Ìyípadà Ọmọ Onínàkúnàá pẹ̀lú Kyle IdlemanÀpẹrẹ

Prodigal Son Transformation With Kyle Idleman

Ọjọ́ 4 nínú 7

“ÌṢÒÓÓTỌ́ - Bíbá Araà Mi Sọ̀rọ̀”

A rí èròjà AHA kejì (Ìṣòòótọ́ tó nira) nínú Lúùkù 15:17: “Ó sọ fún ara rẹ̀…”

Kòsí ẹlòmíràn ní sàkání rẹ̀. Òhun àti àwọn ẹlẹ́dẹ̀ nìkan ló wà níbẹ̀. Nígbà míràn ìtàkùrọ̀ tó nira jù láti ṣe ni èyí tí o ní láti bá ara rẹ̀ ṣe. Ìṣòòótọ́ tí kò yọ ohun kan sílẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú wíwo inú dígí kí a sì sọ òtítọ́ nípa ohun tí a rí. AHA nílò kí o sọ òtítọ́ fúnra rẹ nípa ara rẹ.

Ọmọ Onínàkúnàá nì sọ òtítọ́ fún ara rẹ̀ nípa irú ìjìyà tí ó tọ́ síi. Irú ìṣòòótọ́ báyìí ṣòro. A máa ń fẹ́ ìsọnijí tí kò ní ìṣòòótọ́ tó nira nínú.

Bíi ìyàwó tó jí lówùrọ̀ pẹ̀lú àròyé ṣùgbọ́n tó kọ̀ láti gbà wípé, “Kò dára bí mo ti ń kùn kiri ilé yìí. Mo mọ̀ wípé ìkíni lẹ́yìn àti àdúrótì ni ọkọ mi nílò, àmọ́ àròyé àti ìkùnsínú ni mò ń ṣe kiri.”

Tàbí bíi ọkọ tó mọ àìtọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ àmọ́ tó kọ̀ láti sọ wípé, “Ìpèníjà àgbèrè yí ti mú kí ìgbéyàwó mi mẹ́hẹ àti wípé ó ti mú ọkàn mi yigbì sí ìyàwó mi.”

Sísá fún ìṣòóótọ́ tó nira máa fa ìdíwọ́ fún ìyípadà tó ní ìtumọ̀. Nígbà tí a bá ṣe ìdámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ láì ronúpìwàdà, AHA ò lè wáyé. Nígbà tí iyè Ọmọ Onínàkúnàá nì ṣí, ó bá ara rẹ̀ sọ òtítọ́. Ìsọjí gbọ́dọ̀ tọ́ wa sípa ìṣòóótọ́. Ìdálẹ́bi gbọ́dọ̀ tọ́ wa sípa ìjẹ́wọ́.

Parí parí ẹ̀, Bàbá wa tí ń bẹ ní ọ̀run rí bẹ́ẹ̀ni Ó mọ ohun gbogbo, fún ìdí èyí kìí ṣe kíká àìṣedédé mọ́ ọ lọ́wọ́ là ń sọ. Ìṣòóótọ́ tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ rékọjá ìjẹ́wọ́ ìkùnà rẹ; ó níí ṣe pẹ̀lú jíjọ̀wọ́ ọkàn rẹ. Lóòótọ́, o sọ fún ẹni tó ká ọ wípé kó má bínú, ṣùgbọ́n o ní láti ṣe ju èyí lọ. Ní àkókò ìdákẹ́jẹ́ àti ìṣòóótọ́, o gbọ́dọ̀ sọ òtítọ́ fún ara rẹ kí o sì wà ní ìkárísọ fún ìkùnà rẹ.

Ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìkábàmọ́ọ̀ àti ìrònúpìwàdà nìyí.

* Ǹjẹ́ o ti lépa ìsọjí nípa sísọ òtítọ́ fún ara rẹ, bó tilẹ̀ nira? Ṣé ìṣòóótọ́ rẹ pẹ̀lú ara rẹ dé ipele tí yóò mú ọ rí ìkùnà rẹ àti bí ó ti ba Ọlọ́run nínú jẹ́?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Prodigal Son Transformation With Kyle Idleman

A fa ètò yí jáde látinú ìwé Kyle Idleman "AHA," máa fọkàn báalọ bí ó ti ń ṣàwarí àwọn ǹkan mẹ́ta tó lè túbọ̀ mú wa sún mọ́ Ọlọ́run àti láti yí ayé wa padà fún rere. Ṣé o ṣetán fún àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run tí yóò yí ohun gbogbo padà?

More

A fé láti dúpe lowo David C Cook fún ipese ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, Jọ̀ọ́ bè eyii wò: http://www.dccpromo.com/aha/