fún olórí ilé láti máa ṣàlàyé ìgbésẹ̀ tàbí ìpinnu rẹ̀. Àwọn ìdílé ìgbàanì kìí ṣe ìjọba alágbádá; bí kò ṣe ti àfipámúnisìn. Síbẹ̀ bàbá yìí fèsì sí ìbínú ọmọ rẹ̀ àgbà pẹ̀lú sùúrù àti ọrẹ-ọ̀fẹ́.

A máa ń retí kí Ọlọ́run jẹ́ bàbá tí ń wá ìdájọ́, àmọ́ nípasẹ̀ Jésù, Ó ń fún wa ní ìfẹ́ àti ore-ọ̀fẹ́ tí a kò ní ẹ̀tọ́ sí. Lákòótán, ìtàn tó wà ní Lúùkù 15 yìí kìíṣe nípa ọmọkùnrin méjì tó ṣe àìgbọràn. Ìtàn nípa Bàbá tó ní ìfẹ́ tí kìí yẹ̀ sí àwọn ọmọ rẹ̀ ni.

* Nígbà tí ìwọ bá ṣẹ̀, báwo ni ìwọ ti ń rí Ọlọ́run àti èròńgbà Rẹ̀ sí? Báwo ni ore-ọ̀fẹ́ àti ìfẹ́ Rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun ti ń mú iná ìgbésẹ̀ AHA rẹ jó si?

Ṣé o jẹ̀gbádùn ètò kíkà yí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, forúkọ sílẹ̀ fún àǹfààní láti rí odindi ìwé náà gbà níbí

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Prodigal Son Transformation With Kyle Idleman

A fa ètò yí jáde látinú ìwé Kyle Idleman "AHA," máa fọkàn báalọ bí ó ti ń ṣàwarí àwọn ǹkan mẹ́ta tó lè túbọ̀ mú wa sún mọ́ Ọlọ́run àti láti yí ayé wa padà fún rere. Ṣé o ṣetán fún àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run tí yóò yí ohun gbogbo padà?

More

A fé láti dúpe lowo David C Cook fún ipese ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, Jọ̀ọ́ bè eyii wò: http://www.dccpromo.com/aha/