Ìyípadà Ọmọ Onínàkúnàá pẹ̀lú Kyle IdlemanÀpẹrẹ
“ÌGBÉSẸ̀ – Àkókò láti Dìde”
Ìgbésẹ̀ ni ibi tí ọ̀pọ̀ nínú wa ti ma ń ní ìdádúró. A mọ ohun tó tọ́ láti ṣe, a ti bọ́ s'óríi kẹ̀kẹ́, àti tẹ̀síwájú wá ni ìṣòro. Ọ̀tọ̀ ni kí a ní ìṣojí àti ṣíṣe ìṣòóótọ́ nípa ohun tí ó kàn láti ṣe. Ǹkan ọ̀tọ̀ kepegbe wá ni láti gbé ìgbésẹ̀ ìgboyà. Nínú Lúùkù 15:20 láti rí ọ̀rọ̀ tó rọrùn tó yí ìtàn Ọmọ Onínàkúnàá nì padà. Jésù sọ wípé, “Ó sì dìde…”
Ó gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Iyè rẹ̀ ṣí sí wípé àkókò tó láti dìde. Àkókò tó láti wá ǹkan gbé ṣe. Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ wípé a kò tíi kọ nípa wa wípé, “Arákùnrin náà sì dìde,” tàbí or “Arábìnrin náà sì dìde,” ǹkan ò tíì fi taratara yí padà.
Ibi tí AHA púpọ̀ nínú wa ti ń ní ìjánu nìyí. A ní àkókò ìṣojí ńlá, kódà a ní ipá láti ṣe ìṣòóótọ́ tó nira, àmọ́ àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀ rẹ̀ a ò rí ohun tó ní ìtumọ̀ kan gbé ṣe. Èyí tó jù nínú ìgbésí ayé wa là ń lò ní agbedeméjì ìṣòóótọ́ àti ìgbésẹ̀.
Bí o ti ń ka èyí o lè máa rò ó lọ́kàn rẹ wípé, “Mo gba tìẹ, àmọ́ nkò ní ìwúrí láti gbé ìgbésẹ̀ kankan nípa rẹ̀.”
Ó lè kan létí, tàbí bóyá gbígbọ́ ti sú wa; síbẹ̀, òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé a ní láti ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run bí a kò tilẹ̀ ní ìwúrí láti ṣeé. Nígbà tí a bá ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run bí kò tilẹ̀ rọrùn, ìmọ́lára wa yóò padà jẹ́rìí síi wípé ipa tí ó dára ni a tọ̀.
Bẹjú wo àwọn ètò tí o ní fún àwọn ìyípadà tí o nílò láti ṣe. O lè ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ nígbà kan rí, bóyá sórí ìwé tàbí sí oókan àyà rẹ, o sì rántí bí o ti tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ. Ṣe ìrántí ìgbésẹ̀ tó ṣáájú, àfi bí Ọmọ Onínàkúnàá nì nígbà tí ó pinu wípé, “Èmi yóò sì tọ bàbá mi lọ, èmi yóò wí fún u pé…” Ó mọ ohun tó kàn láti ṣe, ó sì gbé ìgbésẹ̀. Ṣàwárí ìgbésẹ̀ tó ṣáájú kí o sì ṣe ǹkan nípa rẹ̀ lọ̀gàn, bóyá ó nira tàbí ó rọrùn. O sì lè ṣe àkíyèsí bí o ti ń tẹ̀síwájú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, wípé àwọn ǹkan tí o kàn tiraka láti ṣe lè ní ìtumọ̀ ojúlówó.
* Ǹjẹ́ a ti sọ ọ́ jí, ní ìṣòóótọ́ pẹ̀lú ara rẹ, ṣùgbọ́n láì tíì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ? Kíni ìṣísẹ̀ tó lè ṣáájú ìgbésẹ̀ náà?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A fa ètò yí jáde látinú ìwé Kyle Idleman "AHA," máa fọkàn báalọ bí ó ti ń ṣàwarí àwọn ǹkan mẹ́ta tó lè túbọ̀ mú wa sún mọ́ Ọlọ́run àti láti yí ayé wa padà fún rere. Ṣé o ṣetán fún àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run tí yóò yí ohun gbogbo padà?
More