Ìyípadà Ọmọ Onínàkúnàá pẹ̀lú Kyle IdlemanÀpẹrẹ
“Ìlànà Àgbékalẹ̀ AHA”
Ìyàwó mi ní ìwé ìdáná kan nílé, ara àwọn ẹ̀bùn ìgbéyàwó wa ni. Orúkọ rẹ̀ sì ni “Ìwé Ìdáná Eléèlò Mẹ́ta.” Ó ma fẹ́ kí nsọ fún un yín wípé kìí lòó. Nígbà tí aya mi bá sì ń dá'ná, èlò ma ń sábà ju mẹ́ta lọ. Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé èmi ló ma ń sábà lo “Ìwé Ìdáná Eléèlò Mẹ́ta.”
Ní ẹ̀mélò kan tí a bá gbà mí láyé nínú yàrá ìdáná, ìwé yìí ní ma ńṣe atọ́'nà mi, nítorí tí a ó bá ní parọ́, mi ò lè sè ju èròjà mẹ́ta lọ fún ìdáná kan. Ohun kàn tí mo wá kọ́ pẹ̀lú àbámọ̀ ni wípé tí a bá ń lo Ìwé Ìdáná Eléèlò Mẹ́ta yìí, gbogbo èlò tó bá tọ́ka sí ló ṣe pàtàkì—kódà, àìgbọdọ̀-yọsílẹ̀ ni wọ́n jẹ́.
Ìṣòro kan pẹ̀lú Ìwé Ìdáná Eléèlò Mẹ́ta nìyẹn. Kò sí ìrẹ́jẹ níbẹ̀. Tó bá jẹ́ èlò méjì lo lò, oúnjẹ náà ò lè dàbí.
Báyìí gan ni ìrírí AHA ṣe rí.
Mo ti tẹ́tí sí ìrírí AHA àwọn ọgọ́rùn-ún—bóyá gan ní kò tó ẹgbẹ̀rún—ènìyàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn. Mo ti ṣe àṣàrò àwọn ìrírí ìyípadà àwọn èèyàn tó lórúkọ nínú Bíbélì. Pẹ̀lú ìbámu tó jọra pẹ́kípẹ́kí, AHA ma ń ní èròjà mẹ́ta ní gbogbo ìgbà. Tí ìkankan nínú àwọn èròjà yí ò bá sí níbẹ̀, yóò fà ìdádúró fún ètò ìyípadà náà:
(1) Ìsọnijí Òjijì (2) Ìṣòóótọ́ tó Nira (3) Ìgbésẹ̀ Ojú-Ẹsẹ̀ (Ìsọnijí, Ìṣòóótọ́, Ìgbésẹ̀ = III; ni ede geesi: Awakening, Honesty, Action = AHA)
Bí ìsọnijí àti ìṣòóótọ́ bá wà, tí kò sì sí ìgbésẹ̀, AHA ò lè ṣẹlẹ̀.
Tí ìsọnijí àti ìgbésẹ̀ bá wà, ṣùgbọ́n tí a rọ́ ìṣòóótọ́ sí ẹ̀gbẹ́, AHA ò ní lọ títí.
Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti Ẹ̀mí Mímọ́ bá mú àwọn èròjà mẹ́ta yìí papọ̀ sínú ayé rẹ, o ma ní ìrírí AHA—ẹ̀bùn Ọlọ́run tí yóò yí ohun gbogbo padà.
* Ǹjẹ́ o ṣetán fún àkókò AHA tí yóò yí ọ padà? Ǹjẹ́ o ṣetán láti gun àkàbà mẹ́ta tó nííṣe pẹ̀lú ìgbésẹ̀ náà?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A fa ètò yí jáde látinú ìwé Kyle Idleman "AHA," máa fọkàn báalọ bí ó ti ń ṣàwarí àwọn ǹkan mẹ́ta tó lè túbọ̀ mú wa sún mọ́ Ọlọ́run àti láti yí ayé wa padà fún rere. Ṣé o ṣetán fún àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run tí yóò yí ohun gbogbo padà?
More