Ìyípadà Ọmọ Onínàkúnàá pẹ̀lú Kyle IdlemanÀpẹrẹ

Prodigal Son Transformation With Kyle Idleman

Ọjọ́ 2 nínú 7

“ÌSỌNIJÍ – Ìmúbọ̀sípò Iyè Rẹ”

Lọ́pọ̀ ìgbà ni a ń kùnà láti gbọ́ àwọn ìpè tó ń dún lákọ nínú ayé wa nítorí a kò ṣe àkíyèsí wọn. Dùrù olóhùn tútù ò lè ṣiṣẹ́ náà—ó máa gba fèrè olóhùn gooro láti jí wa dìde. Fún ìdí èyí dípò títají ní ojú mọmọ, ní ṣe ni à ń padà sójú ọrùn nígbà tí ìpè bá ti wawọ́ díẹ̀. Ohùn ìpè yí yóò wá máa lọ sókè débi tí a kò lè kọtí dídi síi mọ́. Nígbà náà ni a ó wá tají, fọwọ́ bọ́jú, tí a ó sì wo àyíká wa láti rí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ọmọ onínàkúnàá láyìíká wa, tí a ó sì ní ìyàlẹ́nu ọ̀nà tí a gbà dé bẹ̀.

Ìbéèrè mi fún ọ lèyí: Ṣé kò sí ìpè tó ń dún nínú ayé rẹ lákòókò yí?

Nínú Ìwé Mímọ́ ni a tí gbé rí onírúurú ọ̀nà tí Ọlọ́run fi ń fọn ìpè. Lọ́pọ̀ ìgbà ni ìpè náà ma ti dún ṣáájú àkókò tí ǹkan yóò dojú rú. Nígbà mìíràn ni àwọn ènìyàn a máa retí àti kàn'din nínú iyọ̀ kí iyè wọn tó bọ̀sípo, àmọ́ tí Ọlọ́run bá ń gbìyànjú láti pè ọ́ sí àkíyèsí nísinsìnyí àti láti gbà ọ́ lọ́wọ́ àbámọ̀ Ìlú Àjèjì ńkọ́?

Kíróníkà Kejì 36:15 sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ti máa ń fọn ìpè láti ki àwọn ènìyàn Rẹ̀ n'ílọ̀. Ọ̀rọ̀ yí “ó ń dìde ní kùtùkùtù” kò túmọ̀ pé Ọlọ́run dìde lórí ibùsùn ní ìdájí. Dípò èyí ìtumọ̀ rẹ̀ tó dára jù lọ ni “gbígbé ìgbésí ní kánkán.” Tí a bá gbé yẹ̀ wò lọ́nà yí, ó túmọ̀ sí wípé Ó fọn ìpè ní kété tí ó fura pé ìṣòro wà nítòsí.

Lẹ́yìn èyí ni a wá ka ìdí tí Ó fi ń kìlọ̀: “…torí ó káàánú àwọn ènìyàn rẹ̀…” Fún àǹfààní wa ni àwọn ìpè yí jẹ́, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí wa.

* Ǹjẹ́ àwọn ìpè kan wà tí ìwọ ń kọ etí ikún sí? Ṣé o lè rántí ìgbà kankan tí Ọlọ́run kì ọ́ nílọ̀ ṣáájú ìjákulẹ̀/ẹ̀ṣẹ̀ kan tí o padà bá pàdé?

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Prodigal Son Transformation With Kyle Idleman

A fa ètò yí jáde látinú ìwé Kyle Idleman "AHA," máa fọkàn báalọ bí ó ti ń ṣàwarí àwọn ǹkan mẹ́ta tó lè túbọ̀ mú wa sún mọ́ Ọlọ́run àti láti yí ayé wa padà fún rere. Ṣé o ṣetán fún àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run tí yóò yí ohun gbogbo padà?

More

A fé láti dúpe lowo David C Cook fún ipese ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, Jọ̀ọ́ bè eyii wò: http://www.dccpromo.com/aha/